Àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ fọnmú lórí àdéhùn owó oṣù tó kéré jùlọ, wọ́n ní yóò sọ ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ sóko gbèsè

Àwòrán Ìpàdé àwọn gómìnà àti ìwọ́de ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, NGF/FACEBOOK

Bí àwọn òṣìṣẹ́ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń dúró de kí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fi àbá lórí owó oṣù tó kéré jùlọ tuntun ránṣẹ́ sí ilé aṣòfin fún ìjíròrò àti ìbuwọ́lù, ẹgbẹ́ àwọn gómìnà ní ṣíṣe àmúṣẹ owó oṣù tuntun náà ṣeéṣe kó sọ ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ sóko gbèsè.

Àtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ àwọn gómìnà, Nigeria Governors Forum, NGF, gbé jáde ní iye tí àwọn gómìnà ń ná lásìkò yìí lágbára ju kí wọ́n tún mú àlékún bá owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ lọ.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, owó tí àwọn ìpínlẹ̀ Abia, Ekiti, Gombe, Imo, Katsina, Kogi, Oyo, Plateau, Sokoto, Yobe àti Zamfara ń ná ti ń sọ wọ́n sínú oko gbèsè láti ọdún 2022.

Ìpínlẹ̀ mẹ́tàlá ni wọ́n ní yóò wọ gbèsè tí àlékún bá bá iye tí wọ́n fi ń san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú ìdá àádọ́ta.

"Iye tí àwọn gómìnà yóò máa fi san owó oṣù máa lékún pẹ̀lú ìdá ọgọ́rùn-ún"

Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́bọ̀ tó kọjá ni àwọn gómìnà ẹkùn gúúsù Nàìjíríà gbé àtẹ̀jáde kan jáde níbi tí wọ́n ti sọ pé ó yẹ kí wọ́n gba àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan láàyè láti jíròrò pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ lórí iye tí wọ́n yóò máa san ní ìpínlẹ̀ kóówá wọn.

Àmọ́ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, NLC fèsì padà fún àwọn gómìnà náà pé wọn kò láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú òfin tó de owó oṣù tó kéré jùlọ.

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ fẹnukò lórí ₦62,000 àmọ́ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ₦250,000 ni àwọn ń fẹ́.

Àtẹ̀jáde NGF ní tí wọ́n bá buwọ́lu ₦62,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ, ó túmọ̀ sí pé iye tí àwọn gómìnà yóò máa fi san owó oṣù máa lékún pẹ̀lú ìdá ọgọ́rùn-ún.

Wọ́n ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi Anambra, Bayelsa, Borno, Ebonyi, Gombe, Imo, Jigawa, Kaduna, Eko ati Rivers nìkan ni yóò máa rí owó náà san láì jẹ gbèsè.

"Ìpínlẹ̀ Eko nìkan ló ń pawó wọlé lábẹ́nú jùlọ, tó sì lè san owó oṣù tó kéré jùlọ láì wọ gbèsè"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àtẹ̀jáde náà tún fi kún pé ìpínlẹ̀ Abia tó ní òṣìṣẹ́ 58,631 ń lo ₦5,837,899,980.40 láti fi san owó oṣù ní oṣooṣù.

Anambra ní tirẹ̀ tó ní àwọn òṣìṣẹ́ 20,541 ń lo ₦1,824,851,308.96 yàtọ̀ sí owó tí wọ́n fi ń ṣàn owó oṣù.

Nínú gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tó wà ní Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Eko nìkan ló ń pawó wọlé lábẹ́nú jùlọ tó sì lè san owó oṣù tó kéré jùlọ láì wọ gbèsè.

Títí di àsìkò yìí, ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún ni kò ì tíì máa san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ.

Igbákejì akọ̀wé ẹgbẹ́ NLC, Chris Onyeka nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn gómìnà ni kò tẹ̀lé òfin tó de owó oṣù òṣìṣẹ́.

Ó ka àwọn ìpínlẹ̀ Abia, Bayelsa, Delta, Adamawa, Niger, Sokoto, Imo, Anambra, Taraba, Benue àti Zamfara bíi àwọn tí kò ì tíì máa san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ.

Gomìnà ìpínlẹ̀ Zamfara, Dauda Lawal kéde pé òun máa bẹ̀rẹ̀ sí ní san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù Kẹfà ọdún 2024.

Níbi ìpàdé tí gómìnà Lawal ṣe pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ló ti kéde náà.