You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìtàn Mánigbàgbé: Duro Ladipo fi òjò àti àrá ńlá sàmì ìpapòdà rẹ̀
Ni awujọ awọn oṣere tiata, odu ni oloogbe Duro Ladipọ, kii si ṣe aimọ fun oloko.
Bi onirese Duro Ladipọ ko si fingba mọ, eyi to ti fin silẹ ko to jade laye ko lee parun, tori pe o dabira lagbo tiata ko to jade laye.
Ṣe bo ṣe gbe iṣẹ tiata lọ soke okun ni ka sọ ni abi aimọye ere itage akọnilọgbọn to ti gbe ṣe nigba to wa loke eepẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe Duro Ladipọ ko si laye mọ, ọpọ awọn agba iwoyi ni ko lee gbagbe ere Ọba Koso, Sango, Ajagun Nla, Ẹda, Bode Wasinmi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ ba ṣe ka lori itakun agbaye Wikipedia, itan manigbagbe gbaa ni itan igbe aye oloogbe Duro Ladipọ, eyi to yẹ ki awọn ode iwoyi fi ṣe awokọṣe ati arikọgbọn gidi.
Ohun to yẹ ko o mọ nipa Duro Ladipọ:
- Ọjọ Kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 1931 ni Duro Ladipọ de ile aye, ti wọn si bii si ilu Osogbo, ṣe odo kii ṣan, ko ma ni orirun
- Ọmọlẹyin Kristi gidi, to wa lati idile onigbagbọ ni Duro Ladipọ, ti baba rẹ si jẹ ojiṣẹ Ọlọrun lati inu ijọ Angilika; amọ, baba baba rẹ to wa lati ilu Ọyọ ijọhun, jẹ Onisango ati Ọlọya
- Niwọn igba to jẹ pe ẹjẹ ni agbara, bi o tilẹ jẹ pe inu ẹsin igbagbọ ni wọn bi Duro si, sibẹ, o nifẹẹ si awọn ohun asa iṣẹnbaye gẹgẹ bi baba rẹ agba ti n ṣe.
- Nigba to wa ni ọmọde, o maa n yọ yẹlẹkẹlẹ kuro ni ile alufaa to wa ninu ọgba ṣọọṣi, lati lọ wo iran egungun ati awọn ajọdun oriṣa miiran ti wọn n ṣe nigba naa
- Duro Ladipọ lo bẹrẹ lilo awọn ilu iṣẹmbaye ninu ijọ ọmọlẹyin Kristi, ti wọn si le e kuro ninu ijọ nitori wọn ri iwa yii gẹgẹ bii eewọ nla
- Amọ lati akoko naa, aṣa yii ko parun, ti wọn si n lo ilu abalaye lasiko ọdun Keresi.
- Duro Ladipọ gba ami ẹyẹ latọwọ aarẹ Naijiria nigba naa, Ọmọwe Nnamdi Azikwe lasiko ọdun Keresi kan to waye ni ibudo iko nnkan iṣẹmbaye lọjọ si to wa ni Onikan, niluu Eko
- Ifẹ to ni si asa iṣẹmbaye yii si lo tii titi de idi tiata, ti ọpọ ere rẹ naa si maa n ṣe agbelarugẹ awọn ohun ajogunba wa nilẹ Kaarọ oojire
- Lẹyin ti Duro Ladipọ ka iwe tan nilu Osogbo, lo lọ si ilu Ibadan lati ṣe iṣẹ Olukọ lọdun 1960
- Idi iṣẹ olukọ lo ti dara pọ mọ ẹgbẹ oṣere tiata Mbari Mbayọ pẹlu iranlọwọ oyinbo alawọ funfun kan lati orilẹ-ede Germany, Ulli Beier, ẹni to nifẹẹ si awọn ohun iṣẹmbaye. Amọ ko pẹ lẹyin naa lo pada siluu Osogbo, to si da ẹgbẹ oṣere tiẹ silẹ lọdun 1961
- Duro Ladipọ ni ẹbun orin kikọ ati ilu lilu, eyi to maa n ṣe afihan wọn ninu ere rẹ, to fi mọ amulo owe pipa.
