India: Ẹ wo ọmọ tuntun jòjòló tí wọ́n gbé sin láàyè nínú ìkòkò

Ọmọ jojolo ti wọn gbe sin laaye

Oríṣun àwòrán, ANOOP KUMAR MISHRA

Àkọlé àwòrán, Ọmọ jojolo ọhun ti n gba itọju nile iwosan

Ọmọ tuntun kan ti wọn gbe sin laaye ni ori ti ko yọ lẹyin ti wọn gbe e jade ninu iboji ti wọn sin in si.

Aṣoju ọlọpaa ni Uttar Pradesh, Abhinandan Singh sọ fun awọn oniroyin pe, ọmọ naa ni ẹnikan ri ni iboji naa ni igba to lọ sin oku ọmọ rẹ obinrin to gbemi mi lẹyin iṣeju diẹ ti wọn bii.

Ọmọbinrin naa ni wọn gbe sin ninu ikoko to to iwọn ẹsẹ bata mẹta ti wa ni ile iwosan bayii, to si ti n gba itọju lọwọ.

Ajọ ọlọpaa ilẹ India ti bẹrẹ iwadi lati mọ okodoro bi ọrọ naa ṣe ṣẹ.

Singh sọ fun awọn oniroyin pe, "A ti bẹrẹ iwadii lati foju gan an ni awọn obi ọmọ ọhun, nitori a gbagbọ pe wọn mọ nipa bi ọmọ naa ṣe di gbigbe sin laaye."

maapu

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, India ti aṣa wọn ko ka ọmọbinrin si pupọ

Ọga ọlọpaa ọhun ṣalaye pe, ara abule kan lo ṣeṣi ri ọmọ naa ni igba to n gbẹ iboji to fẹ sin ọmọ rẹ si.

Bawo ni wọn ṣe ri ìkókó yii ninu sàárè?

Oga ọlọpaa naa ṣlaye pe: "Bi wọn ṣe n gbẹ iboji ti awọn obi ọmo to ku fẹ sin ọmọ ti wọn si, ti wọn de iwọn ẹsẹ bata mẹta ni wọn kan ikoko kan.

Nigba ti wọn gbe ikoko naa jade ni wọn ba ọmọ jojolo ninu rẹ ti ẹ̀mí ko tii bọ́ lara rẹ"

Lẹyin eyi ni wọn fi ọrọ naa to ajọ ọlọpaa leti. Ki awọn agbofinro to gbe ọmọ naa lọ sile iwosan.

Orilẹ-ede India wa lara awọn orilẹ-ede ti ko ka obinrin si ju lagbaye, ni bi wọn ṣe ri nina owo lori obinrin gẹgẹ bi ifowoṣofo.

Ọpọ ni aṣa wọn pọn ọmọkunrin le ju ọmọbinrin lọ, ati pe ọpọ lo ti ṣẹ oyun awọn ọmọbinrin wọn danu nitori ọkunrin ni wọn n fẹ.

Àkọlé fídíò, Rape: Ayé obìnrin tí wọ́n fipábálòpọ̀ kò lè rí bákàn náà mọ́