Ta ni Kabiru Tanimu Turaki tí wọ́n yàn bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹrin ọdún 1957 ni wọ́n bí Kabiru Tanimu Turaki tó di alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ University of Jos, tó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde lọ́dún 198, tí wọ́n sì pè é gẹ́gẹ́ bí aṣòfin lọ́dún 1986.

Ọdún 2002 ló di amòfin àgbà, tó sì di alága iléeṣẹ́ amòfin rẹ̀, KT Turaki & Co. lọ́dún kan náà.

Ó ṣe mínísítà fún àkànṣe iṣẹ́ lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan láàárín ọdún 2013 sí 2015.

Bákan náà ló tún ṣe aṣojú mínísítà fọ́rọ̀ iṣẹ́, tó sì tún ṣe alága ìgbìmọ̀ tó ń pè fún àlááfíà ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà.

Kó tó di alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ó díje dupò ààrẹ lọ́dún 2018 ṣùgbọ́n tí kò rí ipò náà, tó sì ṣe alága fáwọn mínísítà tẹ́lẹ̀ rí lẹ́gbẹ́ PDP.

PDP dìbò yan Turaki gẹ́gẹ́ bíi alaga ẹgbẹ́ tuntun, lẹ́yìn tí wọ́n lé Wike àti Fayose kúrò nínú ẹgbẹ́

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti dibo yan Kabiru Tanimu Turaki (SAN) lati ipinlẹ Kebbi gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ tuntun nibi ipade apero ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan ipinlẹ Oyo lọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹwaa yii.

Turaki to jẹ agbẹjọro agba bori pẹlu ibo 1,516, nigba ti alatako rẹ, Lado Danmarke, lati ipinlẹ Katsina ri ibo 275.

Sẹnẹtọ Ben Obi to ti figba kan ri ṣoju ipinlẹ Anambra nile aṣofin agba l'Abuja lo kede esi ibo naa.

Sẹnẹtọ Obi ṣalaye pe Danmarke ri ibo 275, bo tilẹ jẹ pe o kede wi pe oun ko ni dije fun ipo alaga PDP mọ ṣaaju eto idibo naa.

Eyi tumọ si pe Turaki wọle ibo alaga lai si alatako kankan.

Aaya bẹ silẹ o bẹ sare ni ọrọ iyansipo mi - Turaki

Ninu Orọ akọsọ re, Turaki ni aaya bẹ silẹ o bẹ sare ni ọrọ iyansipo oun jẹ nitori oun ṣetan lati di gbogbo ogiri ẹgbẹ oṣelu PDP to lanu silẹ.

‎Turaki ni akoko ti awọn ijoba kan maa n jẹ gaba lori ọmọ orilẹede Naijiria ti dopin, nitori ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni wọn ọn kere fun ẹgbẹ oṣelu APC mọ.

‎Turaki ṣeleri lati ba gbogbo àwọn to ti binu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP sọrọ ki wọn le pada sinu ẹgbẹ naa ki PDP le gbọrẹgẹ jigẹ lati koju ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju àti lẹyin eto idibo ọdun 2027.

''A o kede awọn igbesẹ ti a fẹ gbe ati ọna ti a fẹ gba fawọn eeyan laipẹ.

Kete ti a ba ti ṣe eleyii ni a o bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu,'' Turaki lo sọ bẹẹ.

Turaki fi dawọn ọmọ ẹgbẹ loju wi pe oun ko ni jawọn kulẹ pẹlu igboya ti wọn ni ninu oun.

Ọpọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo ri iyansipo Turaki gẹgẹ bi igbesẹ lati mu ki ẹgbẹ naa duro ṣinṣin ki idibo gbogbogbo ọdun 2027 to de.

‎Ipade apero naa ni awọn aṣojú tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta láti gbogbo ipinlẹ to wa ni orílẹede Nàìjíríà wa nibẹ.

Igbagbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wi pe àbájáde ipade apero to waye ni Ibadan yóò ní ipa pàtàkì lórí ọjọ́ iwájú ẹgbẹ oṣelu PDP àti eto oṣelu orilẹede Naijiria

PDP fọwọ́ òsì júwe ilé fún Wike, Fayose àti àwọn mẹ́wàá míì

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti fọwọ osi juwe ile fun Minisita fun olu ilu Abuja ati Gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers, Nyesome Wike; Gomina nigba kan nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ati alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Samuel Anyanwu.

Igbesẹ yii waye nibi ipade apero ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to waye niluu Ibadan.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun fọwọ osi juwe, oludamọran fun ẹgbẹ naa, Kamaldeen Adeyemi Ajibade, SAN; Senator Mao Ohuabunwa; George Turner ati Hon Umar Bature.

Igbakeji alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Oloye Olabode George, lo pe fun yiyọ Wike ati awọn yooku kuro ninu ẹgbẹ naa, to si kede pe igbesẹ naa da lori bi wọn ṣe n gbimọ pọ lati ba ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP Senetọ Umar Damagum ati Gomina ipinle Oyo,Seyi Makinde ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kaabọ si ipinle Oyo ti wọn si fi gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa lọkan balẹ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa ni won ti satunse sii

Tẹ ba gbagbe ṣaaju akọkọ yii ọpọlọpọ awuyewuye tí waye lori ipade apapọ ẹgbẹ naa to n waye lọwọlọwọ yii.

Ipade apapọ ẹgbẹ yii ni yoo mu iyansipo awọn adari ẹgbẹ tuntun wa.

