You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn kan ń gbèrò láti ṣèkọlù sáwọn ilé ìtura ńlá ní Nàìjíríà - Amẹ́ríkà ṣèkìlọ̀
Ile iṣẹ aṣoju ilẹ America to wa lorilẹ-ede Naijiria lo ti fi lede pe awọn kan n gbimọ lati ṣe akọlu sawọn ile itura to lorukọ lawọn ilu nla-nla kaakiri Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti ile aṣoju naa fi sori ikanni ayelujara wọn lọjọ Ẹti ọjọ kẹta oṣu kọkanla ni wọn ti wi pe “ilẹ America ni ẹri to daju pe ipinnu akọlu sawọn ile itura kan ni Naijiria lo ti de aaye to lapẹẹrẹ”.
Atẹjade naa fikun pe amọ awọn ẹṣọ alaabo nilẹ Naijiria n sa gbogbo ipa wọn lati dena akọlu ọhun.
Ẹwẹ, ijọba ilẹ America ti gba awọn ọmọ ilu naa to wa ni Naijiria lamọran pe ki wọn ronu daadaa lori ikilọ yii ki wọn to gba iyara tabi lọọ gbafẹ nile itura to ba lokiki ni Naijiria.
Wọn si tun fi nọmba ẹrọ ilewọ ti wọn le pe nigbakuugba ti wọn ba wa ninu iṣoro lede.
Bakan naa ni ijọba America tun kilọ fawọn ọmọ ilẹ naa lati maa wo ayika wọn finifini lawọn ile-itura to laami-laaka ki wọn si tun tẹle gbogbo ilana ti ijọba la kalẹ fun wọn lori abẹwo si Naijiria.
Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyí tí ẹ bá wà ní Naijiria - Ìjọba America
Ikilọ yii lon waye lẹyin oṣu meji ti ilẹ America kede awọn ipinlẹ kan tawọn araalu wọn ko gbọdọ lọ ni Naijiria.
Ninu ikilọ ti wọn fi lede ni ogunjọ oṣu kẹsan ọdun yii ni wọn ti wi pe ki awọn ọmọ ilẹ naa o maa ro ti iwa ọdaran, igbesunmọmi, ijinigbe, awọn agbebọn ati idarudapọ laarin ilu ki wọn too gbera lọ Naijiria.
Lara awọn ipinlẹ ọun ati idi tawọn ọmọ ilẹ America fi ni lati jinna si wọn ni Borno, Yobe, Kogi, ati Adamawa nitori igbesunmọmi ati ijinigbe.
Ipinlẹ Bauchi, Gombe, Kaduna, Kano, Katsina, Sokoto ati Zamfara nitori ijinigbe.
Abia, Anambra, Bayelsa, Delta, Enugu, Imo ati ipinlẹ Rivers (yatọ si ilu Port Harcourt) nitori ijinigbe ati awọn agbebọn.
Ninu oṣu kẹwa, ilẹ America kilọ fawọn ọmọ ilẹ naa jakejado agbaye lati ṣọra lori irinajo wọn kaakiri awọn ilu ti wọn ba wa.
Inu atẹjade naa ni wọn ti ka Naijiria kun awọn roliẹ-ede to wa ni abala kẹta ninu awọn orilẹ-ede to mu ifunra lọwọ.Ikilọ yii lon waye lẹyin oṣu meji ti ilẹ America kede awọn ipinlẹ kan tawọn araalu wọn ko gbọdọ lọ ni Naijiria.