Babatunde Fashola: Ọdún 21 rèé tí mo ti ń gba ipò ìjọba, lẹ́yìn èyí, ọ̀pẹ́ ló kù

Àkọlé fídíò, Babatunde Fashola: Ọdún 21 rèé tí mo ti ń gba ipò ìjọba, lẹ́yìn èyí, ọ̀pẹ́ ló kù

Minisita feto irinna lorilẹede Naijiria, Babatunde Raji Fashola, ti salaye bi oriire se gbe alawo rere pade rẹ pẹlu bo se pade oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Fashola, lasiko to n takurọsọ pẹlu BBC Yoruba, eyi ti akọroyin BBC, Uche Akolisa se fun, o salaye pe oun kọkọ pade Bola Tinubu ni ode ariya ti wọn n se niwaju ile Baba oun ni Surulere lasiko ti oun lọ woran loju agbo naa.

Amọ o fikun pe ori tun gbe oun pade Tinubu fun igba keji lati ipasẹ ọmọ ẹgbọn rẹ, Wale Tinubu, lati igba naa si ni oun ti n ri aanu gba niwaju agba oloselu naa.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko naa tun mẹnuba ọpọ awọn aseyọri ti ko ni afiwe ti Tinubu gbe se nipinlẹ Eko lasiko to fi wa nipo gomina.

Fashola wa n kede pe ko si awn eeyan to n ba Tinubu figa gbaga lati du ipo aarẹ to le tọka si ọpọ aseyọri ti wọn se nipinlẹ koowa wọn, bii Bola Tinubu.

Minisita fero irinna naa tun sọrọ nipa ohun to fa irora tawọn eeyan n la kọja lopopona marosẹ Eko si Ibadan ati bi adun yoo se kẹyin ewuro fun wn lori ọrọ yii.

Bakan naa lo tun mẹnuba ọpọ aseyọri aarẹ Muhammadu Buhari ni ẹka igbokegbodo ọkọ pẹlu ohun ti wọn yoo maa ranati isejọba naa fun lẹyin to ba kogba wọle tan.

Fashola tun wa salaye iru isejọba ti Bola Tinubu yoo se to ba di aarẹ Naijiria eyi to ni yoo jẹ isejọba awọn ọdọ gẹgẹ bo ti se nipinlẹ Eko.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko naa wa kede pe ọpẹ lo ku ninu ọrọ oun bayii lẹyin ti isejọba Buhari ba kogba wọle tan nitori ọdun kọkanlelogun ree ti oun ti n gba ipo ijọba .