You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kegel: Eré ìdárayá tí àwọn onímọ̀ sọ pé ó n fikún adùn ìbálòpọ̀ fún obìnrin, tó tún n fún ọkùnrin ní agbára
Awọn onimọ ilera maa n sọ pe pataki ni ere idaraya jẹ, ninu ilera ẹda.
Bẹẹ si ni oriṣiriṣi ere idaraya wa, ṣugbọn o ni awọn to n ṣanfaani fun ibalopọ laarin takọ-tabo.
Dokita onimọ nipa bi egungun inu ara ṣe n ṣiṣẹ, Abubakar Ahmad Tsafe, ti ileewosan Gbogboogbo Farida, nilu Gusau nipinlẹ Zamfara, sọ nipa awọn iwulo ati anfaani ere idaraya fun ibalopọ to dara fun ọkunrin ati obinrin.
Dokita naa sọ pe ere idaraya le ran ọkunrin lọwọ lati fi opin si ti tete da 'ejaculation', aile ṣe deede ninu ibalopọ.
O tun le mojuto ki nkan ọmọkunrin o ma ṣiṣẹ.
O ni o tun le ṣe iranlọwọ lori iṣoro ti ọkunrin ba ni pẹlu ile itọ rẹ.
Fun awọn obinrin, ere idaraya le fun ile itọ ati ẹya ara to wa fun ọmọ bibi, ni okun.
Kegel
Dokita Abubakar Ahmad Tsafe sọ pe ere idaraya Kegel, jẹ eyi ti ko nira rara, to si ma n fun awọn iṣan to wa lara egungun to so ara ati ẹsẹ pọ 'pelvis', ni okun.
Ẹya ara 'pelvis' yii kan naa lo gbe awọn ẹya ara to gbe nkan smọkunrin ati oju ara obinrin duro.
O wa laarin ikùn ati itan.
Iwe iroyin magasiini Healthline Health sọ pe ere idaraya Kegel ma n jẹ ki ile itọ ṣiṣẹ daadaa.
O si tun ma n fun eeyan ni agbara ati fun ibalopọ.
Iwulo ere idaraya Kegel fun awọn ọkunrin
Oriṣiriṣi nkan lo ma n din agbara ẹya ara 'pelvis' ku.
Nigba ti ọkunrin ba wa ni ọdọ, wsn ma n ni agbara.
Amọ bi wọn ba ṣe n dagba, ni yoo ma a rẹ ẹya ara naa, eyi ti yoo nipa lori bi wọn ṣe n ni ibalopọ.
Gẹgẹ bi Magasinni Healthline ṣe sọ, ere idaraya Kegel ma n mu ki adun ati ifẹ si ibalopọ, pọ si lara awọn ọkunrin.
O ma n dena ki ọkunrin tete dà àtọ lasiko ibalopọ, to si ma n din iṣoro ki ọkunrin o ma le ṣe ku.
Yatọ si eyi, Dokita Tsafe sọ pe ere idaya naa ma n mu ki ọkunrin le pa itọ mọra fun igba pipẹ.
Iwulo ere idaraya Kegel fun awọn obinrin
Oriṣiriṣi nkan lo le mu ki aarẹ ba 'pelvis' obinrin tabi ba a jẹ.
Eyi le waye nipasẹ oyun tabi ọmọ bibi.
O si le jẹ nipasẹ isẹ abẹ ile itọ tabi aisan ninu ile itọ.
Ṣugbọn dokita sọ pe ayipada le wa ti iru obinrin bẹ ẹ ba n ṣe ere idaraya Kegel.
O ni o tun ma n mu ki obinrin gbadun ibalopọ ju ti tẹlẹ lọ.
Wo nkan ti o ni lati mọ ki o to ṣe ere ere idaraya Kegel
O sẹ pataki lati da orisun awọn iṣan naa mọ.
Healthline sọ pe o le da wọn mọ nipa kiki ika ọwọ to mọ si inu oju ara rẹ, ki o si pa awọn iṣan oju ara naa pọ daadaa mọ ika naa.
Ọna miran tun ni pe ki ọkunrin tabi obinrin gbiyanju lati da itọ duro lasiko ti wọn ba n tọ lọwọ.
Awọn iṣan ti wọn fi da itọ duro ni ti pelvis, ti yoo si fun wọn ni òye aaye to wa.
Oriṣiriṣi ere idaraya Kegel to wa
Oriṣiriṣi ere idaraya yii lo wa - o le ṣe e lori iduro, ti o ba joko, tabi ki o sun si ilẹ
Eyi to wọpọ ju ni ki o sun silẹ, ki o si kọ oju si oke. Lẹyin naa, gbe itan soke, na ọwọ si iwaju, ki o si ka orunkun rẹ ko.
Dokita Tsafe sọ pe o le ṣe ere idaraya yii laarin iṣẹju aaya mẹta si marun, sinmi, ki o tun bẹrẹ pada.
Bakan naa ni fun ọkunrin ati obinrin.
O tun le ṣe ere idaraya naa nipa jijoko, ki o si ka ẹsẹ rẹ ko si abẹ ara wọn.
O le ṣe e fun iṣẹju diẹ, sinmi, ki o si tun tẹsiwaju.
Omiran tun ni pe ki o fi aya sun, ki o si gbe iku rẹ soke, pẹlu ọwọ rẹ ko di ẹọẹ rẹ mejeeji mu lati ẹyin.
Dokita sọ pe ko si asiko ti eeyan ko le ṣe ere idaraya yii, boya ni owurọ, ọsan tabi alẹ. Koda, o le ṣe nibi ti ko si ni gbangba nibi iṣẹ rẹ.
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ tí o bá fẹ́ lọ fún ìsinmi lẹ́yìn Covid 19
- DSS ti fi ẹ̀sọ́ àbò abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asofin tó pa fẹ́ndọ̀ l'Abuja sátìmọ́lé
- Wọ́n ti rí òkú Alága ẹgbẹ́ APC ní Nasarawa tí àwọn agbébọn jí gbé lọ́jọ́ Satide
- Wo ọ̀nà tí ọrọ̀ ajé Naijiria tó dẹnu kọlẹ̀ gba kàn ọ
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàfihàn ojú àwọn afurasí tó se ẹran ara ọlọ́pàá jẹ ní Ibadan