Afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn pàdé ikú òjijì lẹ́yìn eégún l'Osogbo

Aworan egungun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ikọlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun to waye lasiko ọdun egungun niluu Osogbo lọjọ Aiku, ọjọ kinni oṣu Kẹfa nibi ti eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo ọdun egungun to waye lagbegbe Oke Ola niluu Osogbo lati ṣe ikọlu si ara wọn.

DSP Ojelabi fi idi rẹ mulẹ pe afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Awoniyi Kazeem, ti inagijẹ rẹ jẹ ''Federal'' lo ku nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ibẹru boko gbalẹ kan latari iṣẹlẹ ọhun lagbegbe Oke Ola, ṣugbọn awọn ọlọpaa ṣiṣẹ wọn ti alaafia fi jọba pada ladugbo naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ẹlẹgbẹ okunkun meji lo tẹle Egungun ki wọn to kọlu ara wọn ti ija si bẹ silẹ.

DSP Ojelabi ni ''ajọdun egungun lo n lọ lọwọ lagbegbe Oke Ola niluu Osogbo, nibẹ lawọn ẹlẹgbẹ okunkun ti ṣe ikọlu si ara wọn.

Eeyan kan lo ku ninu ikọlu naa ti iwadii fi han pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni pẹlu.''

Afuarasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Kazeem to ku ninu ikọlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun l'Osogbo - Ọlọpaa

Ọlọpaa sọ pe ọdun mẹẹdọgbọn ni Awoniyi Kazeem to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Ni bayii, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, DSP Ojelabi ṣalaye.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn eeyan to n gbe ni adugbo ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ti n ran ọlọpaa lọwọ lori iwadii to n lọ.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun yoo fun araalu labọ lori ọrọ naa laipẹ ti iṣẹ iwadii ba ti pari.

Awọn ara adugbo ṣalaye ohun toju wọn ri nibi ikọlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun l'Osogbo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O-ṣoju-mi-koro kan sọ pe ori ni wọn ti yinbọn fun Kazeem, ẹni to tẹle egungun de agbegbe naa.

Ẹlomiran tun sọ pe ni nnkan bii aago meje irọlẹ ọjọ Aiku to kọja lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye ti wọn tẹle egungun kan de agbegbe Oke Ola kọju ija sawọn ẹlẹgbẹ okunkun mii eyi to ṣokunfa bi ọpọ eeyan ṣe farapa.

''Mo ri gbogbo nnkan to ṣẹlẹ nibi ti mo duro si, ọkunrin kan ti wọn n pe ni Tajudeen to jẹ olori ẹgbẹ okunkun Eiye lati Oke Baale lo tẹle egungun pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ lọ si agbegbe Oke Ola ti iṣẹlẹ naa fi waye.

Ẹgbẹ okunkun Eiye ti Tajudeen jẹ olori fun, lo kọlu ẹgbẹ okunkun mii to wa lagbegbe Oke Ola ti ija naa si di nla debi wi pe wọn yinbọn mọ Kazeem lori.

Lẹsẹkẹsẹ naa ni Kazeem ku nibi ti wọn ti yinbọn mọ ọn.

Ọpọ eeyan lo farapa yannayanna nibi ikọlu ọhun nitori wọn lo oriṣiiriṣii ohun ija oloro,'' o-ṣoju-mi-koro lo sọ bẹẹ.

Ara adugbo naa sọ fawọn akọroyin pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun lo pada pẹtu sija naa.

Ẹni ọhun ni ọrọ di bo o lọ ya yago fun mi bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe bẹrẹ ija lẹyin egungun naa.

Ara adugbo naa sọ pe awọn ọmọ okunkun ọhun fẹsẹ fẹẹ nigba tawọn ọlọpaa de.