You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Hamas ní òun kò yìnbọn, àmọ́ wọ́n pa mí lọ́mọ - Ìyá tí wọ́n pa ọmọ rẹ̀ kérora
Bi wọn ṣe n gbe Tsachi Idan kuro ni Gaza, niṣe ni gbogbo ọwọ rẹ kun fun ẹjẹ ọmọ rẹ obinrin ti wọn yinbọn fun.
Wọn ko tiẹ fun ni anfaani lati fọ ọwọ rẹ lẹyin to gbe ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mejidinlogun naa ti ọkunrin agbẹbọn Hamas yinbọn pa niwaju awọn ẹbi rẹ mọra.
Bẹẹ si ni wọn ko fun laaye lati nu ẹjẹ ara awọn ọmọ rẹ kekere meji, ko to di pe iro ibugbamu to dun niwaju ita ile wọn ṣẹlẹ.
Ati pe titi gbogbo wahala naa fi pari ni awọn Hamas fi n gba foonu awọn mọlẹbi yii lati maa fi ya fọnran bi awọn ẹbi naa ṣe n kerora lori ikanni ayelujara ti facebook.
Gali Idan, to jẹ iyawo Tsachi ni wọn sọ pe oun ti wa ni ọna to jinna si awọn ayanfẹ rẹ ti Nahal Oz, ọkan lara awọn agbegbe to wa ni Guusu Israel ti wọn kọlu lọjọ keje, oṣu kẹwaa.
Gali ati awọn ọmọ rẹ ti ori ko yọ ni wọn wa ni ibi ọtọọtọ ti wọn pe ni kibbutz, nibi ti wọn ti n gba itọju, ṣugbọn ibẹ kii ṣe ile wọn.
Ile wọn ni ti n gbe latigba ti Maayan, ọmọ ti wọn pa yii ti wa ni ọmọ ọdun mẹrin. Ile naa ni wọn ti jọ gbe dagba fun ọjọ pipẹ pẹlu ọpọlọpọ iriri manigbagbe ti wọn ti jọ ni, to si tun jẹ pe ibẹ ni wọn bi awọn aburo ẹ mejeeji si.
Maayan, to jẹ akọbi ọmọ wọn to dagba ju ni wọn sọ pe o maa n tiju pupọ, o si gbọn daadaa. Ọmọbinrin to pe ni, gẹgẹ bi awọn ara adugbo wọn ṣe sọ.
Wọn ni o ṣẹṣẹ pari idanilẹkọọ ọkọ wiwa to lọ kọ ni, to si ti ni ọrẹkunrin rẹ akọkọ. O fẹran lati maa ka iwe, ati pe o ṣẹṣẹ beere fun ẹbun ọpọ iwe ti yoo maa ka bi ayẹyẹ ọjọ ẹ ṣe ku ọjọ mẹrin, ko to di pe wọn pa a.
Gali, Iya rẹ lo sọ eyi, to si ni ko tun le dagba ju ọdun mejidinlogun lọ mọ titi lai.
Nigba to n fi ibanujẹ sọrọ labẹ igi to jokoo si, Gali sọ pe oun ko fẹ maa ranti ọjọ buruku eṣu gbomimu naa mọ, nitori pe ibanujẹ lo n jẹ f’oun, ṣugbọn toun yoo sọrọ nitori ọkọ oun, Tsachi.
"Mo fẹ ko pada wa ni aaye. Mo tun fẹ maa ri i."
Lọjọ keje, oṣu kẹwaa, iro ikilọ lo ji awọn mọlẹbi yii loju oorun ni aarọ ọjọ naa, iro rọkẹẹti to wa lati Gaza. Nnkan da yatọ gedengbe ni aarọ ọjọ naa.
“Iru nnkan bẹẹ ko ṣẹlẹ, o si ko ipaya sọkan wa. Ikọlu nla gidi ni. A ko le jade lati lọ min. Niṣe la to ara wa mọ inu ahere kan, ibi isadi to wa ninu ile wa ni.
“Emi ati Tsachi wo ara wa loju, a si sọ nnkan to n ṣẹlẹ yii ko dara. Nnkan ibẹru lo n ṣẹlẹ.
“A gba awọn atẹjiṣẹ lori ẹrọ inu ibi ti a sapamọ si naa wi pe a ti wa labẹ ikọlu nla, ati pe a ni lati fi ara pamọ si ibi ti a wa, ka si ma ṣe jade lọ si ibikibi. Nigba to to asiko kan, wọn sọ pe a ko gbọdọ sọrọ, ki a wa ni idakẹrọrọ, nitori pe o ṣee ṣe ki awọn agbebọn wa digun ba wa nibi ti a wa.
