You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Minimum Wage: Ìpàdé ìjọba àti òṣìṣẹ́ kò wọ̀ lánàá, kí ni yóò jẹ́ àbọ̀ ìpàdé tòní?
Ẹgbẹ awọn osisẹ il wa, NLC, ti sẹwe le iyansẹlodi to yẹ ko waye loni, nitori idunadura to si n tẹ siwaju nibi ipade kan ti yoo waye loni.
Igun to n soju ijọ̀ba apapọ ati igun awọn osisẹ ni wọn panupọ kede bẹẹ lẹyin ipade wọn to waye lana, eyi to ko so eso rere.
Ọpọ wakati lawọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ati asoju ijọba apapọ fi joko ipade lọjọ Iṣẹgun, ti ọrọ ko si wọ laarin wọn lori bi ijọba yoo ti ṣe san ẹkunwọ oṣu oṣiṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mama Rainbow pe 77 lónìí, àwọn òṣèré tíátà kọrin re kìí
- Kò sí ìfoyà, mò ṣetán láti sàn jù ₦30,000 fáwọn òṣìṣẹ́ l‘Eko - Sanwo-Olu
- Àlá àwọn òjíṣẹ́ Olúwa tó fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà leè má ṣẹ lógún ọdún - Abiara
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Yatọ̀ fún orí ìtàgé, wo ohun tí o kò mọ̀ nípà Mr Latin
Nigba to n sọrọ nibi ipade to waye lana, minisita fun ọrọ osisẹ, Dokita Chris Ngige salaye pe ibeere awọn osisẹ naa yoo doju ọrọ aje Naijiria de ni, ti ko si seese rara.
Sugbọn ẹgbẹ osisẹ ti wa n beere lọwọ ijọba pe ko mu ẹri to daju wa lati gbe ọrọ rẹ lẹyin , pe owo ti osisẹ n beere ti pọ ju.
Titi di igba ta n ṣe akojọpọ iroyin yii, igun to n soju ijọba apapọ ati igun awọn asaaju osisẹ ko tii ri ọrọ naa yanju, ti wọn si tun ni awọn yoo tẹsiwaju ipade naa lọjọru oni.