You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tọkọ-taya ń fọ́ ṣọ́ọ̀bù, ṣe ‘affidavit’ lórí ẹrù tí wọ́n bá jí
Awọn ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo ti fi oju ọkọ ati iyawo kan lede fun ẹsun idigunjale.
Awọn afurasi ọhun, Adewale Olokungboye jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn nigba ti aya rẹ, Ngozi Kenneth jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.
Amotekun ni oun mu wọn fun ẹsun fifọ ṣọọbu lati ji ẹru ti owo rẹ to ọpọlọpọ miliọnu naira ni ilu Akure, to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ondo.
Adewale, to jẹ ọkọ iyawo, lo n gbiyanju lati di ẹbi iṣẹlẹ naa ru aya rẹ.
Ọkunrin naa ni oun ko mọ kankan nipa iṣẹlẹ naa titi di akoko tawọn Amọtẹkun fi wọle wa bawọn.
Aya mi lo lọ fọ ṣọọbu loru pẹlu Daniel ati Seun ninu ojo lọjọ naa, n ko mọ nkankan nipa rẹ - Adewale
Ẹwẹ, Adewale ni oun ko bi iyawo oun pe nibo lo ti ri ẹru to ko wọle ni idaji ọjọ to ko awọn ẹru naa wọle tori pe ko sunle lọjọ naa.
Arakunrin naa wi pe “aya mi lo lọ fọ ṣọọbu loru pẹlu Daniel ati Seun ninu ojo lọjọ naa.
Igba ti mo ji ni mo ri ẹru ti wọn ko wọle amọ mi o beere ibi ti wọn ti ri ẹru.
Ọjọ tawọn Amọtẹkun de, ni mo mọ pe n ṣe ni wọn lọ ji ẹru ọhun ni, ti iyawo mi si lọ ṣe iwe nile ẹjọ pe oun ni oun ni ẹru naa."
Adewale wi pe awọn ọlọpa SWAT ti mu oun ati iyawo oun ri lori ẹsun ole jija leyi to mu ki oun lọ sipinlẹ Ekiti lati maa gbe.
O ṣe alaye pe awọn ibeji ti Ngozi bi fun oun loun waa wo, ti amọtẹkun fi wa a mu oun pẹlu ọdaran aya ti oun fẹ.
Lootọ ni mo maa n ṣe iwe ‘affidavit’ nile ẹjọ pe emi lo ni awọn ẹru ti wọn ba ti ji ko - Ngozi
Ninu alaye tirẹ, Ngozi wi pe oun kọ loun wọle lati ko ẹru amọ oun lo gba ẹru naa lẹyin ti Daniel ati Seun ji ko.
Ngozi jẹwọ pe ni tootọ ni oun maa n ṣe iwe ‘affidavit’ nile ẹjọ pe oun lo ni awọn ẹru ti wọn ba ti ji ko.
Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Adetunji Adeleye, to fi oju tọkọ-taya ọdaran naa lede pẹlu awọn ọdara miran to to ọgbọn, ni gbogbo awọn afurasi naa ni yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ ọjọ, ni kete ti iwadi ba pari.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ilesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, lo ni awọn ọlọpaa ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.