You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue, Samuel Ortom ti parí ìjà láàrin akọ̀ròyìn Channels TV, Pius Angbo àti Ifeyinwa Angbo, ìyàwó rẹ̀
Arabinrin Ifeyinwa Angbo, to fi ẹsun kan ọkọ rẹ to jẹ akọroyin Channels Television, Pius Angbo, pe o lu oun ni ilukulu, ti sọ pe ki awọn eeyan ma gbadura fun idile oun.
O sọ ọrọ lẹyin ti gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, ba wọn pari ija ni ile ijọba to wa ni Makurdi.
Arabinrin Ifeyinwa sọ pe oun ti gba ẹbẹ ti ọkọ oun bẹ oun.
Eyi waye lẹyin wakati diẹ ti Ifeyinwa fi fidio kan sori ayelujara, pe ọkọ oun fi iya jẹ oun.
Ninu fidio naa lo ti ṣalaye pe dokita ni oun, amọ lati ọdun mẹfa ti oun ati Pius ti ṣegbeyawo,ni ko ti si alaafia ninu igbeyawo naa.
O ni niṣe ni ọkọ oun n paarọ obinrin bi aṣọ.
Iya ọlọmọ mẹrin ọhun sọ pe, ọsẹ mẹrin sẹyin ni oun fi iṣẹ abẹ bimọ tuntun.
Ṣugbọn, Pius lu oun ni alubami nitori pe oun kilọ fun lati dẹkun nina owo wọn sori obinrin mii, ni inakuna.
O ni niṣe lo joko le oun ni ikùn, to si tun gbiyanju lati fun oun ni ọrun pa.
- Àwọn nǹkan tí obìnrin lè ṣe pẹ̀lú olólùfẹ́ oníwà ipá lásìkò ìgbélé Coronavirus yìí
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- A kọ òfin gígé nǹkan ọkùnrin tó bá fipá bá obìnrin lòpọ̀ - Àwọn Alfa yarí
- Iwa nabi tu igbeyawo ọgbọn ọdun ka
- Tẹgbọn-taburo se igbeyawo ni Anambra
- Wo bí ìgbéyàwó ọmọ bàbá olówó, Adama Indimi àti Prince Malik Ado ọmọ Ọba Ohinoyi ilẹ̀ Ebira ṣe lárinrin tó
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nile ijọba, Ifeyinwa sọ pe oun dupẹ lọwọ gomina Ortom to ba wọn da si ọrọ naa.
" Mo dupẹ lọwọ gomina, fun bo ṣe fi aaye silẹ lati ba wa pari wahala yii.
O ni: "Mo mọ pe iṣẹlẹ yii dun awọn eeyan mi to wa nipinlẹ Benue, ṣugbọn mo bẹ yin pe ki ẹ dariji ọkọ mi."
O ni oun ti ṣetan lati jẹ ki igbeyawo oun duro daadaa.
"Adura yin ni emi ati idile mi nilo lasiko yii."
Ileeṣẹ Channels fi atẹjade sita lori iṣẹlẹẹ naa pe awọn ko fọwọ si tabi faramọ iwa ipa si awọn obinrin, tabi ẹnikẹni.
Wọn ni iwadii ti n lọ lori ẹsun iwa ipa ti wọn fi ẹsun rẹ kan akọroyin wọn kan, ati pe igbesẹ to yẹ yoo waye lori ọrọ naa.