#TUNNGR: Ẹyẹ j’ẹyẹ lọ! Super Eagles f'ìyẹ́ bo Carthage Eagles Tunisia mọ́ 'lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Diẹ to ninu nnkan oni nnka, eyi lo difa fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti wọn ipo kẹta tawọn nnkan n pe ni golden bronze ninu idije AFCON 2019.
Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni ẹlẹsẹ ayo, Odion Ighalo gba bọọlu sawọn eyi fun Naijiria lanfani lati siwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun su aṣekagba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ighalo ti gba goolu marun un wọ le bayii lati igba ti idije AFCON 2019 ti bẹrẹ.
- Super Eagles gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Seedorf olùkọ́ni Indomitable Lions Cameroun
- Yinka Ayefele di bàbá ìbẹta
- Buhari ti buwọ́lu ẹ̀kúnwó sísan owó oṣù tuntun fáwọn òṣìṣẹ́ àpapọ̀
- A ti wọ́gilé ìwọ́de lórí COZA tí a fẹ́ ṣe tẹ́lẹ́ nítorí...
- Mercy Aigbe bu èpè jó àwọn tó ní gómìnà kan ló ra ilé fún-un
- Ẹ wo báwọn òṣèré tíátà kan yóò ṣe rí lọ́jọ́ ogbó
O ṣeesẹ ko jẹ pe Ighalo lo maa gbami ẹyẹ agbabọọlu to gbayo sawọn julọ ninu idije AFCON 2019.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ, akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Gernot Rohr sọ ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ alẹ Ọjọru pe lẹyin ere bọọlu pẹlu Tunisia l'oun yoo kede bo ya oun yoo tẹsiwaju pẹlu ikọ agbabọọlu Naijiria.
AFCON 2019: Ìjà ẹlẹyẹ méjì láàrin Nàìjíríà àti Tunisia
Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ati ti orilẹede Tunisia yoo jọ ta kanungbọn lalẹ Ọjọru lati ja fun ipo kẹta ninu idije AFCON 2019 lorilẹede Egypt.
O ku iṣẹju aaya ki ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba laarin Super Eagles ti Naijiria ati Algeria tan ni Riyad Mahraz gbayo keji wọ le Naijiria.
Eleyi to jẹ ki Algeria fi Naijiria ṣatẹgun si ipele aṣekagba pẹlu ami ayo meji sẹyọ kan.

Oríṣun àwòrán, CAF
Ẹgbẹ agbabọọlu Tunisia kuna lati de ipele aṣekagba lẹyin ti Senegal fagba han wọn pẹlu ami ayo kan sodo.
Igba akọkọ ree ti ẹgbẹ agbabọọlu Tunisia yoo de ipele to kangun si aṣekagba lati igba ti wọn ti gba ife ẹyẹ AFCON lọdun 2004 ti wọn gbalejo idije ọhun.
Ọmi ni ikọ agbabọọlu Tunisia ta ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn kọkọ gba, ki wọn to na Ghana pẹlu wo mi ki n gba siọ ni ipele ẹlẹni mẹrindinlogun.

Oríṣun àwòrán, CAF
Ṣugbọn wọn fakọyọ ni ipele ẹlẹni mẹjọ lẹyin ti wọn fiya jẹ Madagascar pẹlu ami ayo mẹta sodo.
Ikọ Super Eagles jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn kọkọ gba pẹlu Burundi ati Guinea ki Madagascar to fiya jẹ wọn lai ro tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, CAF
Naijiria fi Cameroon paa ni ipele ẹlẹni mẹrindinlogun pẹlu ami ayo mẹta si meji ki wọn to ṣeya fun South Africa ni ipele ẹlẹni mẹjọ.
Algeria lo ṣẹ Naijiria leegun ẹyin ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba.













