Ìdí tí àkọọ́lẹ̀ 'writing' àwọn dókítà ò fi kí n dùn ún wò tí kìí sí yé èèyàn

Àwòrán dókítà tó ń kọ̀wé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera ni èèyàn kìí sábà rí kà débi pé èèyàn le ma fẹ̀ ẹ́ rí lẹ́tà kan pè nínú nǹkan tí wọ́n bá kọ sílẹ̀ pàápàá àwọn dókítà.

Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ohu tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà nìkan, kódà, àwọn ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè Brazil ti ṣòfin pé àwọn dókítà gbọdọ̀ máa kọ àwọn nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ kọ sórí kọ̀mpútà tàbí kí wọ́n kọ ọ́ kó hàn dáadáa.

Ìbéèrè ni pé kí ló ń ṣe atọ́nà bí èèyàn ṣe ń kọ nǹkan sílẹ̀? Àti pé kí ló dé táwọn kan fi máa ń ní àkọ́ọ́lẹ̀ tó dára tí tàwọn míì yóò sì dàbí ohun tí èèyàn kò lè kà rárá.

Onímọ̀ nípa ìdàgbàsókè èèyàn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Monika Saini ní India National Institute of Health and Family Welfare sọ pé kíkọ nǹkan sílẹ̀ ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ojú àti ẹ̀yà ara tó níṣe pẹ̀lú gbígbe ara.

"Mo lè sọ pé kíkọ nǹkan wà lára ohun tó le púpọ̀ lára èèyàn," ó sọ fún BBC World Service CrowdScience.

Ẹni tó ń kọ̀wé pẹ̀lú gègé àti ìwé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kókó ohun tó jẹ Saini lógún nídìí iṣẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni láti mọ̀ bí oníkálukú ṣe yàtọ̀ síra nípa bí a ṣe ń kọ nǹkan sílẹ̀.

"Kíkọ nǹkan dá lórí ohun èlò rẹ̀ àti ọwọ́ wa. Tí a bá sì ronú ọwọ́ wa, à ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gba pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, tí egungun mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n wà lára rẹ̀. Àwọn ẹran tó ń ṣe àkóso rẹ̀ lé ní ogójì," ó ṣàlàyé.

Èyí túmọ̀ sí pé bí èèyàn ṣe ń kọ nǹkan sílẹ̀ wà lórí ìṣẹ̀daá rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó jogún látara àwọn òbí rẹ̀.

Ní kúkurú, bí èèyàn ṣe ga sí, bí ọwọ́ ṣe dúró déédéé sí àtàwọn nǹkan míì máa ń ní ipa lórí àwọn nǹkan tí èèyàn bá ń kọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni àṣà bí a ṣe ń kọ́ ọmọ lórí bí wọ́n máa ń mú gègé dání, táwọn àgbà fi máa ń kọ ọmọdé nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ iṣẹ́ jẹ́ ohun tí kò ṣe é fojú fò nítorí bí wọ́n ṣe ń di gègé mú ni wọ́n máa fi kọ́ ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ iṣẹ́.

Bákan náà ni ipa àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́gbẹ́ ọmọdé náà máa ń jẹ́ ohun tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ọ̀nà tí èèyàn ń gbà kọ iṣẹ́.

Bí ọdún bá ṣe ń gorí ọdún ni ọ̀nà tí èèyàn ń gbà láti kọ iṣẹ́ máa ń yípadà. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí kọṣẹ́ ní ojoojúmọ́.

Àìní ohun kan tí èèyàn fẹ́ràn láti máa ṣe àti ìgbéayé ojoojúmọ́ kìí jẹ́ kí èèyàn kọbi ara sí bí èèyàn ṣe ń kọ àwọn ìró àti ọ̀rọ̀ sílẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà la ò lè kọ iyán ipa tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ń ní lórí bí èèyàn ṣe ń kọ iṣẹ́ nítorí títẹ nǹkan ló pọ̀ jù bí a ṣe ń kọ nǹkan lọ.

Bí àwọn aṣaajú ṣe ń kọ́ èèyàn lórí dídi gègé mú máa ń ní ipa lórí ohun tí èèyàn kọ́kọ́ ń kọ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bí àwọn aṣaajú ṣe ń kọ́ èèyàn lórí dídi gègé mú máa ń ní ipa lórí ohun tí èèyàn kọ́kọ́ ń kọ sílẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀, Saini fẹ́ nímọ̀ nípa ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ nípa bí àwọn ṣe ń kọ iṣẹ́ sílẹ̀.

Láti ṣe èyí, ó kọ àkọsílẹ̀ lórí àyípadà ojú ọjọ́, tó sì ní káwọn èèyàn kan ṣe àdàkọ rẹ̀ nípa lílo ọ̀nà kíkọ iṣẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n mọ̀ ọ́n lò jùlọ.

