Lateef Adedimeji weds Bimpe Oyebade now: Ọkọ àti ìyàwó fi àwòrán àwọn ìkíni kú oríire tí wọ́n gbà síta

Ọ̀rọ̀ náà jọ pe o ti n di ohun bọ bayii ti pọpọṣinṣin si ti n lọ ni mẹlọ mẹlọ nipa igbeyawo awọn gbajugbaja oṣere Yoruba meji, Lateef Adedimeji ati Bimpe Oyebade.

Awọn ololufẹ meji yii ko lee fi para mọ rara. Ka tilẹ woo latori Adebimpe Ọmọba to n rẹrin musẹ musẹ ninu fidio kan to fi sita ninu eyi ti ọrẹ rẹ ti ni ko fi oruka rẹ han.

Ọpọ awọn ololufẹ awọn mejeeji lo ti n foju sọna igbeyawo wọn ọhun lati igba ti wọn ti kọkọ n dibọn bii pe ọkọ ati aya ni wọn amọ ti wọn kọ lati jẹwọ.

Koda o ni asiko kan ti Lateef ṣalaye ninu ifọrọ̀wanilẹnuwo kan nipa idi ti ko fi tete ṣe igbeyawo rẹ.

Ọrọ kan ti a ko tun le fidi rẹ mulẹ ni pe awọn to maa n gbe iroyin jade lori ayelujara bii ofofo tabi ayọlẹ ṣe ti ọpọ mọ si "gossip blogger" ti gbe iroyin kan sita ri pe iyawo oju na yii n reti ọmọ pe o wa ninu oyun.

Ẹwẹ nigba ti BBC Yoruba kan si Abdulateef Adedimeji funrarẹ, o jẹ ko di mimọ pe ko si awo kan ninu awo ẹwa pe oun ati ololufẹ oun ti fẹ sọ igbeyawo yii di ohun bayii.

O ni ko jẹ tuntun tabi nkan aṣiri mọ toripe awọn funra awọn ti gbe e sita fun awọn ti awọn fẹ ki wọn mọ.

Nitorinaaa lo mu ki ati Lateef ati Adebimpe fi awn aworan arawọn ti awọn ọrẹ, ara ati ojulumọ n fi si ori ayelujara lati ki wọn ku oriire.

Nigba ti ikọ BBC Yoruba bere pe ṣe loot ni deeti ọjọ ikejilelogun to wa lori kaadi ti awọn oniroyin kan gbe sori ayelujara gẹgẹ bi ọjọ ti igbeyawo wọn yoo waye, Lateef ni "ki gbogbo ololufẹ wa ni suuru, bi asiko ba ti to ipe wa yoo de ọdọ wọn".

A tun bere pe ṣe awọn ni wọn fun ni naa laṣẹ lati gbe ote ara rẹ lee pe oun lo nii, Lateef ni "Naijiria ti ko lofin naa lo faa ti awọn eeyan ko ṣe bọwọ fun ohukohun ti ẹlomii fẹ fi bo".