You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wasiu Ayinde's new wife: Ṣé lóòtọ́ ni K1 fẹ́ ṣe ìgbéyàwó nínú oṣù Kọkànlá?
Yoruba bọ, wọn ni aito eyin ka, la n dọwọ bo o.
Bẹẹ gan-an ni ọrọ ri fun gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde, ti ọpọ mọ si KWAM 1.
Lati bi oṣu melo kan ni iroyin ti n lọ kaakiri lori ayelujara pe K1 tun ti fẹ iyawo miran.
Ọdun 2018 ni ariwo igbeyawo rẹ kan jade sinu iroyin, lasiko to fẹ gbajumọ oniṣowo aṣọ nilu Eko, Fathia Opeyemi ti awọn eeyan tun mọ si Titi Marshal bayii.
Ọmọ mẹta lo wa laarin wọn. Wọn si ti bi awọn ọmọ yii ko to o di pe wọn ṣe igbeyawo wọn.
Koda, igbeyawo oloruka ni wọn ṣe.
Titi si kọ ni obinrin akọkọ to bimọ fun Wasiu Ayinde, bẹẹ ni a ko si le sọ iye obirin to ti ṣe igbeyawo pẹlu wọn.
Nkan ti a mọ ni pe kii ṣe obinrin kan ṣoṣo lo bimọ fun gbajugbaja olorin Fuji naa.
- N kò jẹ Mayegun láti bùgá, mo wá tún ilẹ̀ Yorùbá ṣe ni - Wasiu Ayinde
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjà ti parí láàrin ìdílé Ayinde Barrister àti Kwam 1?
- "Ọmọ kan ṣoṣo tó bí fún mi ni wọ́n gún lọ́dún mẹ̀ta sẹ̀yìn kí wọ́n tó gún òun náà pa báyìí"
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
Gẹgẹ bi a ṣe n sọ lọ, laipẹ yii ni iroyin jade si ori ayelujara pe K1 tun ti fẹ obinrin miran.
Orukọ obinrin naa ni Emmanuella Ropo.
Irọ ni, ootọ ni, ko jẹ ribẹ, ni ọpọ n sọ ni asiko naa.
Koda lasiko ti iroyin yii jade, o ni awọn mejeeji ti ṣe igbeyawo ni kọọrọ.
Botilẹ jẹ pe K1 tabi Emmanuella ko jade lati sọrọ nipa iroyin yii, awọn apẹẹrẹ kan jade pe lootọ ni wsn n fẹ ara wọn.
Emmanuella ni "Ọkan mi n sun ifẹ fun ọ, oun si ni epo to n wa ọkọ aye mi.
"Mo ti ni awọn ero kan tẹlẹ nipa bo sẹ le ri, ṣugbọn o fọ awọn ero naa, o si fi igbeaye to kọja oye mi rọpo rẹ.
Ko si iru skunrin bi tiẹ mọ. Tiẹ ni ọkan ati ẹmi mi."
Ninu ọrọ naa to kọ si ori Instagram rẹ lọjọ mẹta sẹyin, lo fi aworan Wasiu si.
Botilẹ jẹ pe ẹyin ni ẹni to wa ninu aworan naa kọ sita, Emmanuella fi orukọ K1 lori ayeluajara Instagram si i.
Yatọ si eyi, kii ṣe ẹẹkan tabi ẹẹmeji ni Wasiu Ayinde fun'ra rẹ ti fi ifẹ han si Emmanuella lori ayelujara.
Laipẹ yii, ninu oṣu Kẹwaa, Wasiu fi fidio kan si ori ayelujara Instagram rẹ, pẹlu aworan Emmanuella.
Ninu fidio naa lo ti n kọrin kii pe "aya mi Ajikẹ, Ayinde Ade ọkọ Ajike, ọmọ to pọn roro. Emmanuẹlla aya mi Ajikẹ."
Bakan naa lo kọ ọrọ si abẹ fidio naa pe "o n dara si ni gbogbo iṣẹju, Nuella Ajike Mii".
Ni ọsẹ diẹ sẹyin bakan naa, ninu oṣu Kẹsan-an, igba meji ni Wasiu fi aworan Emmanuella si Instagram rẹ pẹlu oriki .
Taa ni Emmanuella ?
Orukọ rẹ ni Emmanuella Moronrọpo. Ọmọ ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni.
Oun ni Otun Iyalode ti Igbein nilu Abeokuta. Baba rẹ, oloogbe Oloye Stephen Gboyega Odebiyi naa jẹ oye ni ill Ẹgba ṣaaju iku rẹ.
Oniṣowo ni pẹlu. O n ta aṣọ, bata ati awọn nkan isẹre ọmọde ati fun ayẹyẹ ni agbegbe Ojodu, nipinlẹ Eko.
Iroyin sọ pe ọmọ mẹrin ni Rọpo ti bi tẹlẹ.
Lọwọlọwọ, iroyin to n lọ ni pe ninu oṣu Kọkanla yii gan-an ni ayẹyẹ igbeyawo wọn yoo waye.