You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Maduka Okoye: Wo ohun tí o lè má mọ̀ nípa Maduka Okoye, aṣọ́lé Nàìjíríà tó ń dá àwọn obìnrin lọ́rùn
Orukọ aṣọle Super Eagles Naijiria, Maduka Okoye lo wa lẹnu ọpọ obinrin Naijiria bayii.
Ibeere ti eeyan le beere ni pe, ṣe nitori idije ere bọọlu AFCON 2021 ti Naijiria n kopa lọwọ ninu rẹ ni Cameroon ni Okoye fi n dawọn lọrun?
Iyalẹnu lo jẹ nitori ẹwa ti Eledua fi jinki Maduka ọmọ Okoye lawọn obninrin fi n sọ nipa rẹ papaa julọ lori itakun agbọrọkaye Twitter.
- Super Eagles Nàìjíríà gún Guinea Bissau ní kẹ́ṣẹ́ pẹ̀lú 2-0
- Ìgbẹ́ àá féwé! Ivory Coast já ìràwọ̀ Algeria lulẹ̀ nínú ìdije AFCON ní Cameroon
- Ẹ̀tànjẹ lásán ni ètò ààbò tí Tinubu ní yóò dára tí òun bá di ààrẹ Naijiria - Afenifere
- Wo bí àbẹ̀wò ọjọ́ méjì tí Aarẹ Buhari ṣe sí Kaduna yóò ṣe lọ
- Ọmọ ọdún 14 gún ara rẹ̀ pa lẹ́yìn tí okùnrin ẹni ọdún 35 fi ipá balòpọ̀
- Ọlọ́pàá Oyo bẹ̀rẹ̀ kán lu ìgbó láti wá àwọn ajínigbé lópópónà Lagos-Ibadan Expressway
Okoye ti inagijẹ rẹ n jẹ ''Madu'' ti di ilumọọka lati igba ti idije AFCON ti bẹrẹ ni Cameroon.
Okoye gba bọọlu fun ikọ Super Eagles Naijiria fun igba akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Naijiria ti koju Brazil lọdun 2019.
Ẹgbẹ agbabọọlu Fortuna Dusseldorf ni Germany lo n gba bọọlu fun nigba naa.
Okoye ṣoju ikọ agbabọọlu ọdọ Bayer Leverkusen ati Fortuna Düsseldorf ti o to darapọ mọ Sparta Rotterdam loṣu keje ọdun 2020.
Wọnyii ni awọn koko kan ti o le ma mọ nipa Maduka Okoye:
1. Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 1999 ni wọn bi Maduka Okoye ni Dusseldorf lorilẹede Germany.
Ọmọ Naijiria ni baba rẹ, amọ ọmọbibi orilẹede Germany iya to bi i lọmọ.
2. Okoye fi Naijria silẹ lọ si Germany lọmọ ọdun mẹfa, ko si pada wale fun ọdun mẹrinla.
3. Ọmọ Enugu ni baba rẹ, Okoye gbe niluu Enugu, Abuja ati ilu Eko fun igba diẹ ki o to morile Germany nibi to ti dagba to si ti di agbabọọlu.
4. Wọn pe Okoye si ikọ agbabọọlu U23 Naijiria lọdun 2019, ṣugbọn ko le wa nitori ikọ to n gbabọọlu fun ko fi i silẹ.
5. Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje ọdun 2019, akọnimọọgba Super Eagles tẹlẹ ri, Gernot Rohr ni oun fẹ pe Maduka lati wa darapọ mọ Super Eagles lẹyin ti aisan Carl Ikeme bẹrẹ.