Nigeria Prison Break: Ìjọba Nàìjíríà korò ojú sí ìkọlù ọgbà ẹ̀wọ̀n, mọ̀ síi nípa àwọn àṣẹ̀ tuntun ti Minista Rauf Aregbesola gbé kalẹ̀

Ọpọ eeyan lo kọkọ bẹrẹ si ni beere pe ṣé lootọ ni Minisita Aregbesola pasẹ pe ki wọn yinbọn pa ẹnikẹni tó bá se ikọlu si ọgbà ẹwọn ni Naijiria.

BBC ti ri aridaju pe lootọ ni Ogbeni Rauf Aregbesola sọ ọrọ yi ati pe ni ilu Ibadan lasiko àbẹwò to ṣe si ọgbà ẹwọn Agodi lo ti sọ.

Lẹnu ọjọ mẹta yi ikọlu sí àwọn ọgbà ẹwọn Naijiria n peleke si ti awọn oṣiṣẹ ọgbà ẹwọn pupọ sí n gbabẹ padanu ẹmi wọn.

A gbọ pe awọn oṣiṣẹ ọgbà ẹwọn kan ti kan sara si Minisita lori igbesẹ yi ti wọn sì láwọn lero pe yoo jẹ ọna ati koju ikọlu lemọ lemọ to n waye.

Igbesẹ yi dabi ẹni pé ọrọ naa ti dojú su ìjọba ti wọn sì ṣetan bayi lati wa ojutu sí.

Ìjọba Naijiria ti n bẹnu àtẹ lu bi awọn olubi ṣe n dana sun ọgbà ẹwọn ti wọn sì n tu àwọn ẹlẹwọn silẹ.

Nitori iṣẹlẹ yi o le ni ẹlẹwọn ẹgbẹrun marun ùn tí wọn ti sa láwọn ọgbà ẹwọn jakejado Naijiria laarin ọdun 2000-2021.

Púpọ ninu wọn ni wọn kò ti ri mu padà.

Minisita Aregbesola sọ pé o ti doju ẹ bayi ati pe awọn alaburu yi ti sun ìjọba kan ogiri.

"Ẹnikẹni to ba gbiyanju lati kọlu ọgbà ẹwọn,ẹ ma ṣe lese,ẹ ma yinbọn mọ lati ṣe lese,ẹ yinbọn lu lati pa ni."

Ohun to jẹ wa logun ni pé kí a pese aabo to peye"

Ki wa l'awọn to mọ nipa iṣẹ aabo lọgba ẹwọn Naijiria n sọ si ọrọ yi?

Onwoye oṣiṣẹ ọgbà ẹwọn tẹlẹ kan to bá BBC sọrọ tó si ni ka ma darukọ oun ni "ọrọ sunukun lo wa nilẹ yi"

O ni oju sunukun lo ku to ye ki a fi wo o ati pe ọpọ igba lo maa n jẹ pe ori bibẹ kọ ni oogun ori fifọ