Ìwọ́de bẹ̀rẹ̀ l'Eko àti Osun, àwọn agbófinró fi gáàsì tajútajú tú olùwọ́de ká l'Abuja

Iwọde ebi-n-panu bẹrẹ lonii to jẹ ayajọ ọjọ ti Naijiria gba ominira lọwọ ijọba ilẹ Gẹẹsi.
Iwọde naa lo waye lagbege Ikeja Under Bridge to wa niluu Eko.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni awọn ajafẹtọ ọmọniyan to n ṣagbatẹru iwọde naa, Omoyele Sowore to jẹ oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC ati Juwon Sanyaolu, to jẹ adari ajọ Take It Back Movement ti kọkọ sọ pe ko si ohun ti yoo yẹ ifẹhonuhan naa ti yoo bẹrẹ laago meje aarọ.
Sowore sọ ninu atẹjade kan pe lati aago meje aarọ ni oun atawọn eeyan yoo ti korajọ si abẹ afara Ikeja nibi ti wọn yoo ti bẹrẹ ifẹhonohan ọhun.
Bi iwọde naa ṣe n lọ lọwọ ni a n ko iroyin yii jọ.
Lara awọn to kopa ninu iwọde naa ni ẹgbẹ Vanguard Liberation, Take it back movement, awọn araalu atawọn ẹgbẹ mii.
Ọpọ awọn agbofinro lo wa nibi iwọde ọhun to n lọ lọwọ niluu Eko.
Wọrọwọ ni iwọde naa n lọ, ti awọn oluwọde si n kọ orin lati sọ oko ọrọ si Aarẹ Bola Tinubu ti ko si si ija laarin awọn atawọn ọlọpaa.

Awọn agbofinro tu oluwọde kan niluu Abuja
Ko pẹ pupọ ti awọn oluwọde bẹrẹ si n ko ara wọn jọ lagbegbe Utako to wa niluu Abuja ti awọn agbofinro fi gaasi tú wọn ká.
Ni gbogbo aarin gbùngbùn ilu Abuja ni a ti ri àwọn agbófinró, DSS ati Civil Defence pẹlu ìbọn ati gaasi taju taju lọwọ wọn.
Bakan naa ni a tun ri awọn ọkọ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti wọn n rin kaakiriaarin gbùngbùn ilu Abuja.
Lara awọn agbegbe ti awọn n ologun n ṣọ lojulẹsẹ ni Berger, Kubwa, Gwarimpa ati bẹẹ bẹẹ lọ.














