Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fọwọ́ sí ìgbésẹ̀ Ààrẹ Buhari láti ya $16b àti €1bn

Ile igbimọ aṣofin Naijiria ti buwọlu ẹbẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lati ya owo ti iye rẹ to $16,230,077,718, ati €1,020,000,000.

Owo miran ti ile aṣofin naa tun buwọlu ni miliọnu márùndínláàdóje dọla.

Gbese naa ni ajọ banki agbaye, ile ifowopamọ Exim ni China, awọn ile ifowopamọ kan, to fi mọ banki idagbasoke ilẹ Afrika, AfDB yoo ṣagbatẹru rẹ.

Wọn fọwọ si yiya owo yii lẹyin ti ile naa tẹwọgba esi iwadii igbimọ to n ri si iye gbese ti Naijiria jẹ, eyii ti alaga igbimọ naa, sẹnetọ Clifford Ordia gbe wa siwaju ile aṣofin ọhun.

Nigba to n jabọ iwadii wọn, Ordia sọ pe awọn iṣẹ akanṣẹ ti wọn ya owo rẹ lọdun 2018 si 2020 ti n lọ lọwọ.

Ọ ni awọn iṣẹ akanṣe ti wọn yoo fi owo naa ṣe yoo mu aye dẹrun fun awọn araalu, ati pe awọn owo ori ti wọn yoo gba lori awọn iṣẹ akanṣẹ naa yoo tun pa owo wọle sapo ijọba apapọ.

Inu oṣu Kẹsan an ọdu 2020 ni Aarẹ Muhammadu Buhari gbe igbesẹ lati ya awọn owo naa ni afikun awọn owo kan to ti kọkọ ya laarin ọdun 2018 si 2020.

Ṣaaju ni ile aṣofin ọhun ti kọkọ buwọlu owo ti iye rẹ to $8.3 miliọnu ati €490 miliọnu gẹgẹ bii owo ti wọn fẹ ya.

Nigba to n sọrọ lori eredi ti yiya owo naa ṣe ṣe pataki, Buhari sọ pe awọn owo naa yoo ran ijọba lọwọ lati mu ki eto ọrọ aje Naijiria gberu si, ati lati pese iṣẹ yanturu fun awọn araalu.

Ẹwẹ, awọn ọmọ Naijiria kan ti n bu ẹnu atẹ lu ijọba Buhari fun bo ṣe n ya owo lọwọ awọn ijọba ilẹ okeere, paapaa China lawọn ọdun diẹ sẹyin.