World Cup qualifier: Senegal àti Egypt yóò wáàkò fún tíkẹ́ẹ̀tì ife ẹ̀yẹ àgbáyé Qatar 2022

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ati Egypt ni yoo koju ara awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ni Qatar lọdun 2022 yii.

Eyi tumọ si pe Mohamed Salah ati Sadio Mane ti wọn jọ jẹ ọmọ agbabọọlu Livrepool yoo koju ara wọn.

Ikọ Super Eagles Naijiria yoo koju Black Stars Ghana ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni Qatar lọdun 2022 yii.

Lonii ọjọ Abamẹta niluu Douala ni Cameroon wọn kede bi awọn ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ṣe lọ nilẹ Afirika.

Laarin ọjọ kọkanlelogun si ọjọ kọkandinlọgbọn ni ifẹsẹwọnsẹ mejeeji gbọdọ waye laarin Naijiria ati Ghana.

Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ mii, Mohamed Salah ati Sadio Mane yoo koju ara wọn nigba ti Egypt ati Senegal yoo maa waako.

Cameroon to n gbalejo idije AFCON lọwọ yoo maa na tan bi owo pẹlu Algeria.

Mali ati Tunisia yoo jọ maa ṣalaye fun ara wọn ẹni ti yoo lọ si idije ife ẹyẹ agbaye bi Qatar.

Ikọ agbabọọlu DR Congo ati Morocco yoo jọ waako bakan naa.