Community shield: Manchester city na Chelsea pẹ̀lú 2-0

Balogun ikọ Man city, Vincent Kompany gbe ife Community shield soke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eyi ni igba akọkọ ti Manchester city yoo maa gba ife ẹyẹ naa lati ọdun 2012

Goolu meji ọtọọtọ lati ẹsẹ atamatase agbabọọlu Manchester city, Kun Aguero lo fun Manchester city ni ife ẹyẹ Community shield ti ọdun 2018.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city pẹlu Chelsea forigbari ninu idije Community Shield lọjọ aiku ni papa iṣire Wembley ni ilu London.

Aguero fẹ gba bọọlu wole

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idije ife ẹyẹ Community shield yii ni ifẹsẹwọnsẹ to maa n ṣe atọna fun saa liigi tuntun lorilẹede Gẹẹsi

Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo fi pari, goolu ti Aguero gba wọle ni iṣẹju kẹtala ati ikejidinlọgọta ifẹsẹwọnsẹ naa lo la aarin Manchester City ati Chelsea.

Manchester city ni ẹgbẹ agbabọọlu to gba liigi saa to kọja nigbati Chelsea gba ife ẹyẹ FA ni orilẹede Gẹẹsi.

Ifẹsẹwọnsẹ laarin Chelsea ati Manchestercity

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Manchester city ni ẹgbẹ agbabọọlu to gba liigi saa to kọja nigbati Chelsea gba ife ẹyẹ FA ni orilẹede Gẹẹsi

Idije ife ẹyẹ Community shield yii ni ifẹsẹwọnsẹ to maa n ṣe atọna fun saa liigi tuntun lorilẹede Gẹẹsi.

Idije yii ni o jẹ idanwo akọkọ fun olukọni tuntun fun ikọ Chelsea Maurizio Sarr lẹyin ti awọn alaṣẹ ikọ Chelsea le olukọni wọn tẹlẹ, Antonio Conte ni ọjọ kẹtala oṣu keje ọdun yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọdunlade Adekọla gbóṣùbà fáwọn ọkùnrin tó ń ran ìyàwó wọn lọ́wọ́

Eyi ni igba akọkọ ti Manchester city yoo maa gba ife ẹyẹ naa lati ọdun 2012 nigba ti wọn na ẹgbẹ agbabọọẹu Chelsea kan naa pẹlu ami ayo mẹta si meji.

Ni bayii, ẹgbẹ agbabọọlu city yoo maa koju Arsenal ni papa iṣire Emirate ni ọjọ aiku to nbọ fun ibẹẹrẹ saa liigi tuntun ti Che;sea yoo ba Huddersfield figagbaga.