You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Flood: Ìjọba Ondo kéde ìsimi ọ́sẹ̀ mẹ́ta fún àwọn ilé ìwé tó lùgbàdì omíyalé!
Ijọba ipinlẹ Ondo ti fun awọn ile iwe kan ni ijọba ibilẹ Ilajẹ ati Ẹsẹ odo ni isimi ọlọsẹ mẹta lọna lati wa ọna abayọ si iṣẹlẹ omiyale to waye ni ipinlẹ naa.
Awọn ile iwe alakọbẹrẹ ati girama ti ọrọ naa kan ni agbara ti ya wọ bayii.
Oluranlọwọ pataki lori ọrọ iroyin fun ijọba ipinlẹ Ondo, Ojo Oyewamide sọ fun BBC pe, bi wọn ṣe ti awọn ile iwe naa jẹ ọna lati wa ojutu si iṣelẹ omiyale naa.
- Èmi kò sí nílé, ọkọ́ mi ló leè sọ bóyá lóòtọ́ọ́ ló fẹ́ gbéyàwó àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha fèsì
- Ẹ jọ̀ọ́, òógùn ojú mi kò gbọdọ̀ já sásán lórí sinimá tí mo yà pẹ̀lú oyún oṣù mẹ́fà - Toyin Abraham
- Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ẹ múra sílẹ̀, ìjà ń bọ̀ lórí owó oṣù tuntun lọ́jọ́rùú - NLC kéde fáráyé
- Kò sí òògùn kankan tó ń mú mi bí ìbejì bíkòṣe oúnjẹ ìbílẹ̀ - Aláàfin Ọyọ
Oyewamide ni ki ṣe gbogbo ile iwe ni ipinlẹ Ondo ni ọrọ naa kan, bikoṣe awọn ile iwe to wa ni ijọba ibilẹ Ilajẹ ati Ẹsẹ odo.
O ṣalaye pe ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ lati boju wo agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, lọna ati wa ọna abayọ si.
Ijọba ipinlẹ Ondo, labẹ iṣakoso gomina Rotimi Akeredolu ti dari awọn oluṣakoso ile iwe lagbegbe naa, lati ri pe wọn ko ohun elo ikawe ti omi le bajẹ kuro lagbegbe ọhun, titi di igba ti ijọba yoo wa ojutu si ọrọ naa.