You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ fọkàn balẹ̀,epo tí yóò kárí aráàlú wà ní ìpamọ́ NNPCL
Ileeṣẹ to n ṣakoso epo rọbi lorileede Naijiria NNPCL ti kìlọ faraalu lati yago fun rira epo bẹntiroolu pamọ tori ìbẹru pe epo fẹ gbowo lori
Ikilọ yi waye lẹyin ti ọpọ araalu bẹrẹ si ni to sẹnu ọna ileepo tori aisi epo lẹnu ọjọ mẹta yi.
NNPCL sọ pe ikilọ yi ṣe dandan pẹlu bi oju ọna ṣe di ni olu ìlu Naijiria Abuja ati awọn ipinlẹ mii ni Naijiria.
Atẹjade lati ọdọ ileeṣẹ naa sọ pe awọn ti wa ojutu si nkan to n fa àìsí epo to mu k'awọn araalu maa to si ileepo.
Ki lo fa ọwọn epo?
NNPCL sọ pe adinku iye epo to n wa lati aaye iko epo pamọ si rẹ to wa ni Apapa nilu Eko lo ṣokunfa rẹ.
Amọ wọn ni bayi ti epo yanturu ti wa níbẹ ti yoo kaari lilo ọgbọn ọjọ lorileede naa gbogbo nkan yoo bọ sipo gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ.
Tori naa NNPCL ti wa kìlọ faraalu lati ma ṣe ra epo pamọ ni ibẹru pe epo ti fẹ gbowo lori tabi pe ko si epo.
"Laarin ọjọ diẹ gbogbo nkan yoo pada sipo nípa lilọ bibọ ati igbokegbodo ọkọ ni Naijiria"
Ọrọ ọwọn epo ni Naijiria jẹ nkan to n kọ araalu ninu.
Yatọ si pe iye owo jala epo ti lọ soke nitori yiyo ẹkunwo epo awọn oniṣowo epo ti n ke gbajare pe awọn ko ri epo ta debi pe yoo kari awọn ileepo ti araalu ti n ra lọwọ wọn.
Latẹyinwa asiko ti ipari ọdun ba ti n sunmọ jẹ igba tí araalu maa n kaya soke lori ọrọ epo.
Idi ni pe ọpọ lọ maa n rinrinajo ọdun keresimesi ti wọn a sí nilo epo bentiroolu sí ọkọ wọn.
Diẹ diẹ ki ọdun to de ni epo ti maa n wọn to si jẹ pe awọn ti n sọ ọjọ di ọwọn a maa fi ara ni araalu lara.