Àlàyé rèé lórí ohun tó ń fa ìjà láàárín Boko Haram àti ISWAP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ iroyin AFP ti jabọ pe ko din ni eeyan 150 si 200 to jade laye lẹyin ija to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ati ISWAP lagbegbe Lake Chad.

A gbọ pe agbegbe Dogon Chiku ni ija naa ti bẹ silẹ laarin igun mejeji lọjọ Aiku.

Ninu fidio ti a foju ri amọ ti a ko le fidi rẹ mulẹ ni a ti ri awọn eeyan naa ti wọn n dana ibọn ya ara wọn lati inu omi.

Fijilante kan to ba awọn akoọroyin sọrọ ni igun mejeji lo padanu ọmọ ogun amọ awọn ti ISWAP padanu pọ ju ti Boko Haram lọ.

Onimọ nipa eto abo, Audu Bulama Bukarti, to ba BBC sọrọ yanana ohun to n fa ija laarin igun mejeji ọhun.

O ni o jọ bii pe igun Boko Haram to yapa kuro labẹ Abubakar Shekau n ri iranlọwọlati ọwọ ISWAP.

Amọ kii ṣe igba kọkọ ree ti ija yoo waye laarin igun mejeji latari pe lati ọdun 2016 ti tirela ti gba aarin wọn kọja ni wọn ti maa n ja.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ija laarin igun Boko Haram mejeji ti mu o kere tan, ẹmi eeyan 900 lọ.

Iwọyin ni awọn ohun to n fa ija laarin igun ẹgbẹ Boko Haram memeji.

Igbagbọ wọn yatọ sira

Onimọ nipa eto abo naa ni ohun kan gboogi to n fa ija laarin Boko Haram ati SWAP ni igbagbọ ọtọtọ ti wọn ni.

Bulama Bukarti sọ pe "Lati ibẹrẹ pẹpẹ, adari Boko Haram ti wọn ṣekupa, Abubakar Shekau sọ pe pe ẹnikẹni ti ko ba darapọ mọ ẹgbẹ naa, yala o gbagbọ ninu Alah ni o tabi o n gbaawẹ to si n gbadura, gbọdọ dero ọrun.

"Awọn ọmọ ogun ISWAP gbagbọ pe alaigbagbọ ni ẹnikẹni ti ko ba darapọ mọ awọn, irufẹ ẹni bẹẹ si gbọdọ fi aye silẹ."

Lati ṣafihan ẹni to lagbara julọ ninu wọn

Onimọ nipa eto abo mii to tun jẹ adari ileeṣẹ Beacon Consulting, Kabiru Adamu, sọ pe nnkan mii to tun fa ija laarin wọn ni lati ṣafihan igun to lagbara julọ ninu awọn mejeji.

O fi kun ISWAP ti lagbara gidi bayii lagbagbe Lake Chad nigba ti Boko Haram lagbara lagbegbe Sambisa Forest.

Adamu fi kun pe awọn ẹgbẹ mejeji n ja si awọn alumọni to tun wa lawọn ilẹ ti wọn gba.

Ẹni ti yoo maa ṣejọba agbegbe

Bulama Bukarti sọ pe lati ibẹrẹ pẹpẹ ni ede aiyede ti maa n waye nipa awọn ti yoo maa ṣejọba awọn agbegbe ti wọn bori.

Bukarti ni "Ija n waye lori awọn ti yoo maa ṣakoso awọn ilu ti wọn gba lagbegbe Lake Chad, paapaa nipa owo ori gbigba nibẹ.

"To fi mọ ẹni ti yoo maa gba owo ori lọwọ awọn apẹja, atawọn ti yoo maa ṣakoso awọn ọna ti wọn ti n ko ohun ija ogun wọle."

Kabiru Adamu faram ohun ti ẹnikeji rẹ sọ, o ni wọn maa n ja lori awọn ti yoo ṣakoso ibi ti owo ori ti n wọle fun wọn.

Bi ija Boko Haram ati Iswap ṣe bẹrẹ

ISWAP ni igun agbesunmọmi to yapa kuro lara Boko Haram, ti wọn si darapọ mọ ẹgbẹ alakakiti ẹsin Islami State IS lọdun 2016.

Lati asiko ti wọn ti pinya ni oniruru ija ti maa n waye laarin ẹgbẹ mejeji, paapaa lagbegbe Lake Chad.

Yatọ si ISWAP, awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmi miran tun ti yapa lati ara Boko Haram lẹyin ede aiyede nipa adari to maa waye laarin wọn.

Ija ISWAP ati Boko Haram tunbọ lagbara siwaju si lẹyin ti wọn ṣekupa olori Boko Haram, Abubakar Shekau ni Sambisa Forest.

Koda, awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram kan ti lọ darapọ mọ ISWAP nigba ti awọn mii lọ jọwọ ara awọn fun ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiiria.

Wayi o, o le ni ẹgbẹrun lọna ogoji eeyan ro ti jade laye lẹyin ti igbesunmọmi ti bẹrẹ ni Naijiria, eeyan to si le ni miliọnu meji lo ti di alairilegbe lati ọdun 2009.

Ija awọn agbesunmọmi naa tun ti ṣakoba fun awọn orilẹede to yi Naijiria kan bii Niger, Chad ati Cameroon.