“Ẹ ni lati mọ pe nibi ti ọrọ de naa, a ko ni ohunkohun lati ṣe. Niṣe lo n dabi ẹni pe a wa loju oorun, a si n la ala ninu ala, ṣugbọn a mọ pe awọn eleto aabo yoo wa ọna abayọ si ohun to n ṣẹlẹ yii. Lojiji, la rii pe kii ṣe ala mọ, o ti wa a di okodoro”
Gali ṣalaye bi nnkan ṣe ṣẹlẹ ni asiko naa, to ni awọn rii pe ibugbamu ṣẹlẹ ni ita ile wọn, to si fọ gbogbo gilaasi oju ferese wọn danu.
Igba to ya lo sọ pe awọn n gbọ iro ẹsẹ ati ohun ninu ile wọn.
O ni ọkunrin kan fi ede oyinbo pariwo wi pe ‘a ko yinbọn,’ ṣugbọn wọn yinbọn.
“Tsachi di ilẹkun ibi ti a wa mu, ko si jẹ ki wọn le ri ilẹkun naa ṣi. Kii ṣe pe kọkọrọ wa lẹnu ilẹkun yii, awọn ọmọ si bẹrẹ sii pariwo, oriṣiriṣi ariwo lo n waye ninu yara. Okunkun ti ṣu bolẹ, ṣugbọn gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii lo ye Maayan.
“O rii pe awọn to wa lẹnu ọna yii ti n ṣi ilẹkun naa, lo jẹ ko fo dide lati ran baba rẹ, Tsachi lọwọ, wọn si jọ di ilẹkun naa mọ.”
Omije bẹrẹ sii bọ loju Gali bo ṣe n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ siwaju
“Awọn eeyan naa n pariwo wi pe ‘a ko yinbọn’, ṣugbọn wọn pada yinbọn naa. Nibẹ ni Tsachi ti bẹrẹ sii pariwo wi pe ‘taani ibọn ba, taani ibọn ba?’ Ṣugbọn o rii pe Maayan ni.
“Maayan ṣubu lulẹ lẹgbẹ ẹ, eyi lo si fun awọn Hamas naa lanfaani lati ṣilẹkun wọle. Ariwo sọ gidi, wọn si tan ina inu ibi ti a wa.
"Inu agbara ẹjẹ nla Maayan wa. Nigba ti mo maa wo o, mo rii pe ori ni wọn ti yinbọn fun un, o si ti farapa gidi gan-an. Wọn sọ fun wa pe ka jade kuro nibi ti a wa.
“A kan sọ fun awọn ọmọ wa wi pe wọn ko gbọdọ wo ohun ti wọn ri, mo si lewaju wọn jade sita. Ogun nla lo n ṣẹlẹ layika ile mi, awọn Hamas tun wa ninu ile.”
Inu aṣọ awọsun ni Tsachi, Gali ati awọn ọmọ wọn mejeeji, Yael, ọmọ ọdun mọkanla ati Shachar, toun jẹ ọmọ ọdun mẹsan wa nilẹẹlẹ ti wọn jokoo si.
Ibẹ ni ọkan lara awọn to ko ogun wa ba wọn yii ti mu ẹrọ ibanisọrọ Gali, to si beere fun ohun to fi n ṣii, ko to di pe o bẹrẹ sii ya fọnran ohun to n ṣẹlẹ si awọn mọlẹbi yii sori ikanni ayelujara Facebook.
Fọnran naa ba ni lọkan jẹ lati wo. Fun iṣẹju mẹrindinlọgbọn, a ri awọn mọlẹbi naa ti n ra nilẹ bi iro rọkẹẹti ṣe n dun lakọ-lakọ, ti awọn Hamas si n ṣe ikọlu lọ.
Awọn ọmọ naa n sunkun gidi lọwọ awọn obi wọn nibi ti wọn wa, ati pe fun gbogbo asiko yii, oku Maayan wa nilẹ nitosi ibi ti wọn wa.
"Si oriire mi, awọn ọmọ mi ṣe ọkan akikanju lọna ti ko si ẹni to le ṣalaye. Wọn ba awọn agbebọn naa sọrọ, mi o mọ ibi ti wọn ti ri igboya ọhun. Wọn n beere idi ti wọn fi wa ṣe ikọlu naa, ati idi ti wọn fi n yinbọn, ti wọn si n pa awọn eeyan. Boya ki n sọ pe ohun to ko wa yọ niyẹn.
