You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
APC NEC Meeting: Ẹkúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ ìkini PDP sí APC bí àwọn adarí ẹgbẹ́ lápapọ̀ ṣe túká rèé
Ẹgbẹ oṣelu oṣelu alatako lorilẹede Naijiria, Peoples Democratic Party, PDP ti fi ikini ku oriire ranṣẹ si gbogbo ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress, APC jakejado orilẹede Naijiria gẹgẹ bi "ẹgbẹ to ti n dun mọhuru-mọhuru mọ wọn fun ọdun marun ṣe ti yọ́ danu kuro ni gbagede oṣelu".
Eyi gẹlẹ ni ọrọ ti akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan fi sita ni kete ti igbimọ alaṣẹ APC pari ipade ti wọn ti tu awọn adari ẹgbẹ ni gbogbo ipele ka lọjọ Iṣẹgun ọsẹ.
Ninu atẹjade rẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP ni nigba ti ẹru ajaga ijakulẹ ni gbogbo igba ti n wọ ẹgbẹ APC lọrun ati pe iwa ọbayejẹ to wọ wọn lẹwu ati iṣoro ifasẹyin ọrọ aje to gogo, iṣekupani ohun bi ilu ṣe le koko ti wọn ko ba awọn araalu lo mu wọn fi tipa tikuuku gba ara wọn da sita kuro ninu oṣelu nipa titu gbogbo awọn adari wọn ni gbogbo ipele lapapọ ka.
- Lóòtọ́ ni ọkọ mi lù mí bí àṣọ òfì, àmọ́ gómìnà ti bá wa parí ẹ̀, ẹ máa gbàdúrà fún ìdílé mi- Dokita Ifeyinwa
- Mi ò kí n ṣe afẹfẹ-yẹ̀yẹ̀ lórí ayélujára nítorí pé mí ò ní dúkìá tí mó le fihàn- Ronke Oshodi-Oke
- Àwọn èèyàn tí bẹ̀rẹ̀ sì ní gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ìdènà àrùn Coronavirus ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tí Amẹ́ríkà fẹ́ gbé lórí Nàìjíríà nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn
Ologbodiyan ni igbesẹ t wọn gbe yii ti wọ inu iwe itan lọ paapaa bi PDP ṣe ni awọn araalu n ṣajọyọ lẹyin ti wọn gbọ pe ẹgbẹ to ti n ko idamu ba wọn tuka.
Ni ẹgbẹ PDP ba ke si ajọ eleto idibo, INEC pe ki wọn wa yọ orukọ ẹgbẹ APC kuro ni akọsilẹ awọn ẹgbẹ to wa ki wọn si yọ iwe ẹri iforukọsilẹ wọn kuro toripe wọn o ni aato to yẹ labẹ ofin.
Bakan naa, wọn ni ki INEC kede aaye awọn aṣofin ẹgbẹ APC gẹgẹ bi eyi to ṣofo ki wọn si bẹrẹ igbesẹ atundi ibo lati fi ẹlomii sipo wọn gẹgẹ bo ṣe wa labẹ ofin.
Ẹgbẹ oṣelu PDP wa funpe si awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn tuka lati gbaradi fun esi wọn si idahun awọn ọmọ Naijiria fun iwa ti wọn pe ni aṣemaṣe pe ki wọn ma ro pe wọn lee mu u jẹ gbe nipa didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mii.
Ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC jáwe lọ gbéle rẹ fún ìgbákejì alága: Hilliard Eta!
APC tú ilé ká ní ìpele ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ́
Igbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tú ilé ká! Kò sí àwọn aláṣẹ mọ́ ní ẹkùn, ìpínlẹ̀ àti làpapọ̀
APC: Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congres tú ilé ká ní ìpele ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ́
Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni Naijiria ti tu gbogbo awọn adari ẹgbẹ ka ni ipele ipinlẹ, ẹlẹkun-jẹkun ati ijọba apapọ wọn lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹjọ, oṣu kejila ọdun 2020.
Eyi waye nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa to waye lori ayelujara nipasẹ Zoom ni ile aarẹ, Aso Rock niluu Abuja.
Lara ohun to tun ṣẹlẹ ni pe igbimọ alaṣẹ jawe lọ gbele ẹ fun igbakeji alaga ẹgbẹ tẹlẹri ni ẹkun Guusu- Guusu, Hilliard Eta.
Gomina Kaduna, Nasiru El-Rufai ṣalaye lẹyin ipade naa pe idi ti wọn fi fọwọ osi juwe ile fun Eta ni pe o kuna lati jami lọrọ ẹjọ kan to lodi si igbimọ fidihẹ ẹgbẹ.
Ẹ o ranti pe ẹgbẹ naa ti ṣeto latinuu oṣu kọkanla, lati ṣepade ti wọn yoo fi ṣagbeyẹwo ipo ti wọn wa ati ọna fun igbesẹ tuntun latari eto idari ẹgbẹ naa.
Alaga igbimọ fidihẹ ati igbimọ alakanṣe eto to fi mọ gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni lo dari awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ to ku pẹlu Aarẹ Buhari ninu ipade naa.
Aarẹ ile igbimọ aṣofin Sẹnetọ Ahmad Lawan ati adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila wa nibi ipade naa lojukoroju.
Bakan naa, awọn gomina APC eyi ti alaga ẹgbẹ awọn gomina, Kayode Fayemi ati gomina ipinlẹ Yobe, Atiku Bagudu naa wa nibẹ lojukoroju.
Nibayii, igbimọ alaṣẹ tun ti fikun saa ti igbimọ fidihẹ alakanṣe eto ẹgbẹ naa eyi ti Gomina Mai Buni n dari. Wọn fi oṣu mẹfa kun saa ti wọn yoo lo.
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Wo ibi fún èsì ìdìbò yíyan aàrẹ tuntun ní orílẹ̀-èdè Ghana
- Ọlọ́pàá, sójà yabo Lekki Toll Plaza láti dènà ìfẹ̀hónúhàn míràn
- Ìdí rèé táwọn àkàndá ẹ̀dá fi dí iwájú iléeṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo pa l'Agodi n'Ibadan
- A kò ní padà sílé ìwé àyàfi t́i ìjọba bá san owó oṣù tó jẹ wá - ASUU