Arsenal fọ́ Sevilla lẹ́nu pẹ̀lú góòlù 6-0

Bukayọ Saka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Goolu mẹta ṣangiliti ni atamatase tuntun ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ṣẹṣẹ ra, Gabriel Jesus gba wọle sawọn lasiko ti Arsenal fi na Sevilla ni goolu mẹfa si odo ni idije ife ẹyẹ Emirates Cup to waye lọjọ.

Bukayọ Saka naa gba bọọlu wọle sawọn ni igba meji.

Ki ifẹsẹwọnsẹ naa to wọ iṣẹju mọkandinlogun ni Arsenal goke pẹlu goolu mẹrin si odo.

Eddie Nketia lo wa fọba lee lori.

Emirate Cup jẹ idije igbaradi fun saa bọọlu to n bọ lọna eyi ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu kan ti ileeṣẹ Emirates n ṣe agbatẹru fun maa n gba lọdọọdun ki ipenija ajakalẹ arun COVID-19 to de ba a lọdun 2020 ati ọdun 2021.

Fred, Agbabọọlu Manchester United gba kaadi pupa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ifẹsẹwọnsẹ miran to tun waye lọjọ abamẹta

Manchester United vs Athletico Madrid

Ni ilu Oslo lorilẹede Norway ni ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ laarin Manchester United ati Athletico Madrid ti waye. Amọṣa nnkan ko fi gbogbo ara ṣe ẹnuure fun Manchester United.

Joao Felix lo bu omi pa ireti wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti n rebi ati danu duro.

Amọṣa, alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa, iyẹn rẹfiri fun agbabọọlu Manchester United lọwọ aaringbungbun papa, Fred ni kaadi pupa fun aṣemaṣe lẹyin ti goolu naa waye.

Chelsea vs Udinese

Awọn agbabọọlu Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ifẹsẹwnsẹ to waye laarin Chelsea ati Udinese ni papa iṣire Dancia arena nilu Udine lorilẹede Italy.

Goolu meji lati ẹsẹ Ruben Loftus -Cheek ati Hakim Ziyech lo fun Chelsea ni igara olubori.