Ìdí tí ń kó fí dáasí ìṣẹ̀lẹ̀ ilé gbimọ aṣòfin rèé - Gómìnà Oyebamiji

Oríṣun àwòrán, Ekiti State Government
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Gomina Ipinle Ekiti, Ọgbẹni Biodun Oyebanji ni ipinnu ti oun ṣe, eyi to da lori bi ofin ati ipinya agbara ṣe wa lo faa ti oun ko ṣe ni ẹtọ lati da si ọrọ iyọnipo abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ na tẹlẹ tabi gbe orukọ oludije to n fẹ fun ipo abẹnugan kalẹ fun Ile-igbimọ.
Gomina sọ eyi lana nigbati olori tuntun ti Ile igbimọ aṣofin ipinle Ekiti ṣe afihan ara rẹ ni ọfisi rẹ pẹlu awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu APC, Barr. Paul Omotoso Owoeye.
Oyebanji sọ pe ko bojumu fun oun lati da si isẹ awon aṣofin, o fi kun un pe gege bi Oloye aabo nipinle naa, ojuse oun ni lati rii daju pe oun daabobo emi ati dukia awọn eniyan.
Ogbeni Oyebanji fi imoore han si awon adari egbe oselu APC nipinlẹ naa fun iyanju wọn lati pẹtu si gbogbo laasigbo to n lọ ninu ile igbimọ aṣofin.
“Mo kọ lati ọjọ kini pe ki n dasi ọrọ yii nitori mo bura lati gbeja ofin orilẹede Naijiria.
Ofin fihan gbangba lori isẹ ati ojuṣe ẹkun ijọba kọkan, mo n lewaju ijọba eyi ti ko niṣe pẹlu ile gbimọ aṣofin. Awọn ile gbimọ aṣofin ko ki n da si ohun ti mo n se, yoo si buru fun mi lati da si ohun to n sẹlẹ nile igbimo aṣofin.
O tẹsiwaju pe ohun ti oun ti ṣe gẹgẹ bii gomina ni lati rii daju pe oun daabo bo ẹmi ati dukia ati pe iyẹn wa ninu agbara oun gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.
"Emi ko da sii ṣugbọn inu mi dun pẹlu abajade. Gẹgẹ bi awọn ilọsiwaju, a ni aṣa, aṣa si jẹ ibọwọ fun olori.
Iṣẹ́ ọwọ́ Fayemi ni ìyọnípò mi gẹ́gẹ́ bí abẹnugan Ekiti, Oyebamiji kó mọ nípa rẹ̀ – Aribisogan

Oríṣun àwòrán, others
Abẹnugan ile aṣofin ti wọn ni wọn yọ nipo nipinlẹ Ekiti, Olugboyega Aribisogan ni gomina tuntun ni ipinlẹ Ekiti, Abiodun Oyebamiji ko mọ nipa bi awọn ile igbimọ kan ṣe yọ oun nipo, ti wọn si kede aṣofin Olubunmi Adelugba gẹgẹ bii agbẹnugan tuntun.
Aribisogan ni isẹ ọwọ gomina ana nipinlẹ, Kayode Fayemi ni oun si lo lewaju awọn aṣofin ti wọn kora wọn jọ lati yan abẹnugan tuntun ni ilana ti ko ba ofin orilẹede Naijiria mu.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ nigba to n ba ileeṣẹ BBC News Yoruba, o ṣalaye pe owurọ ọjọ Aje ni dede ago marun un arọ ni awọn aṣofin meje lati inu ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn to ṣapejuwe gẹgẹ bii janduku lọ si ile aṣofin ti wọn si gbe igbesẹ naa.
“Mo ti sọ tẹlẹ ki wọn to gbe igbesẹ yii pe awọn kan n gbimọ pọ lati yọ mi gẹgẹ bii abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ekiti.
“Wọn lọ si ilẹ asọfin lana pẹlu awọn janduku kan pẹlu ọmọ ẹgbẹ wa meje lati ile aṣofin, wọn wọ ibẹ ni ago marun un idaji, ki ago mẹfa to lu, wọn ni awọn ti yan abẹnugan tuntun, wọn ṣe eto ti ko ba ilana ofin Naijiria mu.
“Eyi n waye lẹyin ti gbogbo wa ti dibo ni ilana to ba ofin mu. Eyi waye lẹyin igba ti ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn n gbero lati ṣe ikọlu si ile igbimọ aṣofin, ti wọn si fẹ jo ile ọhun. Wọn gbe igbesẹ yii lai si awọn osisẹ ile igbimọ ati awọn aṣofin yooku nibẹ.
“Ohun iyalẹnu nipe ọlọpaa gbegi dina, nigba ti wọn gbe igbesẹ naa, eyi ti ko fun awọn oniroyin ni anfani lati wa nibẹ
Ni temi, Ko tii si nkankan to jọ mọ wipe wọn yọ mi nipo gẹgẹ bii abẹnugan
Olugboyega Aribisogan tẹsiwaju pe ko si nkankan to jọ mọ wipe wọn yọ oun nipo nitori pe oun jẹ abẹnugan gẹgẹ bi ilana to ba ofin mu ni.
O ni kete ti abẹnugan tẹlẹ, Funminiyi Afuye jade laye ni wọn gbe idibo kalẹ laarin oun ati Olubunmi Adelugba, ti oun si bori ninu idibo ọhun.
Aribisogan wa fi ẹsun kan gomina tẹlẹ nipinlẹ naa, Kayode Fayemi pe o kopa ninu igbesẹ naa nitori pe oun lo pe awọn sinu ipade, ti o si ni pe ki awọn fi Olubunmi Adelugba jẹ abẹnugan ile aṣofin ile.
“Gbogbo nnkan ti ẹri naa lo jẹ pe wọn gba ọna eru ṣe, wọn dori gbogbo rẹ kodo, wọn ro pe awọn le gba ọna ẹburu wọle.
“Ibo ti a di nile gbimọ aṣofin lẹyin ti aṣofin tẹlẹ fipo silẹ, a jọ dibo naa ni, emi ati Adelugba, to si jẹ pe awọn ọmọ ile mẹẹdogun lo dibo fun mi, ti mẹwaa si dibo fun oun.
“Gomina tẹlẹ, John Kayode Fayemi lo pe awa ọmọ ẹgbẹ sinu ipade kan ni ile rẹ, to si ni ki a lọ dibo fun Olubumi Adelugba, pe oun ni awọn fẹ. O ni nnkan ti oun fẹ ni ki a dibo fun.
“Mo wa dide pe ko yẹ ko ribẹ nitori a ni ofin ati ilana ti a fi yan abẹnugan ti ko sisi ẹnikẹni to lee yii pada nitori pe bii ifin ṣe sọ niyẹn. Ofin ọhun ni a tẹle ti mo fi jẹ abẹnugan ile.
Aribisogan ni awọn to gbe igbesẹ jẹ ọdaran ti awọn yoo si fi wọn jofin