“Ọkan ọkọ mi gbọgbẹ pẹlu bo ṣe n wo oku ọmọ rẹ nilẹ, o n wo bi wọn ṣe yinbọn fun un ni ori, to si ku si ẹgbẹ rẹ. Ọmọbinrin rẹ to ṣẹṣẹ ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlogun.
“Gbogbo inu ile kun fun oriṣiriṣi feere ati iwe ikini, ati...ati ẹjẹ.”
Gali sọ pe nigba to ya, wọn sọ fun Tsachi ko dide, wọn si de ni okun lọwọ sẹyin. Awọn ọmọ bẹrẹ sii pariwo wi pe wọn ko gbọdọ mu baba wọn lọ, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ pa a, ṣugbọn wọn gbe e sinu mọto, wọn si gbe e lọ.
Sharon to jẹ ọmọbinrin keji Gali to tun dagba ju bayii, ẹni toun wa ni Tel Aviv lasiko ikọlu naa lo n rọ mama rẹ bo ṣe n fi ibanujẹ sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ.
Ọmọ ọdun mẹẹdogun naa lo gbiyanju lati ba baba rẹ sọrọ lori foonu lasiko ikọlu ọhun.
“Sharon, a wa ninu wahala bayii, maa ba a sọrọ to ba ya, mo nifẹẹ rẹ.” Ọrọ ti Tsachi ba ọmọ rẹ sọ gbẹyin ree ko to pa foonu.
“Nigba to maa kuro nile, mo sọ fun un pe mo nifẹ rẹ ‘ma jẹ akikanju, jẹ ọlọgbọn. Tọju ara rẹ, ki o si pada sile wa ba mi’. Ohun ti mo sọ ree. Mo ṣi n fẹ ko pada wa ba mi layọ ati ilera pipe.
“Tsachi ni lati wa nibi, ko le kẹdun iku ọmọ rẹ. Mo ni lati di mọ ọn.”
Israel ti ni akọsilẹ awọn ti ko din ni igba ti awọn Hamas to wa ni Gaza ti ko lẹru lọ. Kaakiri Israel ati kaakiri agbaye, ọkan awọn eeyan n gbọgbẹ gidigidi.
“Mi o mọ ohun ti afojusun wọn jẹ, mi o mọ ohun ti wọn n fẹ. Wọn fẹẹ ri ara wọn gẹgẹ bii adẹrubaniyan. Ikooko adẹrubaniyan ni wọn jẹ.
“Ala ibẹru manigbagbe ni wọn jẹ loju awọn ọmọ wa. Mi o mọ bi mo ṣe le ṣapejuwe wọn, o dẹrubani pupọ. Mi o mọ igba ati asiko ti ọgbẹ yii yoo jina, ṣugbọn wọn gbọdọ da awọn ti wọn ko lọ pada, wọn gbọdọ da gbogbo wọn pada.”
Oku Maayan la ri ti wọn gbe sinu poosi ni alaafia lọọkan ibi ti wọn gbe e si niwaju awọn aga ti wọn to.
Aga ti wọn to silẹ ko to fun gbogbo awọn olubanikẹdun to wa nibẹ lati ṣe iranti ẹ, ti wọn si mu oriṣiriṣi ododo dani lati fi bu ọla ikẹyin fun un.
Bi awọn ẹbi ṣe n sọrọ manigbagbe nipa Maayan, bẹẹ l’awọn ọrẹ ati araadugbo naa ko gbẹyin ninu ọrọ iranti ti wọn n sọ nipa ọdọmọbinrin to fẹran bọọlu alafọwọgba ti a mọ si volleyball.
Gali ba gbogbo awọn olubanikẹdun to wa nibẹ sọrọ nipa ọmọ rẹ lai lo ẹrọ gbohungbohun, pẹlu bo ṣe gba awọn ọmọ rẹ yooku mu mọra.
Bẹẹ ni Yael, ọmọ ọdun mọkanla ati Shachar, toun jẹ ọmọ ọdun mẹsan naa n ronu nipa ọjọ manigbagbe buruku naa. Ẹgbọn wọn ti ku, bẹẹ ni baba wọn ko si nibẹ lati tu wọn lọkan.
Gbogbo awọn to wa nibẹ ni wọn ni imọlara wi pe Tsachi ko si nibẹ.
Gali sọ pe oun fẹ ki gbogbo agbaye gbọ orukọ okọ oun. Ati pe oun ṣetan lati ṣe ohunkohun ti yoo jẹ ki wọn fi silẹ kuro ninu igbekun to wa.
Puọ awọn olubanikẹdun naa ni wọn wọ aṣọ ti wọn ya Maayan ati Tsachi siwaju, ti wọn si tun kọ “Bring Tsachi back” sẹyin aṣọ naa.