Lẹ́yìn tó gba ìw;e lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà, ó ṣe àyẹ̀wò àwọn lẹ́tà, bí lẹ́tà kọ̀ọ̀kan ṣe rí, àlàfo tó wà láàárín lẹ́tà kọ̀ọ̀kan àti báwọn èèyàn náà ṣe lè tọpasẹ̀ ilà gbọọrọ sí.

Tí òbí bá kọ́ ọmọ ní bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó ṣeéṣe láti rí àwọn ìjọra nínú iṣẹ́ tí àwọn méjéèjì bá kọ.

Àmọ́ iye ìgbà tí ọmọ bá ń lò nílé ẹ̀kọ́ àti irúfẹ́ ìlànà tí olùkọ́ bá máa ń lò máa ń ní ipa lórí bí ọmọ ṣe máa ń kọ̀wé.

Ọpọlọ lásìkò ìwé kíkọ

Onímọ̀ nípa Neuroscience, Marieke Longcamp ní ilé ẹ̀kọ́ University of Aix-Marseille ní France ń ṣe ìwádìí lórí bí èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní nǹkan kọ.

Láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó lo àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ tó le ṣàfihàn ọpọlọ bí èèyàn bá ṣe ń ṣiṣẹ́ kan.

Níbi ìwádìí náà kan, wọ́n fún àwọn èèyàn ní ohun ìkọ̀wé tó le gba bí ara èèyàn ṣe ń yí bí wọ́n ṣe ń kọ ìwé náà.

Longcamp jábọ̀ pé ó ṣeéṣe láti rí bí àwọn ẹ̀yà ọpọlọ ṣe ń dìde, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ papọ̀ láti mú kú ìwé kíkọ wáyé.

Ó sọ fún BBC CrowdScience pé gbogbo àwọn ẹ̀yà ọpọlọ bíi premotor cortex, primary motor cortex àti parietal cortex ni wọ́n kópa níbi ààtò ọwọ́ lílo láti kọ ìwé.

Ó ní àwọn ẹ̀yà ọpọlọ bíi frontal gyrus tí wọ́n dá lórí abala èdè àti fusiform gyrus tó ń ṣe àkóso èdè kíkọ sílẹ̀ ń ní ipa lórí kíkọ nǹkan sílẹ̀.

Ó fi kun pé àwọn ẹ̀yà míì ni tó ní í ṣw pẹ̀lú kíkọ ìwé sílẹ̀ ni cerebellum.

Onímọ̀ náà sọ pé kíkọ nǹkan sílẹ̀ gba lílo ẹ̀yà ìrínran àti ara yíyí.

Àwọn onímọ̀ sọ pé kíkọ nǹkan sílẹ̀ jẹ́ lára àwọn ohun tó le tí èèyàn ń ṣe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn onímọ̀ sọ pé kíkọ nǹkan sílẹ̀ jẹ́ lára àwọn ohun tó le tí èèyàn ń ṣe

Bí kíkọ nǹkan ṣe ní ipa lórí ìkẹ́kọ̀ọ́

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fún iṣẹ́ yìí, ó yẹ láti wo bí ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe ń nípa lórí bí àwọn nǹkan ṣe ń ye èèyàn sí.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, kíkọ nǹkan sílẹ̀ ni èèyàn fi máa ń ṣe àkọ́sórí, kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tàbí ohun tí èèyàn kò fẹ́ gbàgbé.

Àmọ́ èyí ti ń yípadà báyìí pẹ̀lú ìdásílẹ̀ àwọn ẹ̀rọ kọ̀mpútà, fóònù àtàwọn míì.

Lode òní, orí fóònù àti kọ̀mpùtá láwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ń kẹ́kọ̀ọ́ dípò lílo gègé àti pépà bíi ti ìgbà kan.

Ṣé àyípadà yìí nípa lórí ìkẹ́kọ̀ọ́?

Onímọ̀ nípa ọpọlọ, Karin Harman James láti Indiana University ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.

Ó ń ṣe ìwádìí lórí bí àwọn ọwọ́ wa, àti bí a ṣe ń di nǹkan mú ń ní ipa lórí ìdàgbàsókè ọpọlọ àti bí èèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́.

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ náà ṣe sọ, bí ọpọlọ ṣe máa ń ṣiṣẹ́ nígbà tí èèyàn bá ń wo lẹ́tà àti tí èèyàn bá ń kọ ọ́ sílẹ̀ yàtọ̀ síra gidi.

