Tọkọ-taya ń fọ́ ṣọ́ọ̀bù, ṣe ‘affidavit’ lórí ẹrù tí wọ́n bá jí

Awọn ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo ti fi oju ọkọ ati iyawo kan lede fun ẹsun idigunjale.

Awọn afurasi ọhun, Adewale Olokungboye jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn nigba ti aya rẹ, Ngozi Kenneth jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.

Amotekun ni oun mu wọn fun ẹsun fifọ ṣọọbu lati ji ẹru ti owo rẹ to ọpọlọpọ miliọnu naira ni ilu Akure, to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ondo.

Adewale, to jẹ ọkọ iyawo, lo n gbiyanju lati di ẹbi iṣẹlẹ naa ru aya rẹ.

Ọkunrin naa ni oun ko mọ kankan nipa iṣẹlẹ naa titi di akoko tawọn Amọtẹkun fi wọle wa bawọn.

Aya mi lo lọ fọ ṣọọbu loru pẹlu Daniel ati Seun ninu ojo lọjọ naa, n ko mọ nkankan nipa rẹ - Adewale

Ẹwẹ, Adewale ni oun ko bi iyawo oun pe nibo lo ti ri ẹru to ko wọle ni idaji ọjọ to ko awọn ẹru naa wọle tori pe ko sunle lọjọ naa.

Arakunrin naa wi pe “aya mi lo lọ fọ ṣọọbu loru pẹlu Daniel ati Seun ninu ojo lọjọ naa.

Igba ti mo ji ni mo ri ẹru ti wọn ko wọle amọ mi o beere ibi ti wọn ti ri ẹru.

Ọjọ tawọn Amọtẹkun de, ni mo mọ pe n ṣe ni wọn lọ ji ẹru ọhun ni, ti iyawo mi si lọ ṣe iwe nile ẹjọ pe oun ni oun ni ẹru naa."

Adewale wi pe awọn ọlọpa SWAT ti mu oun ati iyawo oun ri lori ẹsun ole jija leyi to mu ki oun lọ sipinlẹ Ekiti lati maa gbe.

O ṣe alaye pe awọn ibeji ti Ngozi bi fun oun loun waa wo, ti amọtẹkun fi wa a mu oun pẹlu ọdaran aya ti oun fẹ.

Lootọ ni mo maa n ṣe iwe ‘affidavit’ nile ẹjọ pe emi lo ni awọn ẹru ti wọn ba ti ji ko - Ngozi

Ninu alaye tirẹ, Ngozi wi pe oun kọ loun wọle lati ko ẹru amọ oun lo gba ẹru naa lẹyin ti Daniel ati Seun ji ko.

Ngozi jẹwọ pe ni tootọ ni oun maa n ṣe iwe ‘affidavit’ nile ẹjọ pe oun lo ni awọn ẹru ti wọn ba ti ji ko.

Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Adetunji Adeleye, to fi oju tọkọ-taya ọdaran naa lede pẹlu awọn ọdara miran to to ọgbọn, ni gbogbo awọn afurasi naa ni yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ ọjọ, ni kete ti iwadi ba pari.

Ẹwẹ, agbẹnusọ ilesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, lo ni awọn ọlọpaa ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.

Òṣìṣẹ́ LASTMA mẹ́rìnlá kojú ẹ̀sùn ìfipágbowó lójú pópó, wàhálà dé!

Osisẹ ajọ to n ri si irinna oju popo nipinlẹ Eko LASTMA mẹrinla lo ti wọ gau, ti wọn yoo si foju ba igbimọ to n da sẹria fun awọn osisẹ ijọba.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn osisẹ LASTMA naa ni pe wọn n fipa gbowo lọwọ awọn awakọ nipinlẹ naa.

Atẹjade ti agbẹnusọ fajọ LASTMA, Adebayo Taofiq buwọlu fun akọroyin, to si gbe sita soju opo ayelujara X LASTMA, ni iroyin yii ti jẹyọ.

Awọn osisẹ yii ni wọn yoo maa jẹjọ niwaju igbimọ to n da sẹria fawọn osisẹ ọba.

Agba osisẹ mọkanla ati awọn osisẹ kekere mẹta ni awọn osisẹ ti akara wọn tu sepo lori ẹsun iwa ibajẹ yii.

Ajọ LASTIMA si fọwọ sọya pe oun yoo fiya jẹ wọn ni ilana to ba ofin ipinlẹ Eko mu.

Ọga agba fun ajọ LASTMA, Bolaji Oreagba salaye pe awọn osisẹ naa ni igbimọ ijọba to n fiya jẹ awọn osisẹ (PMB) ti ṣe iwadi lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

"Awọn agbegbe ọtọọtọ yika ipinlẹ Eko ni awọn osisẹ LASTMA mẹrinla naa ti sẹ sofin"

Oreagba fikun pe igbimọ yii yoo da sẹria fun awọn osisẹ ni ilana ti ijọba ti pese silẹ lati fiya jẹ awọn osisẹ ijọba to ba lugbadi ofin.

“Awọn osisẹ mọkanla yii ni wọn sẹ si ofin ifipagbowo ni agbegbe ọtọọtọ kakari ipinlẹ Eko, ti wọn si n gba riba lọwọ awọn awakọ.”

O ni ajọ LASTMA ko ni dẹkun lati ri daju pe awọn osisẹ rẹ sisẹ wọn ni ilana ti ijọba la silẹ, ti wọn yoo si gba ijiya ofin lasiko ti wọn ba gbe igbesẹ to tako ilana ajọ ọhun.

O wa rọ awọn osisẹ LASTMA yoku ati fi yi ṣe arikọgbọn, ki wọn si sisẹ wọn lai bẹru ni ilana ti ijọba ti pese fun wọn.

Ọwọ́ tẹ ọlọ́pàá mẹ́ta l'Ogun lórí ẹ̀sùn ìfipágbowó lọ́wọ́ àwọn ọlọ́kadà

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọlọpaa mẹta lori ẹsun ifipagbowo lọwọ awọn to n fi alupupu gbero ti ọpọ mọ sì ọlọkada.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọmọlọla Odutọla gbe jade lonii, ọjọ Aiku, o sọ pe aṣiri awọn ọlọpaa naa tu ninu fọnran kan to tan kaakiri ori ikanni ayelujara laipẹ yii.

Odutọla sọ pe ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 yii ni awọn ọlọpaa mẹta naa, Ikhanorba Lucky, Paul Sunday, ati Edwin Ekeogu n gba owo lọwọ awọn ọlọkada ati awọn to n wa Kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta tàwọn eeyan mọ si Maruwa lagbegbe Maawu to wa ni Agbado.

O ni ibi ti wọn ti n gba owo naa, l’awọn araalu ti bẹrẹ si ni ya wọn lai jẹ ki wọn mọ, ti wọn si gbee sori ayelujara.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni iwa to lodi sí ofin to da iṣẹ ọlọpaa silẹ ni iru iwa yii.

Ni kete ti fọnran naa ti tẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiọdun Alamutu lọwọ lo ti paṣẹ pe awọn mẹta naa gbọdọ jẹ iyan wọn n’iṣu, nitori pe ko si ẹni to ran wọn ni iṣẹ ti wọn n ṣe.

O ni wọn ti wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo nipa idi ti wọn fi lọ n gba owo ti ko tọ lọwọ araalu.

Ọga ọlọpaa Alamutu ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo ọlọpaa jakejado ipinlẹ Ogun lati jawọ ninu iwa ilọnilọwọgba pẹlu awọn araalu, nitori pe agbofinro to gbọdọ gbajumọ ofin ati ilana iṣẹ naa ni wọn.