Yóò ṣòro fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò míì lọ́wọ́ yìí – INEC

Oríṣun àwòrán, @IndependentNGR
Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC ti sọ pe ko ni ṣeeṣe labẹ ofin lati bẹrẹ eto iforukọsilẹ oludibo mii ṣaaju eto idibo ọdun 2023.
Inu oṣu Keje ọdun 2022 yii ni INEC fopin si iforukọsilẹ oludibo naa amọ ọpọ ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan tako igbesẹ ọhun pe ẹgbẹlẹgbẹ araalu ni ko ni lanfaani lati dibo lọdun to n bọ.
Amọ gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ fun INEC lati bẹrẹ eto naa pada, ko ṣi maa ṣe iforukọsilẹ oludibo titi ti eto idibo naa yoo fi ku oṣu mẹta.
Amọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Channels, ọkan lara awọn ̣ọga agba INEC, Festus Okoye sọ pe iwe aṣẹ ile ẹjọ naa ko tii tẹ awọn lọwọ.
Okoye fi kun pe awọn ti pari eto iforukọsilẹ oludibo fun eto idibọ ọdun 2023.
O ni “Yoo ṣoro labẹ ofin fun wa lati tẹsiwaju lati maa forukọ awọn oludibo silẹ lọwọ yii.”
O fi kun pe INEC ti bẹrẹ iṣẹ lati ri daju pe eto iforukọsilẹ naa rọrun fun awọn araalu lọjọ iwaju.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí INEC bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ padà fún káàdì ìdìbò

Oríṣun àwòrán, INEC
Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti pàṣẹ fún àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC, láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìforúkọsílẹ̀ fún káàdì ìdìbò padà lẹ́yẹ ò sọkà.
Adájọ́ Inyang Ekwo ní kí INEC tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìforúkọsílẹ̀ títí tí yóò fi ku àádọ́rùn-ún ọjọ́ tí ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023 máa fi wáyé.
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Adájọ́ Ekwo darí INEC láti rii dájú pé wọn kò fi ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn láti gba káàdì ìdìbò kí wọ́n le kópa níbi ètò ìdìbò kàn wọ́n.
Ó ní ó pọn dandan fún INEC láti fi ààyè gba àwọn ènìyàn láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àjọ náà gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Nàìjíríà ṣe là á kalẹ̀.
Arábìnrin kan Anajat Salmat àwọn mẹ́ta mìíràn ló ti ṣaájú wọ́ INEC lọ sílé ẹjọ́ fẹ́sùn wí pé wọ́n ṣe ìdádúró ètò ìforúkọsílẹ̀ fún káàdì ìdìbò ṣaájú ọjọ́ tí òfin là kalẹ̀.
Wọ́n rọ ilé ẹjọ́ láti pàṣẹ fún INEC láti bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ padà ní ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí.
Adájọ́ Ekwo ní ẹjọ́ tí Salmat àti àwọn yòókù rẹ̀ pè láti bèèrè fún ìtẹ̀síwájú ìforúkọsílẹ̀ náà tọ̀nà tí INEC sì ní láti fi ọjọ́ kún ètò ìforúkọsílẹ̀ ọ̀hún.
Ẹ ó rántí pé ní oṣù Keje ni INEC fòpin sí ètò ìforúkọsílẹ̀ lẹ́yìn ilé ẹjọ́ gíga da ẹjọ́ tí àjọ SERAP pe INEC pé kí wọ́n fi ọjọ́ kún ètò ìforúkọsílẹ̀ dípò ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹfà tí wọ́n fẹ́ fi òpin si ètò náà ṣaájú.












