Oluwo God festival: Ọba Ogboni ìwásẹ̀ ní wọn ò ṣètùtù tó yẹ fún Oluwo kó tó jọba lójẹ́ kó máa ṣ'ìwà hù

Ọba Ogboni iwasẹ, Adeyinka Adisa Sangolade Arifanlajogun naa ti fesi si ọrọ ti Oluwo ilẹ Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi pe ko si ohun to n jẹ oriṣa mọ nilẹ Yoruba wi pe ọba lo jẹ gaba lori awọn oriṣa.

Ọba Igboni iwasẹ ni Oluwo ti yo tan, o wa n wa bẹkun bẹkun kiri lo jẹ ko maa sọ gbogbo ọrọ to n sọ kaakiri,

''Nigba mii, ti eeyan ba yo tan a maa wa bẹkun bẹkun kaakiri, nkan ti eeyan ko tọ si ti wọn gba gbe fun eeyan, o ṣeeṣe ki eeyan ṣii lo.

Tori pe ti ẹ ba woo, iwa Oluwo yatọ si iwa gbogbo ọba ilẹ Yoruba.

Eledumare lo ṣe ẹda awọn oriṣa, awọn ọba naa si wa ninu awọn ti ori ṣa da.

Oluwo fẹ ba ilu Iwo jẹ, awọn alalẹ ko si ni gba fun un, awọn onilẹ atawọn igba iwasẹ ko le gba fun.

Awa o ka Oluwo mọ awọn ọba ilẹ Yoruba nitori ẹ ko mọ iru nkan to ti mu ki o to maa sọrọ lawujọ.

Awọn ooṣa ti Oluwo n tabuku wọn ṣi n wo Oluwo lọwọ ni, to ba to asiko wọn o kan si i tori ọjọ tio ọmọde ba mulẹ lo ma n mọ ki i mọ ọjọ ti yoo da a.

Ba wo ni Oluwo ṣe maa sọ pe ko si nkankan to n jẹ oriṣa nilẹ Yoruba?

Wọn ni oogun ti eeyan ko ba fi owo ṣe, ẹyin aaro lo n gbe, ẹni ti ko ni iru ẹni, ko le mọ iyi ẹni.

Wọn kan lọ mu Oluwo wa jọba ni wọn o ṣe gbogbo etutu to yẹ ki wọn ṣe fun un ki o to jẹ ọba,''Oba Ogboni Iwasẹ lo sọ bẹẹ.

Oba Ogboni tun sọ pe iru kan naa pẹlu Oluwo ni gbogbo awọn to n fi oju ọlaju wo awọn ohun ti Oluwo n ṣe.

O ni o ṣe pataki ki wọn maa fi Ifa ṣe iwadii ẹnikẹni to ba fẹ jẹ ọba nilẹ Yoruba.

'Gómìnà Osun ẹ kìlọ̀ fún Oluwo lórí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ pé Ọba kìí ṣe ìkejì Orìṣà!' Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ tutọ́ s'ókè

Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba AbdulRasheed Akanbi ṣe ọdun Olodumare lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹsan an oṣu kọkanla ọdun 2021, aye gbọ ọrun mọ.

Amọ, ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ, Traditional Religion Worshippers Association (TRWASO), ti kepe gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola wi pe ko kilọ fun Oluwo lori ọrọ ẹnu rẹ ti wọn pe ni ọrọ alufansa.

Nibi ọdun Ọlọrun Ọba yii ni Oluwo ti sọ faraye pe oun kọ ni Ọba, Ọlọrun nikan ni Ọba, Ọlọrun nikan si ni gbogbo eeyan to wa nibi ayẹyẹ Ọdun Ọlọrun Ọba waa yin.

Oluwo ni ''ọba alade gbọdọ maa gboṣuba fun Eledua to jẹ Ọba awọn ọba.

O ṣeewọ ki ọba alade maa sin oriṣa kekeke, Ọlọrun ọba nikan lo yẹ ki gbogbo ọba maa wari fun.

Mi o le sikeji si oriṣa kankan nitori mi kii ṣe ẹru ooṣa.

Mo lagbara lori gbogbo oriṣa nitori emi ni mo n ṣoju Eledumare to n jẹ Kabiyesi.''

Ṣaaju nigba ti Oluwo kọkọ kede pe oun yoo ṣe ayẹyẹ yii, akọle to pee ni "Ọdun Olodumare" amọ nigba to ya, Oluwo yii pada si "Ọdun Ọlọrun Ọba" fun idi to jẹ wipe Kabiyesi nikan lo mọ.

Amọ, ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ TRWASO ti fun Oluwo ni ọjọ mọkanlelogun lati tọrọ aforijin lọwọ awọn.

Ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ sọ nibi ipade ti wọn ṣe nile Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon pe Oluwo gbọdọ dẹkun fifi ori awọn ẹlẹsin gba ara wọn.

Aarẹ ẹgbẹ TRWASO, Ọmọwe Oluseyi Atanda sọ pe ti Oluwo ko ba fẹ wọ ade awọn oriṣa mọ, o yẹ ko fi aafin naa silẹ.

Ọmọwe Atanda ni ti ijọba ipinlẹ Osun ati Oluwo ko ba dawọn lohun titi di ọgbọnjọ oṣu kọkanla, miliọnu kan awọn ẹlẹsin ibilẹ ni yoo ṣe ifẹhonuhan lọ si ilu Iwo pe ki ijọba rọ ọ loye.

O ni aimọye igba ni Oluwo ti ṣe oriṣiiriṣii nkan ti ko bojumu fun ọba alade lati maa ṣe.