Gbadebọwale Abọdẹrin kú lásìkò isẹ́ abẹ ọkàn

Oríṣun àwòrán, @MobilePunch
Alága ìwé ìròyìn Punch, Gbadebọwale Abọdẹrin ti dágbére fáyé ní Ọjọ́rú lẹ́ni ọgọ́ta ọdún.
Ìwé ìròyìn Punch jábọ̀ pé, ó kú ní nkan bi agògò mẹ́fà kọjá ìṣẹ́jú màrun ùn òwúrọ̀ Ọjọ́rú, tí ṣe ọgbọ̀njọ́, oṣù Karùn ún, 2018.
Gbadebọwale Abọdẹrin jẹ́ ìpè Ọlọ́run lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ọkàn tí wọ́n ṣe fun un ní ilé ìwòsàn First Cardiology Consultants, Ikoyi, ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nígbà ayé rẹ̀, òun nà ni Alága ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé Punch.
Ó lọ sí ilé ìwé Government College, Ibadan, ó sì tún kẹ́kọ̀ ní orílẹ̀èdè Amẹrika, gẹ́gẹ́ bi awakọ̀ òfurufú.
Ìyàwó kan, Titilayọ, àti ọmọbìnrin méjì, Nicole àti Cherelle ló ń gbẹ̀yìn tẹ́yìnse fún Ológbèé Gbadebọwale Abọdẹrin.









