You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ijegun pipeline fire: Ẹ̀mi méjì, ọkọ̀ tó lé ni 30 ṣòfò níbi ọ̀pá epo tó gbaná
Awọn olugbe agbegbe Ijegun ni kii ṣe igba akọkọ niyii ti ọpa epo yoo gbana ni ọdọ awọn. "O ti ṣẹlẹ lọdun 2008".
Wọn ni orukọ ti adugbo awọn njẹ tẹlẹ gan ni "Five Junction tori pe ọna naa pin si marun un" ṣugbọn wọn ni iṣẹlẹ ki ina maa jo ni gbogbo igba lo mu awọn sọ ọ lorukọ "Fire Junction" bayii.
Bakan naa wọn ni awọn ará Ijegun kọ́ ló ń bẹ́ ọ̀pá epo ní Ijegun, ita ni wọn ti n wa nitori naa wọn ke gbajare si ijọba pe ''o ti sú awọn, kí ìjọba wá gbà wọ́n!
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko LASEMA ni bi awọn ṣe de ibi iṣẹlẹ naa, wọn ri i pe awọn kan to maa n bẹ ọpa epo lati jale lo fa iṣẹlẹ naa to waye ni Fire Junction Ijegun.
Agbẹnusọ to ba BBC Yoruba sọrọ ni eniyan mejila ni awọn ti doola bayii, wọn ti gbe eniyan mẹjọ ninu wọn lọ si ile iwosan ijọba tó wà ní Gbagada ti wọn si ko awọn mẹrin lọ si ile iwosan ti LASU.
Gẹgẹ bi Ọmọwe Olufemi Oke-Osanyintolu ṣe sọ ọ, awọn janduku yii ti ṣaaju ko epo sinu ọkọ akepo ti iwọn rẹ to lita ẹgbẹrun lọna mẹtalelọgbọn ti wọn si tun ti n ji omii ko sinu iru ọkọ akepo yii miiran nigba ti awọn agbofinro ya lu wọn.
Bi wọn ṣe n gbiyanju ati na papa bora ni opo ta sinu gọta ti wọn si fẹsun kan pe awọn janduku ọhun sọ ina si epo to ta silẹ lati le awọn agbofinro danu ki wọn ma baa mu wọn.
Afi kẹ̀ẹ̀, nina ba ran pada lọ si orisun ibi ti wọn ti n ji epo to si gbana pẹlu ọwọ ina giga to n jo wi wi wi.
Ajọ LASEMA sọ fun BBC Yoruba pe ẹmi meji ti ba iṣẹlẹ naa rin ti o si ti le ni ọkọ ọgbọn to jona.
Wọn ki awọn to le mọ pato iye ẹmi to nu ati awọn to fara pa, o di ti awọn ba ṣe ayẹwo to tọ, afiwe ati isiro to yẹ ki awọn ṣe.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ni awọn janduku to maa n bẹ ọpa epo bẹntiroo lati ji epo wa lo fa katakata to ṣẹlẹ lọjọbọ ni agbegbe Ijegun ti ọpa epo ti gbina.
Akọroyin BBC kan si alabojuto ẹkun Guusu-Iwọ Oorun Naijiria fun ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, Ibrahim Farinloye ni ki awọn eniyan ṣaa bu omi suuru mu.
Ibrahim ni awọn ti kan si awọn alaṣẹ ile iṣẹ NNPC lori iṣẹlẹ owurọ yii bẹẹ si ni awọn tun ti kan si ẹka ile iṣ awọn to n ri si ọrọ aabo lati dawọ pinpin epo bẹntiroo nipasẹ ọpa epo duro na ki ọwọ ina naa le rọlẹ na.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ yii ṣe sọ, wọn ni awọn janduku to maa n bẹ ọpa epo lati ji epo wa lo da wahala yii silẹ.
Bakan naa a gbọ latẹnu NEMA pe wọn ti pa ina ọhun wọn si ti gbe awọn to fara pa lọ si ile iwosan fun itọju.
Ọpa epo bẹntiroo naa to gba ina ni agbegbe Ijegun/Isheri nipinlẹ Eko bẹrẹ ni owurọ kutu ni nkan bii ago marun.
Awọn ti ọ̀rọ̀ naa ka lara ti n fi ọrọ adura sita si Ọlọrun lati dawọ ibi yii duro ki ẹmi si ma nu.
Gẹgẹ bi ohun ta a gbọ, aarin oru ni iṣẹlẹ naa bẹrẹ, ti awọn ara adugbo bẹrẹ si ni i gbọ ariwo ibugbamu nla.
A ko ti i le fi idi nkan to fa ibugbamu ina naa mulẹ, ṣugbọn lori ayelujara, bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn to fẹ ẹ ji epo wa nibi ọpa epo naa, to wa nitosi ileepo kan lo fa ina naa, ni awọn kan n sọ pe ọkọ agbepo kan lo ṣubu lu ọpa epo.
Awọn ara agbegbe naa ti n figbe sita loju opo ayelujara pe ki awọn alaṣẹ tọrọ kan tete wa seranwọ lati pa ina ọhun.
Ẹwẹ, nigba ti BBC Yoruba bá agbẹnusọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri LASEMA l'Eko Ọgbẹni Kehinde Adebayo sọ̀rọ̀, o fi aridaju iṣẹlẹ naa ati agbegbe to ti n ṣẹlẹ han ati pe awọn oṣiṣẹ awọn ti wa lna Ijegun ni akoko ti akọroyin BBC Yoruba fọrọ wa a lẹnu wo.
A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.