Adeleke ati Fubara ko yọ sibi ipade PDP n'Ibadan

Ohun ti akoroyin ilesẹ BBC Yoruba saakiyesi n'ipe ako ti ri gomina ipinlẹ Ọsun senitọ Ademọla Adeleke ati ati Gomina ipinle rivers Siminalayi Fubara ni bi ipade naa

Gomina ipinle Zamfara, Dauda Lawan rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lati fọwọsowọpọ lati gbe ẹgbẹ oṣelu naa de ipo aasaju

‎Umaru Fintiri, Gomina ipinlẹ Adamawa ṣalaye si wi pe botile jẹ wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa kokan ti kuro sugbọn idaniloju wa wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti setan lati mu orile-ede Naijiria pada bo sipo

Gbogbo ọkọ akero ni ilu Ibadan ni alaga awọn oni motor ni ipinle Oyo Paṣẹ fun pe wọn ko gbodo ṣiṣe loni ni tori Ipade apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP lati sa ti lẹyìn fun Gomina ipinle Oyo

Eleyi lọ mu kí ọpọ olugbe ilu Ibadan ati awọn alejo ma ri ọkọ ayọkẹlẹ wo lo sibi ipade apapọ ẹgbẹ naa.

Ìpàdé àpérò PDP gbérasọ n'Ibadan láì fi ti ilé ẹjọ́ tó pàṣẹ ìdádúró ètò náà ṣe

Ipade apero ẹgbẹ oṣelu PDP ti gberasọ niluu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo lonii ọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹwaa yii, bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ ti paṣẹ idaduro eto naa.

Nibi ipade apero naa ni awọn aṣoju ẹgbẹ yoo ti dibo yan awọn oloye ẹgbẹ tuntun.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe bii gomina mẹrin ọtọọtọ ni wọn ti de siluu Ibadan bayii fun ipade apero naa.

Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹkun iwọ oorun guusu, Kamorudeen Ajisafe, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun iwe iroyin Punch.

Ajisafẹ ni Gomina Bala Mohammed ipinlẹ Bauchi, Dauda Lawal Zamfara, Ahmadu Fintiri ipinlẹ Adamawa ati Seyi Makinde ipinlẹ Oyo lawọn gomina mẹrin ọhun.

Ile ẹjọ giga l'Abuja paṣẹ idaduro ipade apero PDP n'Ibadan

Ṣaaju ni ede-ai-yede ti n ṣẹlẹ ninu PDP tawọn igun minisita Abuja, Nyesom Wike ati igun adele alaga ẹgbẹ naa, Umar Damagum ti n bara wọn fa aawọ lori ipade apero ẹgbẹ naa.

Eyi lo mu gomina ipinlẹ Jigawa tẹlẹ, Sule Lamido gba ile ẹjọ giga niluu Abuja lọ, lẹyin ti ko lanfaani lati ra fọọmu ti yoo fi dije fun ipo alaga ẹgbẹ PDP.

Lẹyin naa ni ilẹ ẹjọ giga apapọ niluu Abuja tun paṣẹ lọjọ Ẹti wi pe apejọpọ ẹgbẹ oṣelu PDP ọhun ko gbọdọ waye niluu Ibadan.

Nigba ti Adajọ Peter Lifu n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ ti gomina ipinlẹ Jigawa tẹlẹ, Lamido pe, adajọ ni ipade naa ko gbọdọ waye titi ti ẹgbẹ oṣelu PDP yoo fi tẹle alakalẹ iwe ofin ẹgbẹ naa.

Adajọ LIfu ni PDP ko gbọdọ ṣe ipade apero wọn niluu Ibadan titi ti Lamido yoo fi gba fọọmu ti yoo fi dije fun ipo alaga ẹgbẹ naa.

Ile ẹjọ tun paṣẹ wi pe ajọ eleto idibo INEC ko gbọdọ dasi ipade apero ti PDP fẹ fi ipa ṣe niluu Ibadan bakan naa.

Adajọ Lifu ni ko si idi fun PDP lati kọ eti ikun si idajọ ti Adajọ James Omotosho ile ẹjọ giga apapọ ilu Abuja gbe kalẹ tẹlẹ wi pe ki wọn ṣẹwe le ipade apero naa.

Ti ẹ o ba gbagbe, aarẹ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja tẹlẹ, Bukola Saraki, naa rọ ẹgbẹ osẹlu PDP lati da ipade naa duro tori gbogbo ọrọ to wa nilẹ.

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo fontẹ lu ipade apero PDP n'Ibadan

Ẹwẹ, Adajọ Ladiran Akintola ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo ti paṣẹ pe ki ẹgbẹ oṣelu PDP tésiwaju pẹlu ipade apero to fẹ ṣe lonii ọjọ Abamẹta ati lọla ọjọ Aiku niluu Ibadan.

Ninu ọrọ rẹ, Adajọ Akintola sọ fun ajọ INEC wi pe ki o wa nibi ipade apero naa, ki o si wo o bi o ṣe n lọ.

Alaga PDP lẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria, Ajisafe sọ pe oun ko mọ nipa aṣẹ ti adajọ Lifu ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja pa wi pe ki PDP da ipade apero wọn ni Ibadan duro.

''Ago mẹfa ti fẹ lu bayii, ko si ọkankan ninu awọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP to mọ ohun kan tabi omiran nipa aṣẹ ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja..

Ipade apero PDP yoo tẹsiwaju, ko si nnkan ti yoo ṣẹlẹ tori aṣẹ ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo la n tẹle,'' Ajisafe loi sọ bẹẹ.