2023 presidency: Wo àwọn ọmọ Yorùbá mẹ́fà tí ẹnu ń kùn lórí ìbò ààrẹ ọdún 2023

Bi ibo gbogbo ọdun 2023 ti n kan ilẹkun gbọngbọn ni awọn oludije fun ipo aarẹ ti n yọju lọkọọkan.

Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n sọ nipa awọn to fẹ dupo aarẹ lọdun 2023 ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo gbe ijọba silẹ.

Pataki julọ ọpọ lo gbagbọ lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria pe ẹya Yoruba ni ipo aarẹ kan lọdun 2023.

Aṣiwaju Bola Tinubu, Dele Momodu ati Doyin Okupe wa lara awọn ọmọ Yoruba to ti fi erongba wọn han lati dupo aarẹ lọdun to n bọ.

Wọnyii ni awọn ọmọ Yoruba mẹfa ti ẹnu n kun lori ibo aarẹ ọdun 2023.

Bola Tinubu

Laipẹ yii Asiwaju Bola Tinubu kede erongba rẹ lati du ipo aarẹ orilẹede Naijiria.

Tinubu to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC kan si aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ Aje to kọja niluu Abuja lori erongba rẹ.

Lẹyin naa lo sọ fun awọn oniroyin pe oun ti fi to aarẹ leti pe oun fẹ dupo lọdun 2023.

Awuyewuye lo tẹle ikede Tinubu yii, oriṣiiriṣii nakn lawọn eeyan n sọ lori erongba Tinubu lati dije fun ipo aarẹ Naijiria.

Eekan ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode George ni tẹ sọ pe awada kẹrikẹri ni ikede Tinubu to ni oun fẹ dupo aarẹ Naijiria.

Yemi Osinbajo

Igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo jẹ ọkan lara awọn ọmọ ilẹ Yoruba ti ẹnu n kun fun ibo aarẹ ọdun 2023.

Bo tilẹ jẹ pe Osinbajo gan an fun ra rẹ ko tii kede pe oun maa dije fun ipo aarẹ lọdun 2023, oniruuru ẹgbẹ ni wọn ti bẹrẹ ipolongo fun igbakeji aarẹ.

Koda, olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, ajagun fẹyinti Ibrahim Babangida gan buwọlu Osinbajo laipẹ yii gẹgẹ bi ẹni to le tukọ orilẹede Naijiria.

Awọn ẹgbẹ kan tiẹ sọ fun un pe ko si iru adehun ti o le ṣe pẹlu ẹnikan to le ni ki o maa dije fun ipo aarẹ.

Kayode Fayemi

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi naa wa lara awọn ọmọ ilẹ Yoruba ti ẹnu n kun lori ibo aarẹ ọdun 2023.

Fayemi gan an fun ra rẹ ko tii sọ fawọn ọmọ Naijiria pe oun yoo dupo aarẹ lọdun 2023.

Amọ, ọpọ lo gbagbọ wi pe gomina ipinlẹ Ekiti naa yoo kopa ninu ibo aarẹ ọdun 2023.

Doyin Okupe

Agbẹnusọ aarẹ ana, Goodluck Jonathan, Doyin Okupe naa ti kede bi Asiwaju Bola Tinubu pe oun ṣetan lati dupo aarẹ lọdun 2023.

Okupe ni labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni oun yoo gbegba ibo aarẹ lọdun 2023.

Okupe ni oun yoo ṣe ijọba ti yoo mu ọrọ awọn mẹkunnu lọkunkundun.

Bakan naa ni Okupe ṣeleri lati wa ojutu si ina ọba to n ṣe mọna mọna ti awọn ọmọ Naijiria ba le dibo fun oun.

Babatunde Fashola

Fun igba pipẹ ni ọpọ Naijiria ti n sọ pe o ṣeeṣe ki gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Babatunde Fashola dije fun ipo aarẹ ọdun 2023.

Awọn ololufẹ Fashola gbagbọ pe oun lo gbangba sun lọyẹ lati tukọ orilẹede Naijiria pẹlu iriri iṣejọba ti o ti ni.

Ọpọ sọ pe Fashola gbiyanju nigba to fi jẹ gomina ipinlẹ Eko eyi to tumọ si pe yoo gbarada to le di aarẹ orilẹede Naijiria.

Koda, ọpọ eeyan ni wọn tun ti n lu u lọgọ ẹnu lori iṣẹ to n ṣe gẹi bi minisita akanṣe iṣẹ ati ilegbee.

Dele Momodu

Gbajúgbajà akọròyìn tó ti fi èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́dún 2023, Dele Momodu ti ní láti ọdún 2018 ni ẹnìkan ti fi àtẹ̀jíṣẹ́ ráńṣẹ́ sí òun wí pé òun yóò di Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí.Pásítọ̀ ti ríran sí mi pé mà á jẹ Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọdún 2018- Dele Momodu

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò ká sí nígbà náà, àsìkò ti tó báyìí kí àlá onítọ̀hún wá sí ìmúṣẹ.

Dele Momodu ni ọmọ Yoruba to jẹ ẹni kẹfa ti a n sọrọ le lori lonii.