Ivory Coast vs Algeria: Ivory Coast já ìràwọ̀ Algeria lulẹ̀ nínú ìdije AFCON, ni wọ́n bá dèrò ilé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ṣe afojudu ni ki a pe e ni abi o kan wa bẹẹ naa ni?

Ohun ti a n sọ ni ijakulẹ ẹgbẹ agbabọọlu Algeria ti ife idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON wa lọwọ ninu idije ọhun to n lọ lọwọ ni Cameroon.

Ivory Coast tutọ soke foju gba a nigba ti wọn koju Algeria ni Ọjọru, igbaju igbamu ni wọn fi ṣe fun Algeria.

Eni, eji, ẹta, bi Ivory Coast ṣe ko goolu le Algeria lọwọ niyii ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun eleyii to ya ọpọ ololufẹ ere bọọlu lẹnu.

Amọ, Algeria naa ta putu da ẹyọkan pada bo tilẹ jẹpe aṣọ ko ba Ọmọyẹ mọ nitori Ọmọyẹ wọn ti rin ni ihoho wọ ọja.

Iya o to ya, a fi ada pa ikun, ikun lọ, ada tun sọ nun.

Algeria tun ri pẹnariti ninu ere bọọlu ọhun, amọ ẹlẹsẹ ayo wọn, Riyad Mahrez to gba pẹnariti naa tun padanu rẹ.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti Algeria gba ninu idije AFCON 2021 yii, wọn fidi rẹmi ninu meji nigba ti wọn ta ọmi ninu ọkan to ku.

Koda, goolu kan ṣoṣo ni wọn le ri gba sawọn eleyii to jẹ ki wọn jẹ gbese goolu mẹta bayii.

Ivory Coast to ran wọn lọ sile lo wa loke tente tabili isọri karun un ti wọn wa pẹlu ami ayo meje.

Equatorial Guinea to fagba han Sierra Leone ninu ifẹsẹwọnsẹ keji to waye l'Ọjọbọ ni isọri karun un idije AFCON lo ṣipo keji pẹlu ami ayo mẹfa.

Si iyalẹnu ọpọlọpọ, Algeria lo wa ni isalẹ patapata pẹlu ami ayo kan ṣoṣo.

Algeria lo gba ife ẹyẹ AFCON lọdun 2019 lẹyin ti wọn lu ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije naa.