Nínú ìwádìí kan, James gba ọmọ ọdún mẹ́rin kan tí kò tíì mọ ohunkóhun kọ. ní ilé àyẹ̀wò, wọ́n ń kọ́ ọmọ náà ni ohun mẹ́ta, bí ó ṣe le sọ ilà di ìró, bí ó ṣe le kọ ìró lórí kọ̀mpútà àti bí ó ṣe le kọ ọ́ sínú ìwé.

Ó ní àwọn wòye pé ọpọlọ àwọn ọmọdé tó ń fi ọwọ́ kọ ìwé ń ṣiṣẹ́ yàtọ̀ sí ti àwọn tó ya ìró àtàwọn tó ń kọ lórí kọ̀mpútà.

Àmọ́ àjọṣepọ̀ láàárín ìkẹ́kọ̀ọ́ àti kíkọ iṣẹ́ sílẹ̀ kò pin síbẹ̀.

Children wey learn to write - instead of to type am - show say dem dey activate more areas of di brain.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Children wey learn to write - instead of to type am - show say dem dey activate more areas of di brain.

James tún ṣe àyẹ̀wò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga. Iṣẹ́ wọn ni láti kẹ́kọ̀ọ́ lórí ètò ẹ̀kọ́ tí wọn kò kọ́ rí tí wọ́n sì máa dáhùn ìbéèrè lórí wọn ní ọjọ́ kejì.

Ó ní àwọn ṣe àgbéyẹ̀wò èsì àwọn tó fi ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ ohun tí wọ́n kọ́ sílẹ̀ àtàwọn tí wọ́n lo gègé àti ìwé.

Ó wòye pé àṣà lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀mpútà láti máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló gbilẹ̀ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Amẹ́ríkà tó sì jẹ́ pé orí àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí náà láwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń kọ iṣẹ́ sí pẹ̀lú àwọn gègé ìgbàlódé.

Èyí ló gbé wa padà sí ìbéèrè tí iẹ́ yìí dá lé lórí pé ṣé ó ṣeéṣe láti mú àyípadà bá bí èèyàn ṣe ń kọ̀wé, kó le ṣe é kà fún ẹlòmíràn?

Ìwádìí kan fi hàn pé kíkọ nǹkan sílẹ̀ ní ipa ju kíkọ sórí kọ̀mpútà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìwádìí kan fi hàn pé kíkọ nǹkan sílẹ̀ ní ipa ju kíkọ sórí kọ̀mpútà

Ṣé èèyàn le mú àyípadà bá bí ó ṣe ń kọ nǹkan sílẹ̀?

Ọ̀kan lára àwọn tó kópa níbi ètò CrowdScience, Cherrell Avery, olùkọ́ nípa ìwé kíkọ ní London, UK ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ tó wúlò láti mú àyípadà bí èèyàn ṣe ń kọ̀wé.

Ìmọ̀ràn tó kọ́kọ́ gbà ni kí èèyàn máa kọ̀wé pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. Ó ní tí èèyàn bá ń kọṣẹ́ kíákíá, èèyàn ò ní lè ṣàyẹ̀wò bó ṣe ń kọ ìró àti ọ̀rọ̀.

Ó fi kun pé èèyàn nílò láti mọ ìlànà ẹni, tó fi mọ́ ọ̀nà dídi gègé mú, irú ìwé tí èèyàn ń lò àtàwọn nǹkan míì.

Lérò rẹ̀, ó ṣeéṣe láti mú ìgbèrú bá bí èèyàn ṣe ń kọ̀wé tí èèyàn bá ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

Ó ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọjọ́ kan kò tó láti mú àyípadà bẹ́ẹ̀ wáyé àmọ́ tí èèyàn bá ń tẹ̀síwájú, ó ṣeéṣe kí àyípadà wáyé lórí kíkọ nǹkan.

Fún iṣẹ́ wa, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n lo ìmọ ẹ̀rọ láti fi kọ̀wé ní èsì tó dára níbi ìdánwò wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣe sọ.

"A lè ṣàlàyé èyí pẹ̀lú ẹ̀rí pé, yàtọ̀ sí kọ̀mpútà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lò, wọ́n ní àǹfàní láti kọ nǹkan sílẹ̀ fúnra wọn.

"Ṣùgbọ́n kíkọ iṣẹ́ pẹ̀lú ìwé àti pépà náà mú èsì rere jáde. Àwọn tó lo ìlànà yìí ní èsì tó dára ju ti àwọn tó lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ," Karin Harman James ṣàlàyé.

Ní kúkurú, tí o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa nǹkan, ọ̀nà tó dára jù láti kọ́ ọ ní nípa kíkọ nǹkan náà sílẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ yálà sínú ìwé tàbí sórí kọ̀mpútà.