You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló dé tí ariwo sọ pé wọn fẹ́ pa gómìnà Kogi, Yahaya Bello?
Ni ọjọ Aiku ni ariwo sọ pe awọn eeyan ti pete pero lati ran gomina ipinlẹ Kogi, Alhaji Yahaya Bello sọrun alakeji lopopona kogi si Abuja.
Yahaya Bello, ẹni to gbera nilu Lokoja gba Abuja lọ pẹlu mọto rẹ ni iroyin naa salaye pe awọn agbebọn kan, to wọ asọ Ileeṣẹ ologun kọlu nigba to ku diẹ ko wọ ilu Abuja.
Atẹjade kan ti Kọmisana feto iroyin nipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo fi lede fun awọn akọroyin, salaye pe ikọlu naa waye ni ago mẹrin, Ọjọ Aiku, ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, “Awọn agbegbọn yii mura gẹgẹ bi ọmọ ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria, ti wọn si da ọkọ Gomina duro.
Wọn si sina ibọn bolẹ fun awọn ọkọ to tẹle Gomina.
Akitiyan awọn ẹsọ alaabo to tẹlẹ Gomina lo dabaru erongba awọn agbẹbọn ọmọ ologun naa.”
"Ibudo mẹta ọtọọtọ ni awọn agbebọn ti kọlu Yahaya Bello lọna Abuja"
Atẹjade naa tẹsiwaju pe ibi mẹta ọtọọtọ ni ikọlu naa ti waye, eyi to waye gbẹyin waye ni agbegbe Kwali ni nnkan bi ago mẹrin abọ.
“Akọsilẹ awọn ikọlu yii ni a ti ṣe silẹ fun iwadii fun awọn ẹsọ alabo nipinlẹ Kogi ati lorilẹede Naijiria.
”Gẹgẹ bi ijọba, gbogbo ọna ti a sa ni lati ri pe awọn araalu wa ko ri idunkoko kankan eyi ti awọn oloṣelu kan n ṣe agbatẹru rẹ.”
Ko si nnkan to jẹ mọ pe awọn kan le pa ẹmi mi -Gomina Yahaya Bello
Gomina Ipinlẹ Kogi, Gomina Yahaya Bello ti wa salaye pe irọ to jinna sootọ ni pe awọn agbebọn kan fẹ pa oun.
O ni ko si nnkan to jẹ mọ pe awọn eeyan ti Kọmisọna rẹ ni wọn wọ asọ ologun fẹ ṣekupa oun tabi ṣekọlu si oun lasiko to n lọ olu ilu Abuja.
Gomina Bello, ninu fidio kan to se soju opo X rẹ, lo ti salaye bẹẹ.
Bello salaye pe gbolohun asọ kekere kan lo waye laarin awọn ọlọpaa to n tẹle oun ati awọn ọmọ ologun to wa loju ọna marosẹ Lokoja si Abuja , to si jẹ pe awọn ẹsọ alabo mejeeji n sisẹ wọn ni.
Gomina ni ko si nnkan to jẹ mọ pe awọn kan fẹ ṣekupa oun, to si ni isẹ awọn oloṣelu kan to fa da alaafia ilu lamu saaju eto idibo Gomina to n bọ nipinlẹ naa ni eyi.
"Awọn ẹsọ alaabo mi atawọn akẹẹgbẹ wọn to wa loju ọna Abuja lo n tahun sira wọn, ko kan mi"
“Ohun to waye lọsan oni, mo n lọ si ilu Abuja, ti irinajo mi si lọ ni alaafia, nigba ti a rin siwaju diẹ, awọn ẹsọ alabo to n sọ mi ati awọn ẹsọ alabo miiran ni gbolohun asọ kekere kan.
“Kete ti mo da si ọrọ naa lo ni iyanju sugbọn ohun to ya mi lẹnu ni iroyin ti mo ri lori ayelujara pe awọn kan fẹ ṣekupa mi.
Mo n fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ko si nnkan to jẹ mọ pe awọn kan fẹ ṣe iku pa emi, Yahaya Bello, Gomina ipinlẹ Kogi, lasiko ti mo n rin irinajo lọ ilu Abuja.
“Nigba miiran gbolohun asọ ma n waye laarin awọn ẹsọ alabo lasiko ti wọn ba ṣe isẹ wọn.
Koda ko yẹ ki gbolohun asọ naa waye, mo dẹ rọ gbogbo ẹsọ alabo lati ṣe iwadii lori ohun to waye, ki wọn si fiya jẹ ẹni to yẹ.”
Bello wa kan sara si awọn ẹsọ alabo fun ifọwọsowọpọ wọn to lati ripe wọn da bobo emi ati dukia awọm araalu ipinlẹ Kogi.
Ọdaran ni awọn ti wọn ṣekọlu si Yahaya Bello, ki ṣe awọn ọmọ ologun - Ileeṣẹ Ologun.
Ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria ti fọhun sita lori iroyin naa, to si ni ki i ṣe awọn ọmọ ologun Naijria lo ṣe ikọlu si Gomina Ipinlẹ Kogi.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Brig Gen Tukur Gusau ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ pe awọn ọdaran lo ṣe ikọlu si Gomina, ko ki ṣe ileeṣẹ ologun rara.
“Inu wa kodun si isẹlẹ yii, sugbọn a n jẹ ko di mimọ pe ko ki ṣe awọn ọmọ ileeṣẹ ologun lo ṣekọlu si ọkọ Gomina ipinlẹ Kogi.
“Wọn ni awọn agbebọn yii wọ asọ ileeṣẹ ologun, a n rọ Ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadi lori isẹlẹ yii, ki wọn si mu awọn to lọwọ ninu ikọlu naa.”