Taofeek ni èsù ló jẹ́ kí òun fipá bá ọmọ ìyàwó rè tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlá sùn ní Ogun

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Ọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọkunrin kan, Taofeek Sulaiman, ẹni ogoji ọdun lẹyin to fipa ba ọmọ iyawo rẹ, ọmọ ọdun mẹtala sun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo kede ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọbọ niluu Abeokuta.

Oyeyemi salaye pe ọwọ tẹ afurasi naa lọjọ Aje lẹyin ti ìya ọmọdebinrin naa wa fi ẹjọ sun ni agọ ileeṣẹ ọlọpaa to wa ní Owode Yewa.

Gẹgẹ bii Oyeyemi ṣe sọ, iya ọmọ ni oun fẹ ọkùnrin naa lẹyin iku ọkọ oun to jẹ baba ọmọ to sagbako iṣẹlẹ naa.

"Iya ọmọ naa ni ọmọdebinrin sọ fun oun pe ọkọ oun ti ba oun sun lati ọjọ kẹrinla oṣu kẹwaa, ti afurasi naa si n dunkoko pe oun yoo ṣekupa to ba sọ fun ẹnikẹni."Kete ti iroyin de si agọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Yewa ni wọn bẹrẹ iwadi ti ọwọ si ti tẹ ọkunrin afurasi naa"Nigba ti a bẹrẹ ifọrọwerọ pẹlu afurasi naa ni o jẹwọ pe otitọ nipe oun ṣe amọ isẹ eṣu ni."

Oyeyemi ni ọmọdebinrin ni o ti wa nile wosan Idiroko nibi to ti n gba itọju to peye.

O ni Kọmisona ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti palasẹ pe ki gbe afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ifiyajẹ ọmọde fun iwadi to peye.