CAF President: Wọ́n ti fòfin ọdún márùn ún de Aàrẹ̀ CAF, Ahmad Ahmad

Ajọ to n mojuto ọrọ ere bọọlu ni agbaye ti fofin ọdun marun un de aarẹ ajọ to n ri si ọrọ ere bọọlu nilẹ Adulawọ.

FIFA fẹsun kan Ahmad Ahmad lẹyin ọpọlọpọ iwadii lori ṣiṣe magomago owo ati titẹ oju awọn ofin ajọ naa molẹ nilẹ Afrika.

Wọn tun ni ko ṣe e fi ọkan tan ati pe o tun gba owo ati ẹbun lọna aitọ yatọ si aṣilo ipo ati agbara.

FIFA ni lati ọdun 2017 ni wọn ti n ṣe iwadii naa titi di ọdun 2019.

Wọn tun ni ẹsun riran awọn eeyan lọ fun Umrah ni Mecca fun irinajo ẹsin naa tun jẹyọ.

Ogbeni Ahmad ni FIFA kede fifi ofin ọlọdun marun un de yii ni wọn tun ni ko san owo itanran $200, 000 to jẹ ẹgbẹrun lọna igba owo dọla ilẹ okeere.

O seese fun aarẹ CAF naa lati pe ẹjọ kotẹmilọrun si idajọ yii nile ẹjọ to wa fun igbẹjọ awọn elere bọọlu ati ere idaraya iyẹn: Court of Arbitration for Sport (CAS) laarin ọgọta ọjọ si asiko yii.

Loṣu to kọja ni aarẹ Madagascar naa ni oun fẹ lọ lẹẹkeji ninu idibo to yẹ ko waye ni oṣu kẹta ọdun to m bọ.

Lọdun 2017 ni Ahmad di aarẹ CAF.