Sleeping tips: Tí ó kó bá sùn ni àárín aago yìí... Ò ń ṣe àkóbá fún ìlera ọkàn rẹ

Àwọn ónímọ̀ sọpé tí ènìyàn bá sùn láàrin aago Mẹ́wàá sì aago mọ́kànlá lọ dára fún ọkàn. Wọ́n fẹnukò lórí àbájáde yìí lẹ́yìn tí wọ́n lo ènìyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìdinlaadọ́run tí wọ́n fi ara wọn sílẹ̀.

Àwọn ìgbìmọ̀ to wà lẹ́yìn ìwádìí Bionbank tí wọ́n ṣe ni UK yìí nìgbàgbọ́ pé bí ènìyàn bá sùn gẹ́gẹ́ bí aago àgọ́ ara ènìyàn máa ṣèrànwọ́ láti mọ ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín bí ó ṣe lè mú àdínkù bá ààrùn ọkàn àti súròkí.

Wákàtí mẹ́rìnlélógún ni àsìkò tí ara wa ń kà pàápàá jù lọ ara tó bá pe. Kíni àwọn ónímọ̀ ṣàwárí fún àsìkò tó yẹ láti sùn.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n ṣe nínú ìwé jọ́nà European Heart, àwọn olùwádìí naa mú kí àwọn tó fara wọn sílẹ̀ fún lílò nibi ìwádìí náà lo ẹ̀rọ kan tí yóò máa ka àsìkò tí wọ́n sùn tàbí tí wọ́n jí.

Wọ́n sì ṣe àmójútó nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọkàn wọn àti bí gbogbo ìlera ara wọn yóò ṣe wá fún ọdún mẹ́fà.

Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta péré nínú àwọn tó jẹ́ àgbà nínú wọn ló ní ààrùn ọkàn Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ààrùn náà ni àwọn tó sùn lẹ́yìn aago mẹ́wàá sì mọ́kànlá tó yẹ kí wọ́n sún.

Síbẹ̀ èyí sì farahàn pé ìṣòro náà sì wà nibẹ lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe àtúnṣe àsìkò oorun wọn.

Àwọn olùwádìí náà wọ́nà láti wá ojútùú sì àwọn nǹkan míràn tí ó lè ṣe okùnfà ààrùn ọkàn bí ọjọ́ orí, ìwọ̀n, ọ̀rá tó pọ̀ lára, ṣùgbọ́n wọ́n ni ìwádìí àwọn kò lè sọ ní pàtó èyí tó jẹ́ níbẹ̀.

Ẹni to ṣe àgbékalẹ̀ ìwádìí náà, Dr David Plans láti Fáṣítì Exeter sọ pé" ìdí tí a kò fi lè fi ẹnu kò lórí nǹkan pàtó tó ṣe okùnfà èyí nínú ìwádìí wá ní pé, àbájáde ìwádìí jẹ́ kí ó ye wa pé tí ènìyàn bá tètè sùn tàbí kí ó pẹ́ sùn, ó lè jẹ́ ìdíwọ́ fún aago ara, pẹ̀lú ààrùn to níṣẹ́ pẹ̀lú ọkàn.

"Àsìkò tí ó léwu jùlọ láti sùn ni lẹ́yìn aago méjìlá òru, ìdí ni pé ó kó ni jẹ́ kí ara ní anfaani lati ri imọ̀lẹ̀ àárọ̀ tí ó máa ń ṣe atunto aago ara lojoojumo.

"Regina Giblin to jẹ́ nọ́ọ̀sì àgbà lórí ìtọ́jú ìṣòro ọkàn nílé ìwòsàn British Heart Foundation, sọ pé: " ìwádìí tó gbòòrò yìí ń sọ ní pe, ènìyàn gbọ́dọ̀ máa sùn láàrin aago mẹ́wàá alẹ́ sí aago mọ́kànlá láti mú kí ọkàn wọ́n jí pépé fún ìgbà pípẹ́Ẹ̀wẹ̀, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé ìwádìí náà kan lè sọ ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín méjèèjì ṣùgbọ́n kí ó máa lé fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni pàtó.

Ìwádìí nílò lórí àsìkò tí ènìyàn ń sùn àti iye wákàtí tó gbọdọ̀ jẹ́. Sísun oorun tó tó ṣe pàtàkì fún àgọ́ ara wa, àti fún ọkàn láti jẹ́ kí ìlera kẹ́ṣẹ járí pàápàá julọ àwọn àgbà níláti sùn fún wákàtí méje láàrin òru gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ.

" Ṣùgbọ́n oòrùn nìkan kọ́ ni ó lè fa wàhálà sí àgọ́ ara. Ó ṣe pàtàkì láti mójú tó bí ó ṣe ń gbé ìgbé ayé, àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ nípa ìfúnpá rẹ àti ọ̀rá inú ara, mójú tó bí o ṣe sanra sí, máa ṣe ìdárayá lóòrèkóòrè, mú àdínkù bá iyọ̀ jíjẹ àti ọtí mímu. Jẹ oúnjẹ tí gbogbo èròjà rẹ pé fún àgọ́ ara tó ní àlàáfíà."