You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria vs Guinea Bissau: Super Eagles Nàìjíríà gún Guinea Bissau ní kẹ́ṣẹ́ pẹ̀lú 2-0
Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria gbo ewuro soju Guinea Bissau ninu ere bọọlu kẹta ti wọn gba ninu idije AFCON 2021.
Ẹlẹsẹ ayo Umar Sadiq to kọkọ sọ goolu to yẹ ko gba s'awọn Guinea Bissau lo pada gba goolu s'awọn fun Naijiria.
Naijiria ti kọkọ lu Egypt ati Sudan ninu Ifesewonse meji ti wọn kọkọ gba nibi idije naa.
- Nàìjíríà ló dáńtọ́ láti gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2021 ní Cameroon- Asamoah Gyan
- Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀
- Irọ́ ni Tinubu ń pa o, PVC kìí parí iṣẹ́ – INEC
- Wo àwọn kìnìún tó ń ṣe ọ̀fìnkìn lẹ́yìn tí wọ́n kó covid-19 lára àwọn èèyàn
- Ìjọba Buhari, o gbọdọ̀ san bílíọ̀nù kan náírà(N1bn ) owó gbà máàbínú fún Nnamdi Kanu- Adájọ́
- Akẹ́kọ̀ọ́, ìyá rẹ àtàwọn jàndùkú dá bàntẹ́ ìyà fún olùkọ̀ọ́ l'Ogun
Adiẹyin mu to tun jẹ balogun Super Eagles lori papa, William Troost-Ekong fọba lee fun Naijiria lẹyin to gba goolu keji sawọn fun Naijiria.
Naijiria yóò fórí gbárí pẹ̀lu Guinea Bissau lálẹ́ òní, ohun tí a mọ̀ nípa ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ náà rèé
Lonii ni ikọ agbabọọlu Naijiria yoo koju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Wild Dogs ti orilẹ-ede Guinea Bissau ninu idije Afcon to n lọwọ laago mẹjọ alẹ.
Ikọ Super Eagles lo n leke tente ninu ẹgbẹ ti wọn wa lẹyin ti wọn ti kọkọ na ikọ Egypt ni ami ayo 1-0, lẹyin naa ni wọn tun din dundu iya fun ikọ agbabọolu Sudan pẹlu ami ayo 3-1.
Ti Super Eagles ba bori lalẹ oni, awọn ni yoo jẹ ikọ akọkọ ti yoo ni ojuami mẹsan an ninu ifeọsẹwọnsẹ ẹlẹgbẹjẹgbẹ ninu idije Afcon naa.
Amọ, to ba jẹ pe ikọ Guinea Bissau lo jaweolubori, wọn ni anfaanin lati tẹsiwaju si ipele to kan ninu idije Afcon fun igba akọkọ ninu itan, amọ iyẹn da le esi ifẹsẹwọnsẹ laarin Egypt ati Sudan.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa ifẹsẹwọnṣẹ laarin Naijiria ati Guinea Bissau
Ikọ mejeji ko tii dojukọ ara wọn ri, eyii ni igba akọkọ.
Ipo kẹ́rìndínláàdọ́fà ni Guinea Bissau wa lagbaye, ti wọn si wa ni ipo kẹrinlelogun nilẹ Afrika.
Nigba ti Super Eagles wa ni ipo kẹrindinlogoji lagbaye, ti wọn wa ni ipo karun un nilẹ Afrika.
Ninu idije Afon to n lọ lọwọ yii, Guinea Bissau ko tii sọ bọlu kankan sinu awọn bo tilẹ jẹ pe wọn ni ojuami kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Sudan.
Igba kẹta ree ti Guinea Bissau yoo kopa ninu idije Afcon bo tilẹ jẹ pe wọn ko kọja ipele ẹlẹgbẹjẹgbẹ ri ninu idije ọhun.
Super Eagles ẹwẹ ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba mẹta ọtọtọ.