Buhari in Kaduna: Wo bí àbẹ̀wò ọjọ́ méjì tí Aarẹ Buhari ṣe sí Kaduna yóò ṣe lọ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti gunlẹ si ipinlẹ Kaduna fun abẹwo ẹnu iṣẹ ọlọjọ meji.

Gẹgẹ bi ikede ti ijọ̀ba ibilẹ Kaduna fi sita, ilu Banjul lorilẹ-ede Gambia nibi ti Buhari ti lọ ba wọn ṣajọyọ ifilọlẹ saa keji Aarẹ Adama Barrow lo gba de Kaduna.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti sọ pe aarẹ yoo ṣe ifilọlẹ iṣẹ akanṣe, sọgbẹ digboro ati awọn iṣẹ miran nilu Kafanchan, Kaduna ati Zaria fun ọjọ meji.

Lara awọn akanṣe isẹ naa ni afara oloke Kawo ti ijọba ipinlẹ Kaduna ṣẹṣẹ pari.

Afara naa lo so Kaduna mọ awọn ọna to n bọ lati ipinlẹ Kano, Katisina ati awọn ipinlẹ yooku to wa ni Ariwa Naijiria.

Ọsẹ to kọja ni Aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe iṣẹ kan ni ipinlẹ Ogun. Nibẹ lo ti ṣi ọna ti ijọba ipinlẹ naa ṣe ni oju ọna Sagamu si Abeokuta, Ijebu-Ode si Epe, ile alakọpọ 'estate' meji nilu Abeokuta.

Loṣu Kejila bakan naa, aarẹ ṣi awọn ọkọ oju omi ijagun ni ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi nipinlẹ Eko.