Wo ìgbésẹ̀ ti Tinubu fẹ́ gbé láti mú kí oúnjẹ sùn wá bọ̀ ní Nàíjíríà

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti kede nnkan o fararọ lẹka ipese ounjẹ lorilẹede Naijiria.

Aarẹ Tinubu ti akọwe ijọba apapọ, George Akume, ṣoju rẹ fidi ọrọ yii mulẹ nibi ipade ẹkun ilẹ Afirika lori siṣe eto ọgbin lọna igbalode ẹlẹẹkẹfa iruẹ niluu Abuja.

Tinubu rọ awọn ọmọ ilẹ Afirika lati ṣe amulo eto ọgbin lọna igbalode nipa ipese omi fun nnkan ọgbin papaa julo lasiko ọgbẹlẹ.

O ni akori apẹro naa ti wọn pe ni ''Wiwa ojutuu si iṣoro pipese omi lọna igbalode fun nnkan ọgbin nilẹ Afirika'' jẹ itaniji eyi ti yoo ṣe iranwọ fun eto ọgbin ati ọrọ aje.

''Ilẹ Afirika si n koju oniruuru ipenija nipa ipese omi fun nnkan ọgbin lọna igbalode lasiko ọgbẹlẹ tori ai si awọn irinṣẹ, ipenija owo, oju ọjọ ati ọrọ eto iṣejọba.

Apero ri jẹ ọna kan gboogi lati wa ojutuu si awọn ipenija yii,'' Tinubu lo sọ bẹẹ.

Tinubu ni orilẹede Naijiria ni sare oko to le miliọnu mẹta to wa lagbegbe odo ni ipinlẹ Benue ati Niger ti awọn agbẹ le lo fun ipese omi fun nnkan ọgbin lasiko ọgbẹlẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, minisita alumọni inu omi ati imọtoto, Ọjọgbọn Joseph Utsev, sọ pe ijọba ti pari awọn eto ipese omi fun nnkan ọgbin lasiko ọgbẹlẹ ni Naijiria.

Ọjọgbọn Utsev sọ pe awọn akanṣe eto ipese omi fun nnkan ọgbin lọna igbalode ni Dadin-Kowa ati Bakolori ti pari.

O ni ijọba tun n ṣe iranwọ fun eto ipese omi lọna igbalode fun nnkan ọgbin ni ipinlẹ Ondo, Kwara, Benue, Kebbi, Edo, Adamawa, ati ipinlẹ Oyo.

Ẹ jẹ ka maa ṣamulo ipese omi fun nnkan ọgbin lọna igbalode – Zulum

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Umara Zulum ti kepe awọn olori ilẹ Afirika lati maa ṣe amulo ipese omi lọna igbalode fun nnkan ọgbin yatọ si lilo omi ojo nikan.

Gomina Zulum to wa nibi apero ilẹ Afirika lori ipese omi fun nnkan ọgbin l'Abuja ṣalaye pe nipa siṣe eleyii ni ounjẹ le fi ''sun wa bọ ni Naijiria ati kaakiri ilẹ Afirika.''

Gomina ipinlẹ Bornu tun kepe awọn eeyan lati dokowo lẹkun eto ọgbin ni Naijiria.

O ni ti orilẹede Naijiria ba fẹẹ maa pese ounjẹ ti yoo to araalu jẹ, wọn gbọdọ tun ero wọn pa lori bi wọn ṣe n gbin ounjẹ.

Gomina Zulum ni eto lilo ipese omi lọna igbalode fun nnkan ọgbin lasiko ọgbẹlẹ jẹ ọna kan gboogi lati ṣe eleyii.

Gomina ipinlẹ Borno sọ pe ijọba ni lati ro awọn ileeṣẹ to n ṣewadii lẹka eto ọgbin lagbara.

Bakan naa lo sọ pe eto koriya gbọdọ wa fawọn obinrin atawọn ọdọ ki wọn le dasi ọrọ eto ọgbin ni Naijiria.

''Gẹgẹ bi olori lẹkun ti ayipada oju ọjọ ti n ṣakoba fun araalu, mo ri i pe mimu eto ọgbin lọkunkundun lo le ran wa lọwọ.

A si ti n ṣe eleyii nipa ifilolẹ oniruuru eto lẹka iṣẹ agbẹ ni ipinlẹ Borno,'' Gomina Zulum ṣalaye.