Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n yẹgi fún Ogundoro tó dáná sun ìyàwó àti àbúrò ìyàwó rẹ̀

AworanChinyere ati Benjamin

Oríṣun àwòrán, Other

    • Author, Gift Andrew
    • Role, Reporter, BBC News Pidgin
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile-ẹjọ kan to n jokoo niluu Eko ti ni ki wọn yẹgi fun ọkunrin kan ti ọrukọ rẹ n jẹ Benjamin Ogudoro nitori pe o dana sun iyawo rẹ ati aburo iyawo rẹ ọkunrin.

Ile-ẹjọ ni, Ogudoro jẹbi ẹsun naa to si jẹ pe iku ni ere ẹsẹ rẹ.

Ogudoro gbe igbesẹ yii lasiko ti awọn oloogbe mejeeji n sun lọwọ ni ọganjọ oru.

Ọdun 2022 ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti ede-aiyede kan bẹ silẹ laarin tọkọtaya naa.

Iyawo, Chinyere Ogudoro kagbako iku ojiji ọhun lẹyin to de pada si Naijiria lati orilẹ-ede Scotland.

'Ogudoro ko banujẹ lori idajọ'

Aworan Benjamin Ogudoro

Lasiko igbẹjọ naa l'ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, Onidajọ Sonaike ni, ẹri to wa ni ile-ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe afurasi mọọmọ ṣekupa awọn oloogbe, to si gbọdọ jẹ iya to yẹ labẹ ofin.

"O farabalẹ seto iwa ọdaran yii ni. Iwa ika to tobi ree" - eyi ni ọrọ adajọ.

Bakan naa ni ile-ẹjọ tun ni o jẹbi ẹsun mẹrin ti wọn ka si lẹsẹ, eyi to nii ṣe pẹlu iṣekupani.

"Fun iṣekupani, ile-ẹjọ palasẹ pe ki wọn yẹgi fun ẹ titi wa fi gbe ẹmi mi.

"Fun ẹsun didana sun eeyan, ile-ẹjọ tun sọ ẹ si ẹwọn egbere."

Gẹgẹ bii ile-ẹjọ se sọ, ọdaran naa ko se bi pe ọrọ naa dun-n rara lasiko igbẹjọ.

"Iwa olujẹjọ lo jẹ eyi to buru ju fun eeyan to ṣekupa eeyan bi tirẹ", adajọ sọ

Agbẹjọro fun awọn olupẹjọ ni, ija ti ma n waye ninu igbeyawo naa, to si jẹ ija to waye naa lo mu ki olujẹjọ dana sun awọn oloogbe naa, ti wọn si jẹ Ọlọrun ni pe ni kiakia.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, to si farahan ni ile-ẹjọ, sọ pe ina naa jo iyawo, de ibi pe ẹsẹ kan yọ kuro ni ara rẹ.

"Aburo iyawo ti oun jona, ko tete ku ṣugbọn nigba to ya oun naa jẹ ipe Ọlọrun," Adajọ ṣalaye.

Ki gan-an lo sẹlẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Edna Durueke, ẹni ọdun mẹrinlelọgọta, ẹgbọn oloogbe sọ fun BBC lọdun 2022 pe iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta ọdun, 2022 nigba ti oloogbe pada de lati orilẹ-ede Scotland.

O ni ile wọn to wa ni Abule Ado nipinlẹ eko, lo de si.

"Oorun ti yoo kọkọ sun niyẹn ni ile naa, ko laju si ọjọ keji."

Durueke ni awọn tọkọtaya mejeeji ti yanju ija wọn ko to di pe iyawo rin irinajo ṣugbọn ko mọ pe ọkọ ṣi n binu.

O ni awọn pada mọ pe ohun to n bi ọkọ ninu ni pe orukọ iyawo nikan ni iyawo fi ra ile ti wọn n gbe.

"Aburo mi jẹ oṣiṣẹ banki to n se daada ko to di pe o rin irinajo. Ko to rin irinajo, o n gbe pẹlu ọkọ rẹ ni agbegbe Dopemu.

"Nigba to ya, o ri owo lati ra ilẹ, to si bẹrẹ si ni kọ ile. Nigba to tun ya o ri fisa gba lọ kawe ni oke okun. Fisa yii fun ni anfaani lati ko awọn mọlẹbi rẹ, fun idi eyi o mu awọn ọmọ rẹ mẹrin ati ọkọ lọ.

"Ko si ẹni to mọ idi ti ọkọ fi ni ohun fẹ duro si Naijiria. Nigba to ya, iyawo gbọ pe ọkọ fẹ ta ile wọn ṣugbọn ko le ta nitori orukọ iyawo nikan lo wa ninu iwe."