Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrín ọmọ ìyá méjì ní Yobe, ni wọ́n bá gé ara wọn ní apá jábọ́.

Ìlú Alkali ní ìjọba ìbílẹ̀ Dapchi, nipinlẹ̀ yobe ni iṣẹ̀lẹ̀ naa ti wáyé.

Agbenusọ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ nàá, ASP Dungus Abdulkarim so fún BBC pe awon ọ̀dọ́kùnrin méjèèjì, Bukar audu àti Bukar Muhammad ẹni ọdún márùn-úndinlọgbọ́n ni wọ́n ṣá ara wọn niadá tí wọ́n sì gé apá ara wọn jábọ́.

Àwọn ọlọ́pàá mú apá wọn àwọn pẹ̀lú lọ sí ilé ìwòsàn pẹ̀lú ìrètí láti lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí nílé ìwòsàn.

Ó ní irú ìjà bẹẹ tí ṣẹlẹ̀ láàárin àwọn méjèèjì rí nígbà kan, tí wọ́n sì di èrò ilé ìwòsàn.

Ó sì ṣàlàyé pé, nítorí bí ìnira ṣe pọ̀ tó ọkan nínú wọn kò lè sọ̀rọ̀ rárá, ṣùgbọ́n ìkejì rẹ sọ̀rọ̀.

ASP ọlọ́pàá fìdí rẹ múlẹ̀ pé títí di àsìkò yìí kò sí ẹnì tó lè sọ pé nǹkan tó dìjà láàrin wọn rèé nítorí wọn wà nínú ìnira, ṣùgbọ́n ni kété tí wọn ba ti gba ìtọ́jú tán, ìwádìí yóò tẹ̀síwájú.

Ó ní orisirisi ìjà lọ ń lọ lọ́wọ́ yálà, nítorí nǹkan ọ̀sin, ọmọge, àwọn èso tàbí nítorí koríko.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ìdajì nínú àwọn ọdọ́ yìí ló ń lọ oògùn olóró.

Agbenusọ ọlọ́pàá náà fi kun pé kii se ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí irú ìjà báyìí yóò bẹ silẹ lágbègbè náà, kódà láìpẹ́ yìí ọmọkùnrin kan pá bàbá rẹ̀ nítorí ó fún ẹran ní koríko rẹ.

Ó ní ìwádìí fi hàn pé ọdọmọkunrin náà ń lo oògùn olóró, èyí tó mú kó là igi mọ bàbá rẹ̀.

Ó ní àwọn sí ń wá ona láti jẹ́ ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́nran wáyé láàárín àwọn ọdọ́ àti àwọn òbí wọn.