Ohun tí a mọ̀ nípa ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí tó gbẹ̀mí èèyàn 32 l’étíkun kan ní Somalia

Aworan ọkọ alaarẹ kan pẹlu ọpọ ero lẹgbẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn agbofinro ni ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn to ṣe ikọlu naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni eeyan mejilelọgbọn to ti ku ti ọpọ miran si farapa lẹyin ti agbebọn kan to so ado oloro mọra atawọn agbebọn kan kọlu eti okun kan ni olu ilu Somalia.

Agbẹnusọ fun ọlọpaa ilẹ naa kan, Abdifatah Adam Hassan sọ pe nnkan bii eeyan mẹtalelọgọta lo farapa, ti awọn kan ninu wọn si wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

Awọn fidio to jade lati ibi ikọlu naa ṣe afihan ọpọlọpọ oku atawọn to fara ṣeṣe ni agbegbe Abdiaziz naa ni ilu Mogadishu.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle lorilẹede naa n sọ pe awọn agbebọn ikọ agbesunmọmi al-Shabab, to n ṣakoso ọpọ agbegbe lẹkun gusu ati arigbungbun Somalia, lo ṣe ikọlu ọhun.

Ẹgbẹ naa ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi al-Qaeda, lati nnka bii ogun ọdun ni wọn si ti wa nidi igbesunmọmi tako ijọba ti ajọ iṣọ̀kan agbaye da mọ lorilẹede naa.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe ibẹrubojo ba awọn eeyan agbegbe naa nitori pe o ṣoro lati mọ ohun gan to n ṣẹlẹ ni pato nitori pe iro ibọn bẹrẹ si ni dun lẹyin ti ado oloro ti agbebọn kan so ọmọ ra kọkọ bu.

Abdulatif Ali ni awọn eeyan kan gbiyanju lati wa ibi fara pamọ si nibudo igbafẹ etikun naa nigba ti awọn miran si sa asala fun ẹmi wọn.

“Mo ri awọn eeyan to farapa ni eti okun naa. Awọn eeyan n pariwo kikankikan pẹlu ibẹru, o si nira lati da awọn to ku mọ yatọ si awọn to ṣi wa laaye”

Ko din ni eeyan marun un to wa nidi ikọlu naa, pẹlu bi Ọgbẹni Hasan ṣe sọ pe ọkan lara awọn to ṣe ikọlu naa fi ado oloro gbẹmi ara rẹ.

Ọwọ awọn agbofinro tẹ ọkan lara awọn to ṣe ikọlu naa, gẹgẹbi lukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ ni ilu Mogadishu.