Ilé ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Abia pàṣẹ fún DSS láti san bílíọnù kan Naira fún Nnamdi Kanu

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Umuahia, nipinlẹ Abia, ti paṣẹ fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS pe ko san biliọnu kan Naira fun Nnmadi Kanu gẹgẹ bi owo itunnu fun ile rẹ ti ajọ naa kọlu nilu Iaiama Afaraukwu loṣu Kẹsan-an, ọdun 2017.

Kanu to jẹ olori ẹgbẹ to n polongo fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra lo pe ẹjọ naa.

Nibi igbẹjọ Kanu to waye ni owurọ ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ni onidajọ Benson Anya tun fun ijọba apapọ Naijiria pe o gbọdọ kọ iwe ẹbẹ si Kanu ninu iwe iroyin mẹta lori ikọlu naa.

Ninu igbẹjọ miran to tun waye lori ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan Nnamdi Kanu, eyi to waye nilu Abuja bakan naa ni Kanu ti sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti ijọba fi kan oun.

Awọn ẹsun to ni i sẹ pẹlu iditẹ mọ ijọba, igbesunmọmi ati awọn ẹsun miran ni ijọba Naijriia fi kan Kanu.

Bo ṣe sọ pe oun ko jẹbi yii, awọn agbẹjọro ijọba sọ pe awọn ti ṣetan lati tẹsiwaju pẹlu ẹjọ naa pẹlu ẹlẹri meji.

Ṣugbọn ṣa, agbẹjọro Kanu, Mike Ozekhome sọ pe awn ti kọwe si ile ẹjọ pe ko fagile awọn ẹsun ti ijọba fi kan onibaara rẹ.

Bakan naa lo fẹ ki ile ẹjọ gba beeli rẹ.

Amọ, awọn agbẹjọro ijọba sọ pe awọn ṣẹṣẹ tẹwọ gba iwe ẹbẹ naa ni owurọ oni ni, ti awọn ko si le fesi si lọwọlọwọ.

Onidajọ Nyako ti da ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji, gẹgẹ bi ọjọ ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.

|Saaju lo ti kọkọ paṣẹ fun DSS pe ki wọn o jẹ ki Nnamdi Kanu paarọ aṣọ to ti n wọ lati ọdun 2021 ti wọn ti mu u.