Nnamdi Kanu trial: Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ olórí ẹgbẹ́ IPOB Nnamdi Kanu sí oṣù tó ń bọ̀

Ileẹjọ giga ijọba apapọ niluu Abuja ti sun igbejọ Nnamdi Kanu siwaju si ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keji ọdun 2022 yii.

Ileẹjọ ni eyi yoo fawọn ni aye lati wo ibeere awọn agbẹjọro Kanu ti wọn ni ki ileẹjọ yi ọrọ olupẹjọ danu.

Adajọ tun sọ pe awọn olupẹjọ gbọdọ fi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Kanu to awọn agbẹjọro rẹ leti o kere tan bi ọrọ marun un si igbẹjọ.

Eleyii ṣẹlẹ lẹyin ti Kanu sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti ijọba tun ṣẹṣẹ fi kan oun.

Amọ awọn olupẹjọ ni awọn ṣetan lati tẹsiwaju pẹlu ẹjọ naa wi pe awọn ni ẹlẹri meji.

Amọ, Mike Ozekhome to jẹ agbẹjọro Nnamdi bẹ ileẹjọ lati yi ẹbẹ awọn olupẹju danu.

Agbẹjọro Ozekhome tun sọ fun ileẹjọ lati gba beeli Nnamdi.

Adajọ sọ pe ki awọn olupẹjọ gbe ọrọ agbẹjọro Kanu to ni ki ileẹjọ yyi ọrọ wọn danu wo.

DSS, ẹ jẹ́ kí Kanu pààrọ̀ aṣọ tó ń wọ̀ wá sílé ẹjọ́ mi bí bẹ́ẹ̀ kọ́.......- Adajọ Binta Nyako

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ọ̀rọ̀ Kanu lẹ́yìn tó sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

Nnamdi Kanu ko sọ pe oun jẹbi abi oun ko jẹbi awọn ẹsun tuntun ti ijọba apapọ fi kan an bi wọn ṣe sun igbẹjọ to bẹrẹ lóòní sí ọla, ọjọ kọkandinlogun oṣu kini ọdun 2022.

Awọn agbẹjoro Kanu sọ fun Onidajọ Binta Nyako pe awọn ni lati wo ẹsun tuntun naa finifini ki wọn si tun ni gbolohun pẹlu onibara wọn fun esi to yẹ.

Eleyi lo mu ki ile ẹjọ wa sun igbẹjọ sí ọla, ọjọ kọkandinlogun oṣu kini ọdun 2022 ki awọn agbẹjọro Kanu le fi oju ṣunnukun wo ẹsun tuntun naa.

Ogbontarigi agbẹjọro, Mike Ozekhome ni o dari ọpọlọpọ awọn agbẹjọro fun Kanu bi igbẹjọ naa ṣe bẹrẹ loni ọjọ kejidinlogun oṣu kini ọdun 2022.

Wo ibi tí ọ̀rọ̀ Nnamdi Kanu dé dúró nílé ẹjọ́ lónìí

Igbẹjọ Kanu ni o n tẹsiwaju ni ọjọ Isẹgun, ọjọ kejidinlogun oṣu kini ọdun 2022 ni ile ẹjọ giga ilu Abuja.

Kanu ni o n koju ẹsun ikogunja ijọba, igbesunmọmi, igbiyanju lati ya ẹya kan kuro lara ilẹ Naijiria pẹlu pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ IPOB ti ijọba ti fi ofin de.

Wọn tun fi ẹsun kan pe o gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa aarẹ Muhammadu Buhari eyi ti Kanu nipe oun ko jẹbi awọn ẹsun yii.

Awọn agbẹjọro Kanu fi idi re mulẹ pe lootọ ni ijọba apapọ fi awọn ẹsun tuntun kan ni bi wakati mẹrinlelogun ki igbẹjọ rẹ to bẹrẹ.

Igbẹjọ Kanu ma waye ni ọjọ kejidinlogun, ketadinlogun ati kerindinlogun oṣu kini ọdun 2022.

Ile ẹjọ Onidajọ Binta Nyako ni Igbẹjọ Kanu ti n waye ni ilu Abuja.

Igbẹjọ yii ni o waye lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti Ààre Buhari sọ wipe oṣelu kọ ni oun yoo fi yanju ọrọ Kanu afi ki o lọ wẹ orukọ ara rẹ mọ ni ile ẹjọ.