You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Tax Exemption: Ìjọba àpapọ̀ kéde pé òun ń fẹ́ fi òpin sí bí àwọn tó ń gba owó oṣù tó kéré jùlọ ṣe ń san owó orí
Iroyin ayọ lo jẹ fun awọn oṣiṣẹ to n gba owo oṣu to kere julọ ni Naijiria, pẹlu bi ijọba apapọ ṣe kede pe, wọn ko ni ma a san owo ori lori owo oṣu wọn mọ.
Ọjọ Aje ni ileeṣẹ aarẹ kede iroyin yii loju opo ibaraẹnidọrẹ Twitter rẹ.
Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe igbesẹ naa jẹ ọkan lara ọna ti ijọba fẹ ẹ fi mu ọrọ aje Naijiria pada bọ sipo.
O ni "erongba yii jẹ ọkan lara awọn aba ofin eto ẹnawo to wa niwaju ile igbimọ aṣofin".
Buhari sọ pe "ilana tuntun naa jẹ ọna lati pari eto itura to sẹ fun awọn olokoowo kekeeke, to bẹrẹ ni ọdun to kọja.
- Ìjọba fẹ́ kọ́lé 300,000, pẹ̀lú ìrànwọ́ fún àgbẹ̀ 4m láti mú àdínkù bá ìṣẹ́ - Osinbajo
- Wo ọ̀nà tí ọrọ̀ ajé Naijiria tó dẹnu kọlẹ̀ gba kàn ọ
- Ọrọ̀ ajé Nàíjíríà yóò forí ṣánpọ́n tá a bá san ₦30,000 fún òṣìṣẹ - Ìjọba
- Owó orí VAT di 7.5% láti 5% lẹ́yìn tí ààrẹ Buhari buwọ́lu àbá ètò ìnáwó
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
"Eyi jẹ ọna lati fi ẹsẹ eto ọrọ aje mulẹ, nipa mimu adinku ba inira owo ọkọ, ati ọwọn gogo , ni lara awọn ọmọ Naijiria."
Ati pe eredi ti ijọba fi mu adinku ba owo ori ọkọ, ati awọn ọkọ eero, ni lati mu ki owo ti awọn awakọ n gba lọwọ ero dinku.
O ṣalaye pe bi ijọba ṣe fi opin si sisan owo iranwọ ori eporọbi 'subsidy', ati bi iye ti wọn n ta lita epo ṣe lọ soke si, n ni ipa lara iye ti araalu n ra ounjẹ.
Yatọ si eyi, ileeṣẹ aarẹ sọ pe ijọba n ṣiṣẹ pọ pẹlu banki apapọ, ati ileeṣẹ to n mojuto awọn idokowo ijọba, NSIA, to fi mọ awọn ijọba ipinlẹ, lati ṣeto bilisnu mẹẹdogun Naira.
Miliọnu mẹẹdogun Naira naa "yoo ṣe iranlọwọ lori ipese awọn nkan amayedẹrun.
"Yoo si tun duro gẹgẹ bi ipilẹ to dara fun idagbasoke ọrọ aje Naijiria."
- Wo bí o ṣe lè ṣe eré ìdárayá tí yóò fún ọ ní adùn àti okun fún ìbálòpọ̀
- Omotara pàdánù isẹ́ olówó ńlá nítorí ó fi ọtí ẹlẹ́rìndòdò sódà lá ọmọ alágbe lójú
- Jemila dáná sún ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́kadà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ibadan
- Adájọ́ ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọmọ Rasheed Maina, Faisal, tó sá mọ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́