You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé ìwòsàn Gaza kún fún òkú èèyàn àtàwọn tó farapa torí ìkọlù Israel
Ni ileewosan Al-Aqsa Martyrs ni aringbungbun Gasa, wọn gbiyanju lati wa awọn ohun elo lati bo awọn oku.
Lara awọn oku naa ni wọn ti ko jọ si oju kan ni ita ile iwosan naa, ti awọn eeyan si n gbadura ni kikankikan, ti awọn mọlẹbi mii si n gbera sanlẹ.
Ninu ileewosan, awọn dokita n saapa wọn lati dola ẹmi awọn ti wọn fara gbọgbẹ.
Sugbọn awọn ile itaja oogun ati awọn ibudo ipese oogun n dinku si ni ojojumọ.
Asoju ikọroyin ileesẹ BBC Arabic fidi iṣẹlẹ mulẹ pe awọn ohun elo ti awọn dokita yoo fi siṣẹ lati dolaa ẹmi awọn eeyan ko to rara.
Diẹ ninu awọn aworan ti o ti jade lati ileewosan ni ọjọ Aiku jẹ awọn aworan to ba ni nu jẹ lati pin.
Awọn ọmọde, o kere ju, awọn ọmọ-ọwọ meji lo wa laarin awọn oku naa.
Awọn oṣiṣẹ to n risi eto ilera ni Gaza sọ pe awọn eniyan to le ni ọgọrun ni wọn ti jade laye bi ilẹ Israel ṣeṣe awọn ikọlu si afẹfẹ ni ooru mọju.
UNICEF ni ọmọde to le ni aadọjọ to wa ninu igo nile iwosan ni Gaza to n gba itọju
Nigba ti awọn ologun Israel n ba akọroyin BBC sọrọ, wọn ni awọn ti foju si awọn agbegbe kan to wa nitosi.
“Awọn iroyin to n tẹ wọn lọwọ lati ọdọ oludari Hamas kan ni agbegbe to wa lẹba ileewosan naa, sọ pe Hamas ti paṣẹ fawọn ologun rẹ lati maa yinbọn si awọn eeyan Israel to wa ni agbegbe yẹn".
Ni owurọ ọjọ Sundee ni a ri awọn ọkọ ayọkẹlẹ to n gbe awọn eniyan ti wọn fara gbọgbẹ lọ si ileewosan.
Nigba ti a n ba lara awọn osiṣẹ naa ṣọrọ, o ni:
“A ti wa nibi lati owurọ lati se itọju awọn eeyan to kun gbogbo agbala ileewosan patapata, to fi mọ awọn to wa lori oke, awọn eeyan inu ileewosan ati ni ita rẹ."
Ni ọjọ Aiku, ajọ Unicef kilọ pe awọn ọmọ-ọwọ to le ni ọgọfa niye lo wa ninu igo fun itọju.
Bakan naa, awọn ọmọ jojolo ti wọn to aadọjọ niye lo tun wa nibẹ pẹlu..