- Lara awọn ere tiata to si jẹ ki Duro Ladipọ di ilumọọka ni Ọba Moro eyi to ṣe lọdun 1962, Ọba Koso ati Ọba Waja, ti wọn jade lọdun 1964, Mọremi, Suuru baba Iwa, Tanimowo Iku, Bode Wasinmi, Ajagun nla ati bẹẹ bẹẹ lọ
- Duro Ladipọ lọ si ọpọ orilẹ-ede jakejado agbaye lati ṣe afihan ere ori itage rẹ.
- Lara awọn orilẹ-ede ti Duro Ladipọ atawọn ọmọ ẹgbẹ osere rẹ lọ ni Amẹrika, Holland, France, Italy, Yugoslavia, Iran, Belgium, Scotland, Swizerland ati bẹẹ bẹẹ lọ
- Ọpọ ami ẹyẹ ni Duro Ladipọ gba ninu ere tiata lorilẹ-ede Naijiria ati loke okun.
- Lara rẹ ni eyi to gba ni orilẹ-ede Germany nibi ajọdun iṣẹ ọna ti ilu Berlin lọdun 1964 ati ami ẹyẹ to gba ni ajọdun iṣẹ ọna Commonwealth lọdun 1965
- Ere tiata mẹrindinlogoji ni Duro Ladipọ kọ, to si ṣe jade, nigba to kọ ere mẹwaa, to si ko awo ere mẹsan an sita lori ẹrọ giramofoonu, to si ṣe ere fiimu mẹrin
- Lara awọn osere tiata ti wọn jẹ akẹgbẹ Duro Ladipọ ni Kọla Ogunmọla, Ọla Rotimi, Herbert Ogunde, Ayo Arisekọla, Ojo Ladipọ, Moses Ọlaiya Adejumọ (Baba Sala), Oyin Adejọbi, Isọla Ogunsọla (I show pepper) ati bẹẹ bẹẹ lọ
- Duro Ladipọ ni ọpọ iyawo, to si tun bi ọmọ pupọ, amọ eyi to jẹ aayo ninu awọn iyawo rẹ ti gbogbo aye mọ ni Mama Abiọdun Duro Ladipọ, to maa n ṣe ere Ọya, nigba ti Duro ba se Sango
- Ọjọ nla ni ọjọ Kọkanla, osu Kẹta, ọdun 1978 ti Duro Ladipọ mi kanlẹ, to si ki aye pe o digbose
- Gẹgẹ bii oriṣa Sango ti gbogbo eeyan mọ ọ si, apẹẹrẹ Sango lo jẹyọ lọjọ ti Duro Ladipọ jade laye, nitori ojo nla, to mu ara lọwọ lo rọ lọjọ naa, ti ara si n ṣana gidigidi.
- Asiko ojo ati ara nla yii naa si ni Duro Ladipọ mi kanlẹ, ti akukọ si kọ lẹyin ọmọkunrin rẹ.
Imọran BBC Yoruba lori itan manigbagbe akọni ọmọ Oodua yii:
Duro Ladipo ti wa sile aye, to si ti lọ amọ ko kọja nile aye gẹgẹ bii ejo to kọja lori apata, ti ko ni ipa kankan.
Kii kuku ṣe pe Duro Ladipọ ka iwe rẹpẹtẹ ko to ṣe aṣeyọri, amọ o lo ẹbun atinuda ti Ọlọrun fun-un lati ta ara rẹ yọ, to si di ilumọọka lawujọ agbanla aye.
Ki ni awọn talẹnti ti iwọ naa ro pe o ni? bawo lo si ṣe le lo talẹnti naa fun agbega iran rẹ, ti orukọ rẹ ko si ni di igbagbe?
Eyi lo yẹ ko jẹ ibeere ti yoo jẹ wa logun, ka si lọ ṣe awari talẹnti wa gẹgẹ bi Duro Ladipọ ti ṣe, kawa naa le wọ inu iwe itan manigbagbe.