You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gómìnà, aráàlú kí ọkùnrin tó rìn láti Eko sí Port Harcourt fún ọjọ́ márùn-ún káàbọ̀
Ijọba ipinlẹ Rivers ti gbe oṣuba kare fun gendekunrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Promise Nwosu lori bo ṣe rin lati ilu Eko lọ si ilu Port Harcourt, to si jẹ pe oun ni ẹni akọkọ ti yoo rin iru irin bẹẹ lagbaye pẹlu ẹsẹ nikan.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun ti a wa yii ni Nwosu, ẹni ti awọn eeyan mọ pe Wene Port Harcourt lori ikanni ayelujara gbera lati agbegbe Lẹkki Toll Gate n’ipinlẹ Ekoo, to si fi ẹsẹ rẹ rin de ilu Port Harcourt pẹlu ẹsẹ lasan, lai wọ mọto.
Erongba ọkunrin yii ni lati gba ami ẹyẹ ẹni akọkọ ti yoo rin irurẹ lọwọ Guniness World Record.
Ere ni awọn eeyan kọkọ pe e nigba ti Nwosu kede sita wi pe oun yoo fi ẹsẹ rin lati Eko si Port Harcourt, irin ti wọn lo le diẹ ni ẹgbẹta kilomita (606km).
A gbọ pe bi Nwosu ṣe wọ ilu Port Harcourt lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii ni awọn to da a mọ ti sare lọ pade ẹ, ti wọn si jọ kọwọrin pẹlu ẹ lọ si ile gomina.
Kete to ti debẹ ni wọn sọ pe Gomina ipinlẹ naa, Siminalayi Fubara ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Rivers ti pade rẹ, nibi ti wọn ti gbe oṣuba kare fun un, ti wọn si lo ti mu orukọ ipinlẹ naa wọnu iwe agbaye nipa igbesẹ akikanju naa.
Nibẹ ni Gomina Siminalayi Fubara ti ṣe ileri pe oun yoo wa nnkan agidi ṣe fun un nigba ti yoo ba fi di ọjọ Aje, Mọnde.